2 Chronicles 18 (BOYCB)

1 Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. 2 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi. 3 Ahabu ọba Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jehoṣafati, ọba Juda pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Ramoti Gileadi?”Jehoṣafati sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ nínú ogun náà”. 4 Ṣùgbọ́n Jehoṣafati náà sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ OLÚWA.” 5 Bẹ́ẹ̀ ọba Israẹli kó àwọn wòlíì papọ̀, irinwó (400) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Ramoti Gileadi tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”Wọ́n dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Ọlọ́run yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” 6 Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì OLÚWA níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” 7 Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ìbá tún béèrè lọ́wọ́ OLÚWA, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorí kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Mikaiah ọmọ Imla.”Jehoṣafati sì dá lóhùn pé, “Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” 8 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹ mú Mikaiah ọmọ Imla kí ó yára wá.” 9 Wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10 Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: ‘Pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.’ ” 11 Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà. Wọ́n sì wí pé, “Dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, nítorí OLÚWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” 12 Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.” 13 Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé OLÚWA ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.” 14 Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Mikaiah, ṣe kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Ramoti Gileadi, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?”Ó sì dáhùn pé, “Ẹ dojúkọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun, nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” 15 Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ OLÚWA?” 16 Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, OLÚWA sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ” 17 Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?” 18 Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, mo rí OLÚWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. 19 OLÚWA sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. 20 Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú OLÚWA ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ OLÚWA béèrè. 21 “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni OLÚWA wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 22 “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí OLÚWA ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. OLÚWA sì ti sọ ibi sí ọ.” 23 Nígbà náà Sedekiah ọmọ Kenaana lọ sókè ó sì gbá Mikaiah ní ojú. Ó sì béèrè pé, “Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí OLÚWA gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” 24 Mikaiah sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò ṣe ìwádìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sá pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.” 25 Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba, 26 Ó sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ, ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ” 27 Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, OLÚWA kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!” 28 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. 29 Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. 30 Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.” 31 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, OLÚWA sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, 32 Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró. 33 Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.” 34 Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.

