2 Corinthians 5 (BOYCB)
1 Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. 2 Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. 3 Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. 4 Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. 5 Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀. 6 Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 7 Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. 8 Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. 9 Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú. 11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde. 16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà.” 21 Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.
In Other Versions
2 Corinthians 5 in the ANGEFD
2 Corinthians 5 in the ANTPNG2D
2 Corinthians 5 in the AS21
2 Corinthians 5 in the BAGH
2 Corinthians 5 in the BBPNG
2 Corinthians 5 in the BBT1E
2 Corinthians 5 in the BDS
2 Corinthians 5 in the BEV
2 Corinthians 5 in the BHAD
2 Corinthians 5 in the BIB
2 Corinthians 5 in the BLPT
2 Corinthians 5 in the BNT
2 Corinthians 5 in the BNTABOOT
2 Corinthians 5 in the BNTLV
2 Corinthians 5 in the BOATCB
2 Corinthians 5 in the BOATCB2
2 Corinthians 5 in the BOBCV
2 Corinthians 5 in the BOCNT
2 Corinthians 5 in the BOECS
2 Corinthians 5 in the BOGWICC
2 Corinthians 5 in the BOHCB
2 Corinthians 5 in the BOHCV
2 Corinthians 5 in the BOHLNT
2 Corinthians 5 in the BOHNTLTAL
2 Corinthians 5 in the BOICB
2 Corinthians 5 in the BOILNTAP
2 Corinthians 5 in the BOITCV
2 Corinthians 5 in the BOKCV
2 Corinthians 5 in the BOKCV2
2 Corinthians 5 in the BOKHWOG
2 Corinthians 5 in the BOKSSV
2 Corinthians 5 in the BOLCB
2 Corinthians 5 in the BOLCB2
2 Corinthians 5 in the BOMCV
2 Corinthians 5 in the BONAV
2 Corinthians 5 in the BONCB
2 Corinthians 5 in the BONLT
2 Corinthians 5 in the BONUT2
2 Corinthians 5 in the BOPLNT
2 Corinthians 5 in the BOSCB
2 Corinthians 5 in the BOSNC
2 Corinthians 5 in the BOTLNT
2 Corinthians 5 in the BOVCB
2 Corinthians 5 in the BPBB
2 Corinthians 5 in the BPH
2 Corinthians 5 in the BSB
2 Corinthians 5 in the CCB
2 Corinthians 5 in the CUV
2 Corinthians 5 in the CUVS
2 Corinthians 5 in the DBT
2 Corinthians 5 in the DGDNT
2 Corinthians 5 in the DHNT
2 Corinthians 5 in the DNT
2 Corinthians 5 in the ELBE
2 Corinthians 5 in the EMTV
2 Corinthians 5 in the ESV
2 Corinthians 5 in the FBV
2 Corinthians 5 in the FEB
2 Corinthians 5 in the GGMNT
2 Corinthians 5 in the GNT
2 Corinthians 5 in the HARY
2 Corinthians 5 in the HNT
2 Corinthians 5 in the IRVA
2 Corinthians 5 in the IRVB
2 Corinthians 5 in the IRVG
2 Corinthians 5 in the IRVH
2 Corinthians 5 in the IRVK
2 Corinthians 5 in the IRVM
2 Corinthians 5 in the IRVM2
2 Corinthians 5 in the IRVO
2 Corinthians 5 in the IRVP
2 Corinthians 5 in the IRVT
2 Corinthians 5 in the IRVT2
2 Corinthians 5 in the IRVU
2 Corinthians 5 in the ISVN
2 Corinthians 5 in the JSNT
2 Corinthians 5 in the KAPI
2 Corinthians 5 in the KBT1ETNIK
2 Corinthians 5 in the KBV
2 Corinthians 5 in the KJV
2 Corinthians 5 in the KNFD
2 Corinthians 5 in the LBA
2 Corinthians 5 in the LBLA
2 Corinthians 5 in the LNT
2 Corinthians 5 in the LSV
2 Corinthians 5 in the MAAL
2 Corinthians 5 in the MBV
2 Corinthians 5 in the MBV2
2 Corinthians 5 in the MHNT
2 Corinthians 5 in the MKNFD
2 Corinthians 5 in the MNG
2 Corinthians 5 in the MNT
2 Corinthians 5 in the MNT2
2 Corinthians 5 in the MRS1T
2 Corinthians 5 in the NAA
2 Corinthians 5 in the NASB
2 Corinthians 5 in the NBLA
2 Corinthians 5 in the NBS
2 Corinthians 5 in the NBVTP
2 Corinthians 5 in the NET2
2 Corinthians 5 in the NIV11
2 Corinthians 5 in the NNT
2 Corinthians 5 in the NNT2
2 Corinthians 5 in the NNT3
2 Corinthians 5 in the PDDPT
2 Corinthians 5 in the PFNT
2 Corinthians 5 in the RMNT
2 Corinthians 5 in the SBIAS
2 Corinthians 5 in the SBIBS
2 Corinthians 5 in the SBIBS2
2 Corinthians 5 in the SBICS
2 Corinthians 5 in the SBIDS
2 Corinthians 5 in the SBIGS
2 Corinthians 5 in the SBIHS
2 Corinthians 5 in the SBIIS
2 Corinthians 5 in the SBIIS2
2 Corinthians 5 in the SBIIS3
2 Corinthians 5 in the SBIKS
2 Corinthians 5 in the SBIKS2
2 Corinthians 5 in the SBIMS
2 Corinthians 5 in the SBIOS
2 Corinthians 5 in the SBIPS
2 Corinthians 5 in the SBISS
2 Corinthians 5 in the SBITS
2 Corinthians 5 in the SBITS2
2 Corinthians 5 in the SBITS3
2 Corinthians 5 in the SBITS4
2 Corinthians 5 in the SBIUS
2 Corinthians 5 in the SBIVS
2 Corinthians 5 in the SBT
2 Corinthians 5 in the SBT1E
2 Corinthians 5 in the SCHL
2 Corinthians 5 in the SNT
2 Corinthians 5 in the SUSU
2 Corinthians 5 in the SUSU2
2 Corinthians 5 in the SYNO
2 Corinthians 5 in the TBIAOTANT
2 Corinthians 5 in the TBT1E
2 Corinthians 5 in the TBT1E2
2 Corinthians 5 in the TFTIP
2 Corinthians 5 in the TFTU
2 Corinthians 5 in the TGNTATF3T
2 Corinthians 5 in the THAI
2 Corinthians 5 in the TNFD
2 Corinthians 5 in the TNT
2 Corinthians 5 in the TNTIK
2 Corinthians 5 in the TNTIL
2 Corinthians 5 in the TNTIN
2 Corinthians 5 in the TNTIP
2 Corinthians 5 in the TNTIZ
2 Corinthians 5 in the TOMA
2 Corinthians 5 in the TTENT
2 Corinthians 5 in the UBG
2 Corinthians 5 in the UGV
2 Corinthians 5 in the UGV2
2 Corinthians 5 in the UGV3
2 Corinthians 5 in the VBL
2 Corinthians 5 in the VDCC
2 Corinthians 5 in the YALU
2 Corinthians 5 in the YAPE
2 Corinthians 5 in the YBVTP
2 Corinthians 5 in the ZBP