1 Corinthians 12 (BOYCB)

1 Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. 2 Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ kèfèrí, a fà yín lọ sọ́dọ̀ àwọn odi òrìṣà. 3 Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 4 Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni o ń pín wọn. 5 Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. 6 Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn. 7 Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. 8 Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá. 9 Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 10 Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. 11 Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan. 12 Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13 Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀. 15 Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16 Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́. 17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? 18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. 19 Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà. 20 Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni. 21 Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” 22 Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. 23 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24 Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25 Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26 Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀. 27 Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 28 Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

In Other Versions

1 Corinthians 12 in the ANGEFD

1 Corinthians 12 in the ANTPNG2D

1 Corinthians 12 in the AS21

1 Corinthians 12 in the BAGH

1 Corinthians 12 in the BBPNG

1 Corinthians 12 in the BBT1E

1 Corinthians 12 in the BDS

1 Corinthians 12 in the BEV

1 Corinthians 12 in the BHAD

1 Corinthians 12 in the BIB

1 Corinthians 12 in the BLPT

1 Corinthians 12 in the BNT

1 Corinthians 12 in the BNTABOOT

1 Corinthians 12 in the BNTLV

1 Corinthians 12 in the BOATCB

1 Corinthians 12 in the BOATCB2

1 Corinthians 12 in the BOBCV

1 Corinthians 12 in the BOCNT

1 Corinthians 12 in the BOECS

1 Corinthians 12 in the BOGWICC

1 Corinthians 12 in the BOHCB

1 Corinthians 12 in the BOHCV

1 Corinthians 12 in the BOHLNT

1 Corinthians 12 in the BOHNTLTAL

1 Corinthians 12 in the BOICB

1 Corinthians 12 in the BOILNTAP

1 Corinthians 12 in the BOITCV

1 Corinthians 12 in the BOKCV

1 Corinthians 12 in the BOKCV2

1 Corinthians 12 in the BOKHWOG

1 Corinthians 12 in the BOKSSV

1 Corinthians 12 in the BOLCB

1 Corinthians 12 in the BOLCB2

1 Corinthians 12 in the BOMCV

1 Corinthians 12 in the BONAV

1 Corinthians 12 in the BONCB

1 Corinthians 12 in the BONLT

1 Corinthians 12 in the BONUT2

1 Corinthians 12 in the BOPLNT

1 Corinthians 12 in the BOSCB

1 Corinthians 12 in the BOSNC

1 Corinthians 12 in the BOTLNT

1 Corinthians 12 in the BOVCB

1 Corinthians 12 in the BPBB

1 Corinthians 12 in the BPH

1 Corinthians 12 in the BSB

1 Corinthians 12 in the CCB

1 Corinthians 12 in the CUV

1 Corinthians 12 in the CUVS

1 Corinthians 12 in the DBT

1 Corinthians 12 in the DGDNT

1 Corinthians 12 in the DHNT

1 Corinthians 12 in the DNT

1 Corinthians 12 in the ELBE

1 Corinthians 12 in the EMTV

1 Corinthians 12 in the ESV

1 Corinthians 12 in the FBV

1 Corinthians 12 in the FEB

1 Corinthians 12 in the GGMNT

1 Corinthians 12 in the GNT

1 Corinthians 12 in the HARY

1 Corinthians 12 in the HNT

1 Corinthians 12 in the IRVA

1 Corinthians 12 in the IRVB

1 Corinthians 12 in the IRVG

1 Corinthians 12 in the IRVH

1 Corinthians 12 in the IRVK

1 Corinthians 12 in the IRVM

1 Corinthians 12 in the IRVM2

1 Corinthians 12 in the IRVO

1 Corinthians 12 in the IRVP

1 Corinthians 12 in the IRVT

1 Corinthians 12 in the IRVT2

1 Corinthians 12 in the IRVU

1 Corinthians 12 in the ISVN

1 Corinthians 12 in the JSNT

1 Corinthians 12 in the KAPI

1 Corinthians 12 in the KBT1ETNIK

1 Corinthians 12 in the KBV

1 Corinthians 12 in the KJV

1 Corinthians 12 in the KNFD

1 Corinthians 12 in the LBA

1 Corinthians 12 in the LBLA

1 Corinthians 12 in the LNT

1 Corinthians 12 in the LSV

1 Corinthians 12 in the MAAL

1 Corinthians 12 in the MBV

1 Corinthians 12 in the MBV2

1 Corinthians 12 in the MHNT

1 Corinthians 12 in the MKNFD

1 Corinthians 12 in the MNG

1 Corinthians 12 in the MNT

1 Corinthians 12 in the MNT2

1 Corinthians 12 in the MRS1T

1 Corinthians 12 in the NAA

1 Corinthians 12 in the NASB

1 Corinthians 12 in the NBLA

1 Corinthians 12 in the NBS

1 Corinthians 12 in the NBVTP

1 Corinthians 12 in the NET2

1 Corinthians 12 in the NIV11

1 Corinthians 12 in the NNT

1 Corinthians 12 in the NNT2

1 Corinthians 12 in the NNT3

1 Corinthians 12 in the PDDPT

1 Corinthians 12 in the PFNT

1 Corinthians 12 in the RMNT

1 Corinthians 12 in the SBIAS

1 Corinthians 12 in the SBIBS

1 Corinthians 12 in the SBIBS2

1 Corinthians 12 in the SBICS

1 Corinthians 12 in the SBIDS

1 Corinthians 12 in the SBIGS

1 Corinthians 12 in the SBIHS

1 Corinthians 12 in the SBIIS

1 Corinthians 12 in the SBIIS2

1 Corinthians 12 in the SBIIS3

1 Corinthians 12 in the SBIKS

1 Corinthians 12 in the SBIKS2

1 Corinthians 12 in the SBIMS

1 Corinthians 12 in the SBIOS

1 Corinthians 12 in the SBIPS

1 Corinthians 12 in the SBISS

1 Corinthians 12 in the SBITS

1 Corinthians 12 in the SBITS2

1 Corinthians 12 in the SBITS3

1 Corinthians 12 in the SBITS4

1 Corinthians 12 in the SBIUS

1 Corinthians 12 in the SBIVS

1 Corinthians 12 in the SBT

1 Corinthians 12 in the SBT1E

1 Corinthians 12 in the SCHL

1 Corinthians 12 in the SNT

1 Corinthians 12 in the SUSU

1 Corinthians 12 in the SUSU2

1 Corinthians 12 in the SYNO

1 Corinthians 12 in the TBIAOTANT

1 Corinthians 12 in the TBT1E

1 Corinthians 12 in the TBT1E2

1 Corinthians 12 in the TFTIP

1 Corinthians 12 in the TFTU

1 Corinthians 12 in the TGNTATF3T

1 Corinthians 12 in the THAI

1 Corinthians 12 in the TNFD

1 Corinthians 12 in the TNT

1 Corinthians 12 in the TNTIK

1 Corinthians 12 in the TNTIL

1 Corinthians 12 in the TNTIN

1 Corinthians 12 in the TNTIP

1 Corinthians 12 in the TNTIZ

1 Corinthians 12 in the TOMA

1 Corinthians 12 in the TTENT

1 Corinthians 12 in the UBG

1 Corinthians 12 in the UGV

1 Corinthians 12 in the UGV2

1 Corinthians 12 in the UGV3

1 Corinthians 12 in the VBL

1 Corinthians 12 in the VDCC

1 Corinthians 12 in the YALU

1 Corinthians 12 in the YAPE

1 Corinthians 12 in the YBVTP

1 Corinthians 12 in the ZBP