2 Chronicles 21 (BOYCB)

1 Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 2 Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. 3 Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin. 4 Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli. 5 Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. 6 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu. Ó ṣe búburú lójú OLÚWA. 7 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí OLÚWA ti dá fún Dafidi kì í ṣe ìfẹ́ OLÚWA láti pa ìdílé Dafidi run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé. 8 Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀. 9 Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. 10 Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda.Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ OLÚWA sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. 11 Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ. 12 Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé,“Èyí ní ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. 13 Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ. 14 Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí, OLÚWA ti fẹ́rẹ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn ńlá. 15 Ìwọ tìkára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ” 16 OLÚWA ru ìbínú àwọn ará Filistini àti àwọn Arabia tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá àwọn ará Kuṣi sí Jehoramu. 17 Wọ́n dojú ìjà kọ Juda, wọ́n gbà á, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Ahasiah, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, OLÚWA jẹ Jehoramu ní yà pẹ̀lú ààrùn tí kò ṣe é wòsàn nínú ìfun. 19 Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí ààrùn náà ó sì kú nínú ìrora ńlá. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bu ọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀. 20 Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dafidi. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.

In Other Versions

2 Chronicles 21 in the ANGEFD

2 Chronicles 21 in the ANTPNG2D

2 Chronicles 21 in the AS21

2 Chronicles 21 in the BAGH

2 Chronicles 21 in the BBPNG

2 Chronicles 21 in the BBT1E

2 Chronicles 21 in the BDS

2 Chronicles 21 in the BEV

2 Chronicles 21 in the BHAD

2 Chronicles 21 in the BIB

2 Chronicles 21 in the BLPT

2 Chronicles 21 in the BNT

2 Chronicles 21 in the BNTABOOT

2 Chronicles 21 in the BNTLV

2 Chronicles 21 in the BOATCB

2 Chronicles 21 in the BOATCB2

2 Chronicles 21 in the BOBCV

2 Chronicles 21 in the BOCNT

2 Chronicles 21 in the BOECS

2 Chronicles 21 in the BOGWICC

2 Chronicles 21 in the BOHCB

2 Chronicles 21 in the BOHCV

2 Chronicles 21 in the BOHLNT

2 Chronicles 21 in the BOHNTLTAL

2 Chronicles 21 in the BOICB

2 Chronicles 21 in the BOILNTAP

2 Chronicles 21 in the BOITCV

2 Chronicles 21 in the BOKCV

2 Chronicles 21 in the BOKCV2

2 Chronicles 21 in the BOKHWOG

2 Chronicles 21 in the BOKSSV

2 Chronicles 21 in the BOLCB

2 Chronicles 21 in the BOLCB2

2 Chronicles 21 in the BOMCV

2 Chronicles 21 in the BONAV

2 Chronicles 21 in the BONCB

2 Chronicles 21 in the BONLT

2 Chronicles 21 in the BONUT2

2 Chronicles 21 in the BOPLNT

2 Chronicles 21 in the BOSCB

2 Chronicles 21 in the BOSNC

2 Chronicles 21 in the BOTLNT

2 Chronicles 21 in the BOVCB

2 Chronicles 21 in the BPBB

2 Chronicles 21 in the BPH

2 Chronicles 21 in the BSB

