2 Samuel 21 (BOYCB)
1 Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA, OLÚWA sì wí pé, “Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.” 2 Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn, Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda. 3 Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní OLÚWA?” 4 Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.”Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?” 5 Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. 6 Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún OLÚWA ní Gibeah ti Saulu ẹni tí OLÚWA ti yàn.”Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.” 7 Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra OLÚWA tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu. 8 Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola. 9 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú OLÚWA: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle. 10 Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru. 11 A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi. 12 Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa. 13 Ó sì mú egungun Saulu àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ. 14 Wọ́n sì sin egungun Saulu àti ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ní ilé Benjamini, ní Ṣela, nínú ibojì Kiṣi baba rẹ̀, wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ, lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà. 15 Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi. 16 Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. 17 Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.” 18 Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa. 19 Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ. 20 Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa. 21 Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á. 22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
In Other Versions
2 Samuel 21 in the ANGEFD
2 Samuel 21 in the ANTPNG2D
2 Samuel 21 in the AS21
2 Samuel 21 in the BAGH
2 Samuel 21 in the BBPNG
2 Samuel 21 in the BBT1E
2 Samuel 21 in the BDS
2 Samuel 21 in the BEV
2 Samuel 21 in the BHAD
2 Samuel 21 in the BIB
2 Samuel 21 in the BLPT
2 Samuel 21 in the BNT
2 Samuel 21 in the BNTABOOT
2 Samuel 21 in the BNTLV
2 Samuel 21 in the BOATCB
2 Samuel 21 in the BOATCB2
2 Samuel 21 in the BOBCV
2 Samuel 21 in the BOCNT
2 Samuel 21 in the BOECS
2 Samuel 21 in the BOGWICC
2 Samuel 21 in the BOHCB
2 Samuel 21 in the BOHCV
2 Samuel 21 in the BOHLNT
2 Samuel 21 in the BOHNTLTAL
2 Samuel 21 in the BOICB
2 Samuel 21 in the BOILNTAP
2 Samuel 21 in the BOITCV
2 Samuel 21 in the BOKCV
2 Samuel 21 in the BOKCV2
2 Samuel 21 in the BOKHWOG
2 Samuel 21 in the BOKSSV
2 Samuel 21 in the BOLCB
2 Samuel 21 in the BOLCB2
2 Samuel 21 in the BOMCV
2 Samuel 21 in the BONAV
2 Samuel 21 in the BONCB
2 Samuel 21 in the BONLT
2 Samuel 21 in the BONUT2
2 Samuel 21 in the BOPLNT
2 Samuel 21 in the BOSCB
2 Samuel 21 in the BOSNC
2 Samuel 21 in the BOTLNT
2 Samuel 21 in the BOVCB
2 Samuel 21 in the BPBB
2 Samuel 21 in the BPH
2 Samuel 21 in the BSB
2 Samuel 21 in the CCB
2 Samuel 21 in the CUV
2 Samuel 21 in the CUVS
2 Samuel 21 in the DBT
2 Samuel 21 in the DGDNT
2 Samuel 21 in the DHNT
2 Samuel 21 in the DNT
2 Samuel 21 in the ELBE
2 Samuel 21 in the EMTV
2 Samuel 21 in the ESV
2 Samuel 21 in the FBV
2 Samuel 21 in the FEB
2 Samuel 21 in the GGMNT
2 Samuel 21 in the GNT
2 Samuel 21 in the HARY
2 Samuel 21 in the HNT
2 Samuel 21 in the IRVA
2 Samuel 21 in the IRVB
2 Samuel 21 in the IRVG
2 Samuel 21 in the IRVH
2 Samuel 21 in the IRVK
2 Samuel 21 in the IRVM
2 Samuel 21 in the IRVM2
2 Samuel 21 in the IRVO
2 Samuel 21 in the IRVP
2 Samuel 21 in the IRVT
2 Samuel 21 in the IRVT2
2 Samuel 21 in the IRVU
2 Samuel 21 in the ISVN
2 Samuel 21 in the JSNT
2 Samuel 21 in the KAPI
2 Samuel 21 in the KBT1ETNIK
2 Samuel 21 in the KBV
2 Samuel 21 in the KJV
2 Samuel 21 in the KNFD
2 Samuel 21 in the LBA
2 Samuel 21 in the LBLA
2 Samuel 21 in the LNT
2 Samuel 21 in the LSV
2 Samuel 21 in the MAAL
2 Samuel 21 in the MBV
2 Samuel 21 in the MBV2
2 Samuel 21 in the MHNT
2 Samuel 21 in the MKNFD
2 Samuel 21 in the MNG
2 Samuel 21 in the MNT
2 Samuel 21 in the MNT2
2 Samuel 21 in the MRS1T
2 Samuel 21 in the NAA
2 Samuel 21 in the NASB
2 Samuel 21 in the NBLA
2 Samuel 21 in the NBS
2 Samuel 21 in the NBVTP
2 Samuel 21 in the NET2
2 Samuel 21 in the NIV11
2 Samuel 21 in the NNT
2 Samuel 21 in the NNT2
2 Samuel 21 in the NNT3
2 Samuel 21 in the PDDPT
2 Samuel 21 in the PFNT
2 Samuel 21 in the RMNT
2 Samuel 21 in the SBIAS
2 Samuel 21 in the SBIBS
2 Samuel 21 in the SBIBS2
2 Samuel 21 in the SBICS
2 Samuel 21 in the SBIDS
2 Samuel 21 in the SBIGS
2 Samuel 21 in the SBIHS
2 Samuel 21 in the SBIIS
2 Samuel 21 in the SBIIS2
2 Samuel 21 in the SBIIS3
2 Samuel 21 in the SBIKS
2 Samuel 21 in the SBIKS2
2 Samuel 21 in the SBIMS
2 Samuel 21 in the SBIOS
2 Samuel 21 in the SBIPS
2 Samuel 21 in the SBISS
2 Samuel 21 in the SBITS
2 Samuel 21 in the SBITS2
2 Samuel 21 in the SBITS3
2 Samuel 21 in the SBITS4
2 Samuel 21 in the SBIUS
2 Samuel 21 in the SBIVS
2 Samuel 21 in the SBT
2 Samuel 21 in the SBT1E
2 Samuel 21 in the SCHL
2 Samuel 21 in the SNT
2 Samuel 21 in the SUSU
2 Samuel 21 in the SUSU2
2 Samuel 21 in the SYNO
2 Samuel 21 in the TBIAOTANT
2 Samuel 21 in the TBT1E
2 Samuel 21 in the TBT1E2
2 Samuel 21 in the TFTIP
2 Samuel 21 in the TFTU
2 Samuel 21 in the TGNTATF3T
2 Samuel 21 in the THAI
2 Samuel 21 in the TNFD
2 Samuel 21 in the TNT
2 Samuel 21 in the TNTIK
2 Samuel 21 in the TNTIL
2 Samuel 21 in the TNTIN
2 Samuel 21 in the TNTIP
2 Samuel 21 in the TNTIZ
2 Samuel 21 in the TOMA
2 Samuel 21 in the TTENT
2 Samuel 21 in the UBG
2 Samuel 21 in the UGV
2 Samuel 21 in the UGV2
2 Samuel 21 in the UGV3
2 Samuel 21 in the VBL
2 Samuel 21 in the VDCC
2 Samuel 21 in the YALU
2 Samuel 21 in the YAPE
2 Samuel 21 in the YBVTP
2 Samuel 21 in the ZBP