Amos 5 (BOYCB)
1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ: 2 “Wúńdíá Israẹli ṣubúláì kò sì le padà dìdeó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.” 3 Èyí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí:“Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde,yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli.Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jádeyóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.” 4 Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún ilé Israẹli:“Wá mi kí o sì yè; 5 ẹ má ṣe wá Beteli,ẹ má ṣe lọ sí Gilgali,ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba.Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn,A ó sì sọ Beteli di asán.” 6 Ẹ wá OLÚWA, ẹ̀yin yóò sì yè,kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfua sì jó o runBeteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á. 7 Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkoròtí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀. 8 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioniẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ OLÚWA ni orúkọ rẹ̀, 9 Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódití ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro. 10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodèó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́. 11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́léṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn. 12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹmo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́. 13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́. 14 Wá rere, má ṣe wá búburúkí ìwọ ba à le yè.Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí. 15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ reredúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́bóyá OLÚWA Ọlọ́run alágbárayóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù. 16 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónàigbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú.A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkúnàti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún. 17 Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà,nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”ni OLÚWA wí. 18 Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́nítorí ọjọ́ OLÚWAkí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ OLÚWA?Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́. 19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọtí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀tí ejò sì bù ú ṣán. 20 Ǹjẹ́ ọjọ́ OLÚWA kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀. 21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín. 22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.Èmi kò ní náání wọn. 23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn!Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín. 24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odòàti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ! 25 “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wání ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli? 26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè,ibùgbé àwọn òrìṣà yín,àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe. 27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”ni OLÚWA wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
In Other Versions
Amos 5 in the ANGEFD
Amos 5 in the ANTPNG2D
Amos 5 in the AS21
Amos 5 in the BAGH
Amos 5 in the BBPNG
Amos 5 in the BBT1E
Amos 5 in the BDS
Amos 5 in the BEV
Amos 5 in the BHAD
Amos 5 in the BIB
Amos 5 in the BLPT
Amos 5 in the BNT
Amos 5 in the BNTABOOT
Amos 5 in the BNTLV
Amos 5 in the BOATCB
Amos 5 in the BOATCB2
Amos 5 in the BOBCV
Amos 5 in the BOCNT
Amos 5 in the BOECS
Amos 5 in the BOGWICC
Amos 5 in the BOHCB
Amos 5 in the BOHCV
Amos 5 in the BOHLNT
Amos 5 in the BOHNTLTAL
Amos 5 in the BOICB
Amos 5 in the BOILNTAP
Amos 5 in the BOITCV
Amos 5 in the BOKCV
Amos 5 in the BOKCV2
Amos 5 in the BOKHWOG
Amos 5 in the BOKSSV
Amos 5 in the BOLCB
Amos 5 in the BOLCB2
Amos 5 in the BOMCV
Amos 5 in the BONAV
Amos 5 in the BONCB
Amos 5 in the BONLT
Amos 5 in the BONUT2
Amos 5 in the BOPLNT
Amos 5 in the BOSCB
Amos 5 in the BOSNC
Amos 5 in the BOTLNT
Amos 5 in the BOVCB
Amos 5 in the BPBB
Amos 5 in the BPH
Amos 5 in the BSB
Amos 5 in the CCB
Amos 5 in the CUV
Amos 5 in the CUVS
Amos 5 in the DBT
Amos 5 in the DGDNT
Amos 5 in the DHNT
Amos 5 in the DNT
Amos 5 in the ELBE
Amos 5 in the EMTV
Amos 5 in the ESV
Amos 5 in the FBV
Amos 5 in the FEB
Amos 5 in the GGMNT
Amos 5 in the GNT
Amos 5 in the HARY
Amos 5 in the HNT
Amos 5 in the IRVA
Amos 5 in the IRVB
Amos 5 in the IRVG
Amos 5 in the IRVH
Amos 5 in the IRVK
Amos 5 in the IRVM
Amos 5 in the IRVM2
Amos 5 in the IRVO
Amos 5 in the IRVP
Amos 5 in the IRVT
Amos 5 in the IRVT2
Amos 5 in the IRVU
Amos 5 in the ISVN
Amos 5 in the JSNT
Amos 5 in the KAPI
Amos 5 in the KBT1ETNIK
Amos 5 in the KBV
Amos 5 in the KJV
Amos 5 in the KNFD
Amos 5 in the LBA
Amos 5 in the LBLA
Amos 5 in the LNT
Amos 5 in the LSV
Amos 5 in the MAAL
Amos 5 in the MBV
Amos 5 in the MBV2
Amos 5 in the MHNT
Amos 5 in the MKNFD
Amos 5 in the MNG
Amos 5 in the MNT
Amos 5 in the MNT2
Amos 5 in the MRS1T
Amos 5 in the NAA
Amos 5 in the NASB
Amos 5 in the NBLA
Amos 5 in the NBS
Amos 5 in the NBVTP
Amos 5 in the NET2
Amos 5 in the NIV11
Amos 5 in the NNT
Amos 5 in the NNT2
Amos 5 in the NNT3
Amos 5 in the PDDPT
Amos 5 in the PFNT
Amos 5 in the RMNT
Amos 5 in the SBIAS
Amos 5 in the SBIBS
Amos 5 in the SBIBS2
Amos 5 in the SBICS
Amos 5 in the SBIDS
Amos 5 in the SBIGS
Amos 5 in the SBIHS
Amos 5 in the SBIIS
Amos 5 in the SBIIS2
Amos 5 in the SBIIS3
Amos 5 in the SBIKS
Amos 5 in the SBIKS2
Amos 5 in the SBIMS
Amos 5 in the SBIOS
Amos 5 in the SBIPS
Amos 5 in the SBISS
Amos 5 in the SBITS
Amos 5 in the SBITS2
Amos 5 in the SBITS3
Amos 5 in the SBITS4
Amos 5 in the SBIUS
Amos 5 in the SBIVS
Amos 5 in the SBT
Amos 5 in the SBT1E
Amos 5 in the SCHL
Amos 5 in the SNT
Amos 5 in the SUSU
Amos 5 in the SUSU2
Amos 5 in the SYNO
Amos 5 in the TBIAOTANT
Amos 5 in the TBT1E
Amos 5 in the TBT1E2
Amos 5 in the TFTIP
Amos 5 in the TFTU
Amos 5 in the TGNTATF3T
Amos 5 in the THAI
Amos 5 in the TNFD
Amos 5 in the TNT
Amos 5 in the TNTIK
Amos 5 in the TNTIL
Amos 5 in the TNTIN
Amos 5 in the TNTIP
Amos 5 in the TNTIZ
Amos 5 in the TOMA
Amos 5 in the TTENT
Amos 5 in the UBG
Amos 5 in the UGV
Amos 5 in the UGV2
Amos 5 in the UGV3
Amos 5 in the VBL
Amos 5 in the VDCC
Amos 5 in the YALU
Amos 5 in the YAPE
Amos 5 in the YBVTP
Amos 5 in the ZBP