2 Chronicles 21 in the CCB

2 Chronicles 21 in the CUV

2 Chronicles 21 in the CUVS

2 Chronicles 21 in the DBT

2 Chronicles 21 in the DGDNT

2 Chronicles 21 in the DHNT

2 Chronicles 21 in the DNT

2 Chronicles 21 in the ELBE

2 Chronicles 21 in the EMTV

2 Chronicles 21 in the ESV

2 Chronicles 21 in the FBV

2 Chronicles 21 in the FEB

2 Chronicles 21 in the GGMNT

2 Chronicles 21 in the GNT

2 Chronicles 21 in the HARY

2 Chronicles 21 in the HNT

2 Chronicles 21 in the IRVA

2 Chronicles 21 in the IRVB

2 Chronicles 21 in the IRVG

2 Chronicles 21 in the IRVH

2 Chronicles 21 in the IRVK

2 Chronicles 21 in the IRVM

2 Chronicles 21 in the IRVM2

2 Chronicles 21 in the IRVO

2 Chronicles 21 in the IRVP

2 Chronicles 21 in the IRVT

2 Chronicles 21 in the IRVT2

2 Chronicles 21 in the IRVU

2 Chronicles 21 in the ISVN

2 Chronicles 21 in the JSNT

2 Chronicles 21 in the KAPI

2 Chronicles 21 in the KBT1ETNIK

2 Chronicles 21 in the KBV

2 Chronicles 21 in the KJV

2 Chronicles 21 in the KNFD

2 Chronicles 21 in the LBA

2 Chronicles 21 in the LBLA

2 Chronicles 21 in the LNT

2 Chronicles 21 in the LSV

2 Chronicles 21 in the MAAL

2 Chronicles 21 in the MBV

2 Chronicles 21 in the MBV2

2 Chronicles 21 in the MHNT

2 Chronicles 21 in the MKNFD

2 Chronicles 21 in the MNG

2 Chronicles 21 in the MNT

2 Chronicles 21 in the MNT2

2 Chronicles 21 in the MRS1T

2 Chronicles 21 in the NAA

2 Chronicles 21 in the NASB

2 Chronicles 21 in the NBLA

2 Chronicles 21 in the NBS

2 Chronicles 21 in the NBVTP

2 Chronicles 21 in the NET2

2 Chronicles 21 in the NIV11

2 Chronicles 21 in the NNT

2 Chronicles 21 in the NNT2

2 Chronicles 21 in the NNT3

2 Chronicles 21 in the PDDPT

2 Chronicles 21 in the PFNT

2 Chronicles 21 in the RMNT

2 Chronicles 21 in the SBIAS

2 Chronicles 21 in the SBIBS

2 Chronicles 21 in the SBIBS2

2 Chronicles 21 in the SBICS

2 Chronicles 21 in the SBIDS

2 Chronicles 21 in the SBIGS

2 Chronicles 21 in the SBIHS

2 Chronicles 21 in the SBIIS

2 Chronicles 21 in the SBIIS2

2 Chronicles 21 in the SBIIS3

2 Chronicles 21 in the SBIKS

2 Chronicles 21 in the SBIKS2

2 Chronicles 21 in the SBIMS

2 Chronicles 21 in the SBIOS

2 Chronicles 21 in the SBIPS

2 Chronicles 21 in the SBISS

2 Chronicles 21 in the SBITS

2 Chronicles 21 in the SBITS2

2 Chronicles 21 in the SBITS3

2 Chronicles 21 in the SBITS4

2 Chronicles 21 in the SBIUS

2 Chronicles 21 in the SBIVS

2 Chronicles 21 in the SBT

2 Chronicles 21 in the SBT1E

2 Chronicles 21 in the SCHL

2 Chronicles 21 in the SNT

2 Chronicles 21 in the SUSU

2 Chronicles 21 in the SUSU2

2 Chronicles 21 in the SYNO

2 Chronicles 21 in the TBIAOTANT

2 Chronicles 21 in the TBT1E

2 Chronicles 21 in the TBT1E2

2 Chronicles 21 in the TFTIP

2 Chronicles 21 in the TFTU

2 Chronicles 21 in the TGNTATF3T

2 Chronicles 21 in the THAI

2 Chronicles 21 in the TNFD

2 Chronicles 21 in the TNT

2 Chronicles 21 in the TNTIK

2 Chronicles 21 in the TNTIL

2 Chronicles 21 in the TNTIN

2 Chronicles 21 in the TNTIP

2 Chronicles 21 in the TNTIZ

2 Chronicles 21 in the TOMA

2 Chronicles 21 in the TTENT

2 Chronicles 21 in the UBG

2 Chronicles 21 in the UGV

2 Chronicles 21 in the UGV2

2 Chronicles 21 in the UGV3

2 Chronicles 21 in the VBL

2 Chronicles 21 in the VDCC

2 Chronicles 21 in the YALU

2 Chronicles 21 in the YAPE

2 Chronicles 21 in the YBVTP

2 Chronicles 21 in the ZBP