Deuteronomy 24 (BOYCB)
        
        
          1 Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, tí ó sì gbe ní ìyàwó, yóò sì ṣe, bí obìnrin náà kò bá rí ojúrere ní ojú ọkùnrin náà, nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan lára rẹ̀, ǹjẹ́ kí ó kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún obìnrin náà, kí ó sì fi lé e lọ́wọ́, kí ó sì ran jáde kúrò nínú ilé rẹ̀, 2 tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ, 3 àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú, 4 nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú OLÚWA. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.  5 Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.  6 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsè, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní pàṣípàrọ̀ n nì.  7 Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tà á, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹ ní láti wẹ búburú kúrò láàrín yín.  8 Ní ti ààrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pàṣẹ fún wọn. 9 Rántí ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ṣe sí Miriamu lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Ejibiti.  10 Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí. 11 Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògo rẹ jáde wá fún ọ. 12 Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ tálákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ. 13 Dá aṣọ ìlekè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó bá à le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì máa jásí ìwà òdodo níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ.  14 Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ. 15 San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe OLÚWA sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.  16 Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.  17 Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí. 18 Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.  19 Nígbà tí o bá ń kórè oko rẹ tí o sì fojú fo ìtí kan, má ṣe padà lọ mú u. Fi í kalẹ̀ fún àwọn àlejò, aláìní baba àti opó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún fún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. 20 Nígbà tí o bá ń gun igi olifi lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. 21 Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó. 22 Rántí pé ìwọ ti jẹ́ àlejò ní Ejibiti. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
        
        
          In Other Versions
        
        
  
    Deuteronomy 24 in the ANGEFD
  
  
    Deuteronomy 24 in the ANTPNG2D
  
  
    Deuteronomy 24 in the AS21
  
  
    Deuteronomy 24 in the BAGH
  
  
    Deuteronomy 24 in the BBPNG
  
  
    Deuteronomy 24 in the BBT1E
  
  
    Deuteronomy 24 in the BDS
  
  
    Deuteronomy 24 in the BEV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BHAD
  
  
    Deuteronomy 24 in the BIB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BLPT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BNTABOOT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BNTLV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOATCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOATCB2
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOBCV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOCNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOECS
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOGWICC
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOHCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOHCV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOHLNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOHNTLTAL
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOICB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOILNTAP
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOITCV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOKCV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOKCV2
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOKHWOG
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOKSSV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOLCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOLCB2
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOMCV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BONAV
  
  
    Deuteronomy 24 in the BONCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BONLT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BONUT2
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOPLNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOSCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOSNC
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOTLNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the BOVCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BPBB
  
  
    Deuteronomy 24 in the BPH
  
  
    Deuteronomy 24 in the BSB
  
  
    Deuteronomy 24 in the CCB
  
  
    Deuteronomy 24 in the CUV
  
  
    Deuteronomy 24 in the CUVS
  
  
    Deuteronomy 24 in the DBT
  
  
    Deuteronomy 24 in the DGDNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the DHNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the DNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the ELBE
  
  
    Deuteronomy 24 in the EMTV
  
  
    Deuteronomy 24 in the ESV
  
  
    Deuteronomy 24 in the FBV
  
  
    Deuteronomy 24 in the FEB
  
  
    Deuteronomy 24 in the GGMNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the GNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the HARY
  
  
    Deuteronomy 24 in the HNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVA
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVB
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVG
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVH
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVK
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVM
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVM2
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVO
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVP
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVT
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVT2
  
  
    Deuteronomy 24 in the IRVU
  
  
    Deuteronomy 24 in the ISVN
  
  
    Deuteronomy 24 in the JSNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the KAPI
  
  
    Deuteronomy 24 in the KBT1ETNIK
  
  
    Deuteronomy 24 in the KBV
  
  
    Deuteronomy 24 in the KJV
  
  
    Deuteronomy 24 in the KNFD
  
  
    Deuteronomy 24 in the LBA
  
  
    Deuteronomy 24 in the LBLA
  
  
    Deuteronomy 24 in the LNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the LSV
  
  
    Deuteronomy 24 in the MAAL
  
  
    Deuteronomy 24 in the MBV
  
  
    Deuteronomy 24 in the MBV2
  
  
    Deuteronomy 24 in the MHNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the MKNFD
  
  
    Deuteronomy 24 in the MNG
  
  
    Deuteronomy 24 in the MNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the MNT2
  
  
    Deuteronomy 24 in the MRS1T
  
  
    Deuteronomy 24 in the NAA
  
  
    Deuteronomy 24 in the NASB
  
  
    Deuteronomy 24 in the NBLA
  
  
    Deuteronomy 24 in the NBS
  
  
    Deuteronomy 24 in the NBVTP
  
  
    Deuteronomy 24 in the NET2
  
  
    Deuteronomy 24 in the NIV11
  
  
    Deuteronomy 24 in the NNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the NNT2
  
  
    Deuteronomy 24 in the NNT3
  
  
    Deuteronomy 24 in the PDDPT
  
  
    Deuteronomy 24 in the PFNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the RMNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIAS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIBS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIBS2
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBICS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIDS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIGS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIHS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIIS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIIS2
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIIS3
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIKS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIKS2
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIMS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIOS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIPS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBISS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBITS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBITS2
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBITS3
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBITS4
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIUS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBIVS
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBT
  
  
    Deuteronomy 24 in the SBT1E
  
  
    Deuteronomy 24 in the SCHL
  
  
    Deuteronomy 24 in the SNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the SUSU
  
  
    Deuteronomy 24 in the SUSU2
  
  
    Deuteronomy 24 in the SYNO
  
  
    Deuteronomy 24 in the TBIAOTANT
  
  
    Deuteronomy 24 in the TBT1E
  
  
    Deuteronomy 24 in the TBT1E2
  
  
    Deuteronomy 24 in the TFTIP
  
  
    Deuteronomy 24 in the TFTU
  
  
    Deuteronomy 24 in the TGNTATF3T
  
  
    Deuteronomy 24 in the THAI
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNFD
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNT
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNTIK
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNTIL
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNTIN
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNTIP
  
  
    Deuteronomy 24 in the TNTIZ
  
  
    Deuteronomy 24 in the TOMA
  
  
    Deuteronomy 24 in the TTENT
  
  
    Deuteronomy 24 in the UBG
  
  
    Deuteronomy 24 in the UGV
  
  
    Deuteronomy 24 in the UGV2
  
  
    Deuteronomy 24 in the UGV3
  
  
    Deuteronomy 24 in the VBL
  
  
    Deuteronomy 24 in the VDCC
  
  
    Deuteronomy 24 in the YALU
  
  
    Deuteronomy 24 in the YAPE
  
  
    Deuteronomy 24 in the YBVTP
  
  
    Deuteronomy 24 in the ZBP