Colossians 3 (BOYCB)
1 Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 2 Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. 3 Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. 4 Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo. 5 Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. 6 Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. 7 Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. 8 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. 9 Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, 10 tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. 11 Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. 12 Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13 Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. 14 Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé. 15 Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀. 18 Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. 19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn. 20 Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa. 21 Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì. 22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 23 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn; 24 kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè, nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi. 25 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbà á padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì ṣí ojúsàájú.
In Other Versions
Colossians 3 in the ANGEFD
Colossians 3 in the ANTPNG2D
Colossians 3 in the AS21
Colossians 3 in the BAGH
Colossians 3 in the BBPNG
Colossians 3 in the BBT1E
Colossians 3 in the BDS
Colossians 3 in the BEV
Colossians 3 in the BHAD
Colossians 3 in the BIB
Colossians 3 in the BLPT
Colossians 3 in the BNT
Colossians 3 in the BNTABOOT
Colossians 3 in the BNTLV
Colossians 3 in the BOATCB
Colossians 3 in the BOATCB2
Colossians 3 in the BOBCV
Colossians 3 in the BOCNT
Colossians 3 in the BOECS
Colossians 3 in the BOGWICC
Colossians 3 in the BOHCB
Colossians 3 in the BOHCV
Colossians 3 in the BOHLNT
Colossians 3 in the BOHNTLTAL
Colossians 3 in the BOICB
Colossians 3 in the BOILNTAP
Colossians 3 in the BOITCV
Colossians 3 in the BOKCV
Colossians 3 in the BOKCV2
Colossians 3 in the BOKHWOG
Colossians 3 in the BOKSSV
Colossians 3 in the BOLCB
Colossians 3 in the BOLCB2
Colossians 3 in the BOMCV
Colossians 3 in the BONAV
Colossians 3 in the BONCB
Colossians 3 in the BONLT
Colossians 3 in the BONUT2
Colossians 3 in the BOPLNT
Colossians 3 in the BOSCB
Colossians 3 in the BOSNC
Colossians 3 in the BOTLNT
Colossians 3 in the BOVCB
Colossians 3 in the BPBB
Colossians 3 in the BPH
Colossians 3 in the BSB
Colossians 3 in the CCB
Colossians 3 in the CUV
Colossians 3 in the CUVS
Colossians 3 in the DBT
Colossians 3 in the DGDNT
Colossians 3 in the DHNT
Colossians 3 in the DNT
Colossians 3 in the ELBE
Colossians 3 in the EMTV
Colossians 3 in the ESV
Colossians 3 in the FBV
Colossians 3 in the FEB
Colossians 3 in the GGMNT
Colossians 3 in the GNT
Colossians 3 in the HARY
Colossians 3 in the HNT
Colossians 3 in the IRVA
Colossians 3 in the IRVB
Colossians 3 in the IRVG
Colossians 3 in the IRVH
Colossians 3 in the IRVK
Colossians 3 in the IRVM
Colossians 3 in the IRVM2
Colossians 3 in the IRVO
Colossians 3 in the IRVP
Colossians 3 in the IRVT
Colossians 3 in the IRVT2
Colossians 3 in the IRVU
Colossians 3 in the ISVN
Colossians 3 in the JSNT
Colossians 3 in the KAPI
Colossians 3 in the KBT1ETNIK
Colossians 3 in the KBV
Colossians 3 in the KJV
Colossians 3 in the KNFD
Colossians 3 in the LBA
Colossians 3 in the LBLA
Colossians 3 in the LNT
Colossians 3 in the LSV
Colossians 3 in the MAAL
Colossians 3 in the MBV
Colossians 3 in the MBV2
Colossians 3 in the MHNT
Colossians 3 in the MKNFD
Colossians 3 in the MNG
Colossians 3 in the MNT
Colossians 3 in the MNT2
Colossians 3 in the MRS1T
Colossians 3 in the NAA
Colossians 3 in the NASB
Colossians 3 in the NBLA
Colossians 3 in the NBS
Colossians 3 in the NBVTP
Colossians 3 in the NET2
Colossians 3 in the NIV11
Colossians 3 in the NNT
Colossians 3 in the NNT2
Colossians 3 in the NNT3
Colossians 3 in the PDDPT
Colossians 3 in the PFNT
Colossians 3 in the RMNT
Colossians 3 in the SBIAS
Colossians 3 in the SBIBS
Colossians 3 in the SBIBS2
Colossians 3 in the SBICS
Colossians 3 in the SBIDS
Colossians 3 in the SBIGS
Colossians 3 in the SBIHS
Colossians 3 in the SBIIS
Colossians 3 in the SBIIS2
Colossians 3 in the SBIIS3
Colossians 3 in the SBIKS
Colossians 3 in the SBIKS2
Colossians 3 in the SBIMS
Colossians 3 in the SBIOS
Colossians 3 in the SBIPS
Colossians 3 in the SBISS
Colossians 3 in the SBITS
Colossians 3 in the SBITS2
Colossians 3 in the SBITS3
Colossians 3 in the SBITS4
Colossians 3 in the SBIUS
Colossians 3 in the SBIVS
Colossians 3 in the SBT
Colossians 3 in the SBT1E
Colossians 3 in the SCHL
Colossians 3 in the SNT
Colossians 3 in the SUSU
Colossians 3 in the SUSU2
Colossians 3 in the SYNO
Colossians 3 in the TBIAOTANT
Colossians 3 in the TBT1E
Colossians 3 in the TBT1E2
Colossians 3 in the TFTIP
Colossians 3 in the TFTU
Colossians 3 in the TGNTATF3T
Colossians 3 in the THAI
Colossians 3 in the TNFD
Colossians 3 in the TNT
Colossians 3 in the TNTIK
Colossians 3 in the TNTIL
Colossians 3 in the TNTIN
Colossians 3 in the TNTIP
Colossians 3 in the TNTIZ
Colossians 3 in the TOMA
Colossians 3 in the TTENT
Colossians 3 in the UBG
Colossians 3 in the UGV
Colossians 3 in the UGV2
Colossians 3 in the UGV3
Colossians 3 in the VBL
Colossians 3 in the VDCC
Colossians 3 in the YALU
Colossians 3 in the YAPE
Colossians 3 in the YBVTP
Colossians 3 in the ZBP