1 Samuel 3 (BOYCB)

1 Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú OLÚWA ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ OLÚWA ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀. 2 Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. 3 Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili OLÚWA, níbi tí àpótí OLÚWA gbé wà. 4 Nígbà náà ni OLÚWA pe Samuẹli.Samuẹli sì dáhùn, “Èmi nìyí.” 5 Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀. 6 OLÚWA sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.” 7 Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ OLÚWA: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ OLÚWA hàn án. 8 OLÚWA pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé OLÚWA ni ó ń pe ọmọ náà. 9 Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘Máa wí, OLÚWA nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀. 10 OLÚWA wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” 11 OLÚWA sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13 Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14 Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ” 15 Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16 Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.” 17 Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18 Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni OLÚWA; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.” 19 OLÚWA wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20 Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì OLÚWA. 21 OLÚWA sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí OLÚWA ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ OLÚWA.

In Other Versions

1 Samuel 3 in the ANGEFD

1 Samuel 3 in the ANTPNG2D

1 Samuel 3 in the AS21

1 Samuel 3 in the BAGH

1 Samuel 3 in the BBPNG

1 Samuel 3 in the BBT1E

1 Samuel 3 in the BDS

1 Samuel 3 in the BEV

1 Samuel 3 in the BHAD

1 Samuel 3 in the BIB

1 Samuel 3 in the BLPT

1 Samuel 3 in the BNT

1 Samuel 3 in the BNTABOOT

1 Samuel 3 in the BNTLV

1 Samuel 3 in the BOATCB

1 Samuel 3 in the BOATCB2

1 Samuel 3 in the BOBCV

1 Samuel 3 in the BOCNT

1 Samuel 3 in the BOECS

1 Samuel 3 in the BOGWICC

1 Samuel 3 in the BOHCB

1 Samuel 3 in the BOHCV

1 Samuel 3 in the BOHLNT

1 Samuel 3 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 3 in the BOICB

1 Samuel 3 in the BOILNTAP

1 Samuel 3 in the BOITCV

1 Samuel 3 in the BOKCV

1 Samuel 3 in the BOKCV2

1 Samuel 3 in the BOKHWOG

1 Samuel 3 in the BOKSSV

1 Samuel 3 in the BOLCB

1 Samuel 3 in the BOLCB2

1 Samuel 3 in the BOMCV

1 Samuel 3 in the BONAV

1 Samuel 3 in the BONCB

1 Samuel 3 in the BONLT

1 Samuel 3 in the BONUT2

1 Samuel 3 in the BOPLNT

1 Samuel 3 in the BOSCB

1 Samuel 3 in the BOSNC

1 Samuel 3 in the BOTLNT

1 Samuel 3 in the BOVCB

1 Samuel 3 in the BPBB

1 Samuel 3 in the BPH

1 Samuel 3 in the BSB

1 Samuel 3 in the CCB

1 Samuel 3 in the CUV

1 Samuel 3 in the CUVS

1 Samuel 3 in the DBT

1 Samuel 3 in the DGDNT

1 Samuel 3 in the DHNT

1 Samuel 3 in the DNT

1 Samuel 3 in the ELBE

1 Samuel 3 in the EMTV

1 Samuel 3 in the ESV

1 Samuel 3 in the FBV

1 Samuel 3 in the FEB

1 Samuel 3 in the GGMNT

1 Samuel 3 in the GNT

1 Samuel 3 in the HARY

1 Samuel 3 in the HNT

1 Samuel 3 in the IRVA

1 Samuel 3 in the IRVB

1 Samuel 3 in the IRVG

1 Samuel 3 in the IRVH

1 Samuel 3 in the IRVK

1 Samuel 3 in the IRVM

1 Samuel 3 in the IRVM2

1 Samuel 3 in the IRVO

1 Samuel 3 in the IRVP

1 Samuel 3 in the IRVT

1 Samuel 3 in the IRVT2

1 Samuel 3 in the IRVU

1 Samuel 3 in the ISVN

1 Samuel 3 in the JSNT

1 Samuel 3 in the KAPI

1 Samuel 3 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 3 in the KBV

1 Samuel 3 in the KJV

1 Samuel 3 in the KNFD

1 Samuel 3 in the LBA

1 Samuel 3 in the LBLA

1 Samuel 3 in the LNT

1 Samuel 3 in the LSV

1 Samuel 3 in the MAAL

1 Samuel 3 in the MBV

1 Samuel 3 in the MBV2

1 Samuel 3 in the MHNT

1 Samuel 3 in the MKNFD

1 Samuel 3 in the MNG

1 Samuel 3 in the MNT

1 Samuel 3 in the MNT2

1 Samuel 3 in the MRS1T

1 Samuel 3 in the NAA

1 Samuel 3 in the NASB

1 Samuel 3 in the NBLA

1 Samuel 3 in the NBS

1 Samuel 3 in the NBVTP

1 Samuel 3 in the NET2

1 Samuel 3 in the NIV11

1 Samuel 3 in the NNT

1 Samuel 3 in the NNT2

1 Samuel 3 in the NNT3

1 Samuel 3 in the PDDPT

1 Samuel 3 in the PFNT

1 Samuel 3 in the RMNT

1 Samuel 3 in the SBIAS

1 Samuel 3 in the SBIBS

1 Samuel 3 in the SBIBS2

1 Samuel 3 in the SBICS

1 Samuel 3 in the SBIDS

1 Samuel 3 in the SBIGS

1 Samuel 3 in the SBIHS

1 Samuel 3 in the SBIIS

1 Samuel 3 in the SBIIS2

1 Samuel 3 in the SBIIS3

1 Samuel 3 in the SBIKS

1 Samuel 3 in the SBIKS2

1 Samuel 3 in the SBIMS

1 Samuel 3 in the SBIOS

1 Samuel 3 in the SBIPS

1 Samuel 3 in the SBISS

1 Samuel 3 in the SBITS

1 Samuel 3 in the SBITS2

1 Samuel 3 in the SBITS3

1 Samuel 3 in the SBITS4

1 Samuel 3 in the SBIUS

1 Samuel 3 in the SBIVS

1 Samuel 3 in the SBT

1 Samuel 3 in the SBT1E

1 Samuel 3 in the SCHL

1 Samuel 3 in the SNT

1 Samuel 3 in the SUSU

1 Samuel 3 in the SUSU2

1 Samuel 3 in the SYNO

1 Samuel 3 in the TBIAOTANT

1 Samuel 3 in the TBT1E

1 Samuel 3 in the TBT1E2

1 Samuel 3 in the TFTIP

1 Samuel 3 in the TFTU

1 Samuel 3 in the TGNTATF3T

1 Samuel 3 in the THAI

1 Samuel 3 in the TNFD

1 Samuel 3 in the TNT

1 Samuel 3 in the TNTIK

1 Samuel 3 in the TNTIL

1 Samuel 3 in the TNTIN

1 Samuel 3 in the TNTIP

1 Samuel 3 in the TNTIZ

1 Samuel 3 in the TOMA

1 Samuel 3 in the TTENT

1 Samuel 3 in the UBG

1 Samuel 3 in the UGV

1 Samuel 3 in the UGV2

1 Samuel 3 in the UGV3

1 Samuel 3 in the VBL

1 Samuel 3 in the VDCC

1 Samuel 3 in the YALU

1 Samuel 3 in the YAPE

1 Samuel 3 in the YBVTP

1 Samuel 3 in the ZBP