In Other Versions

2 Chronicles 18 in the ANGEFD

2 Chronicles 18 in the ANTPNG2D

2 Chronicles 18 in the AS21

2 Chronicles 18 in the BAGH

2 Chronicles 18 in the BBPNG

2 Chronicles 18 in the BBT1E

2 Chronicles 18 in the BDS

2 Chronicles 18 in the BEV

2 Chronicles 18 in the BHAD

2 Chronicles 18 in the BIB

2 Chronicles 18 in the BLPT

2 Chronicles 18 in the BNT

2 Chronicles 18 in the BNTABOOT

2 Chronicles 18 in the BNTLV

2 Chronicles 18 in the BOATCB

2 Chronicles 18 in the BOATCB2

2 Chronicles 18 in the BOBCV

2 Chronicles 18 in the BOCNT

2 Chronicles 18 in the BOECS

2 Chronicles 18 in the BOGWICC

2 Chronicles 18 in the BOHCB

2 Chronicles 18 in the BOHCV

2 Chronicles 18 in the BOHLNT

2 Chronicles 18 in the BOHNTLTAL

2 Chronicles 18 in the BOICB

2 Chronicles 18 in the BOILNTAP

2 Chronicles 18 in the BOITCV

2 Chronicles 18 in the BOKCV

2 Chronicles 18 in the BOKCV2

2 Chronicles 18 in the BOKHWOG

2 Chronicles 18 in the BOKSSV

2 Chronicles 18 in the BOLCB

2 Chronicles 18 in the BOLCB2

2 Chronicles 18 in the BOMCV

2 Chronicles 18 in the BONAV

2 Chronicles 18 in the BONCB

2 Chronicles 18 in the BONLT

2 Chronicles 18 in the BONUT2

2 Chronicles 18 in the BOPLNT

2 Chronicles 18 in the BOSCB

2 Chronicles 18 in the BOSNC

2 Chronicles 18 in the BOTLNT

2 Chronicles 18 in the BOVCB

2 Chronicles 18 in the BPBB

2 Chronicles 18 in the BPH

2 Chronicles 18 in the BSB

2 Chronicles 18 in the CCB

2 Chronicles 18 in the CUV

2 Chronicles 18 in the CUVS

2 Chronicles 18 in the DBT

2 Chronicles 18 in the DGDNT

2 Chronicles 18 in the DHNT

2 Chronicles 18 in the DNT

2 Chronicles 18 in the ELBE

2 Chronicles 18 in the EMTV

2 Chronicles 18 in the ESV

2 Chronicles 18 in the FBV

2 Chronicles 18 in the FEB

2 Chronicles 18 in the GGMNT

2 Chronicles 18 in the GNT

2 Chronicles 18 in the HARY

2 Chronicles 18 in the HNT

2 Chronicles 18 in the IRVA

2 Chronicles 18 in the IRVB

2 Chronicles 18 in the IRVG

2 Chronicles 18 in the IRVH

2 Chronicles 18 in the IRVK

2 Chronicles 18 in the IRVM

2 Chronicles 18 in the IRVM2

2 Chronicles 18 in the IRVO

2 Chronicles 18 in the IRVP

2 Chronicles 18 in the IRVT

2 Chronicles 18 in the IRVT2

2 Chronicles 18 in the IRVU

2 Chronicles 18 in the ISVN

2 Chronicles 18 in the JSNT

2 Chronicles 18 in the KAPI

2 Chronicles 18 in the KBT1ETNIK

2 Chronicles 18 in the KBV

2 Chronicles 18 in the KJV

2 Chronicles 18 in the KNFD

2 Chronicles 18 in the LBA

2 Chronicles 18 in the LBLA

2 Chronicles 18 in the LNT

2 Chronicles 18 in the LSV

2 Chronicles 18 in the MAAL

2 Chronicles 18 in the MBV

2 Chronicles 18 in the MBV2

2 Chronicles 18 in the MHNT

2 Chronicles 18 in the MKNFD

2 Chronicles 18 in the MNG

2 Chronicles 18 in the MNT

2 Chronicles 18 in the MNT2

2 Chronicles 18 in the MRS1T

2 Chronicles 18 in the NAA

2 Chronicles 18 in the NASB

2 Chronicles 18 in the NBLA

2 Chronicles 18 in the NBS

2 Chronicles 18 in the NBVTP

2 Chronicles 18 in the NET2

2 Chronicles 18 in the NIV11

2 Chronicles 18 in the NNT

2 Chronicles 18 in the NNT2

2 Chronicles 18 in the NNT3

2 Chronicles 18 in the PDDPT

2 Chronicles 18 in the PFNT

2 Chronicles 18 in the RMNT

2 Chronicles 18 in the SBIAS

2 Chronicles 18 in the SBIBS

2 Chronicles 18 in the SBIBS2

2 Chronicles 18 in the SBICS

2 Chronicles 18 in the SBIDS

2 Chronicles 18 in the SBIGS

2 Chronicles 18 in the SBIHS

2 Chronicles 18 in the SBIIS

2 Chronicles 18 in the SBIIS2

2 Chronicles 18 in the SBIIS3

2 Chronicles 18 in the SBIKS

2 Chronicles 18 in the SBIKS2

2 Chronicles 18 in the SBIMS

2 Chronicles 18 in the SBIOS

2 Chronicles 18 in the SBIPS

2 Chronicles 18 in the SBISS

2 Chronicles 18 in the SBITS

2 Chronicles 18 in the SBITS2

2 Chronicles 18 in the SBITS3

2 Chronicles 18 in the SBITS4

2 Chronicles 18 in the SBIUS

2 Chronicles 18 in the SBIVS

2 Chronicles 18 in the SBT

2 Chronicles 18 in the SBT1E

2 Chronicles 18 in the SCHL

2 Chronicles 18 in the SNT

2 Chronicles 18 in the SUSU

2 Chronicles 18 in the SUSU2

2 Chronicles 18 in the SYNO

2 Chronicles 18 in the TBIAOTANT

2 Chronicles 18 in the TBT1E

2 Chronicles 18 in the TBT1E2

2 Chronicles 18 in the TFTIP

2 Chronicles 18 in the TFTU

2 Chronicles 18 in the TGNTATF3T

2 Chronicles 18 in the THAI

2 Chronicles 18 in the TNFD

2 Chronicles 18 in the TNT

2 Chronicles 18 in the TNTIK

2 Chronicles 18 in the TNTIL

2 Chronicles 18 in the TNTIN

2 Chronicles 18 in the TNTIP

2 Chronicles 18 in the TNTIZ

2 Chronicles 18 in the TOMA

2 Chronicles 18 in the TTENT

2 Chronicles 18 in the UBG

2 Chronicles 18 in the UGV

2 Chronicles 18 in the UGV2

2 Chronicles 18 in the UGV3

2 Chronicles 18 in the VBL

2 Chronicles 18 in the VDCC

2 Chronicles 18 in the YALU

2 Chronicles 18 in the YAPE

2 Chronicles 18 in the YBVTP

2 Chronicles 18 in the ZBP