Deuteronomy 3 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei. 2 OLÚWA sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. Kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.” 3 Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. 4 Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta ìlú tí wọ́n ní, gbogbo agbègbè Argobu, lábẹ́ ìjọba Ogu ní Baṣani. 5 Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kéékèèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú. 6 Gbogbo wọn ni a parun pátápátá gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Sihoni ọba Heṣboni, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátápátá: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn. 7 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú wọn, fún ara wa. 8 Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jordani láti odò Arnoni, títí dé orí òkè Hermoni lọ́wọ́ àwọn ọba Amori méjèèjì wọ̀nyí. 9 (Àwọn ará Sidoni ń pe Hermoni ní Sirioni. Àwọn Amori sì ń pè é ní Seniri). 10 Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gileadi, àti gbogbo Baṣani, títí dé Saleka, àti Edrei, ìlú àwọn ọba Ogu ní ilẹ̀ Baṣani. 11 (Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.) 12 Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn. 13 Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu. 14 Jairi ọ̀kan nínú àwọn ìran Manase gba gbogbo agbègbè Argobu títí dé ààlà àwọn ará Geṣuri àti àwọn ará Maakati; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Baṣani fi ń jẹ́ Hafoti-Jairi títí di òní.) 15 Mo sì fi Gileadi fún Makiri, 16 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Reubeni àti ọmọ Gadi ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gileadi lọ dé odò Arnoni (àárín odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jabbok. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ammoni. 17 Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun Iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn. 18 Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “OLÚWA Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli. 19 Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín, 20 títí di ìgbà tí OLÚWA yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jordani. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.” 21 Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Joṣua pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ. 22 Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, OLÚWA Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.” 23 Nígbà náà ni mo bẹ OLÚWA wí pé, 24 “OLÚWA Olódùmarè, ìwọ tí bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe? 25 Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jordani, ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lebanoni.” 26 Ṣùgbọ́n torí i tiyín, OLÚWA Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. OLÚWA sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́. 27 Gòkè lọ sí orí òkè Pisga, sì wò yíká ìwọ̀-oòrùn, ìlà-oòrùn, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jordani yìí. 28 Ṣùgbọ́n yan Joṣua, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.” 29 Báyìí ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Beti-Peori.

In Other Versions

Deuteronomy 3 in the ANGEFD

Deuteronomy 3 in the ANTPNG2D

Deuteronomy 3 in the AS21

Deuteronomy 3 in the BAGH

Deuteronomy 3 in the BBPNG

Deuteronomy 3 in the BBT1E

Deuteronomy 3 in the BDS

Deuteronomy 3 in the BEV

Deuteronomy 3 in the BHAD

Deuteronomy 3 in the BIB

Deuteronomy 3 in the BLPT

Deuteronomy 3 in the BNT

Deuteronomy 3 in the BNTABOOT

Deuteronomy 3 in the BNTLV

Deuteronomy 3 in the BOATCB

Deuteronomy 3 in the BOATCB2

Deuteronomy 3 in the BOBCV

Deuteronomy 3 in the BOCNT

Deuteronomy 3 in the BOECS

Deuteronomy 3 in the BOGWICC

Deuteronomy 3 in the BOHCB

Deuteronomy 3 in the BOHCV

Deuteronomy 3 in the BOHLNT

Deuteronomy 3 in the BOHNTLTAL

Deuteronomy 3 in the BOICB

Deuteronomy 3 in the BOILNTAP

Deuteronomy 3 in the BOITCV

Deuteronomy 3 in the BOKCV

Deuteronomy 3 in the BOKCV2

Deuteronomy 3 in the BOKHWOG

Deuteronomy 3 in the BOKSSV

Deuteronomy 3 in the BOLCB

Deuteronomy 3 in the BOLCB2

Deuteronomy 3 in the BOMCV

Deuteronomy 3 in the BONAV

Deuteronomy 3 in the BONCB

Deuteronomy 3 in the BONLT

Deuteronomy 3 in the BONUT2

Deuteronomy 3 in the BOPLNT

Deuteronomy 3 in the BOSCB

Deuteronomy 3 in the BOSNC

Deuteronomy 3 in the BOTLNT

Deuteronomy 3 in the BOVCB

Deuteronomy 3 in the BPBB

Deuteronomy 3 in the BPH

Deuteronomy 3 in the BSB

Deuteronomy 3 in the CCB

Deuteronomy 3 in the CUV

Deuteronomy 3 in the CUVS

Deuteronomy 3 in the DBT

Deuteronomy 3 in the DGDNT

Deuteronomy 3 in the DHNT

Deuteronomy 3 in the DNT

Deuteronomy 3 in the ELBE

Deuteronomy 3 in the EMTV

Deuteronomy 3 in the ESV

Deuteronomy 3 in the FBV

Deuteronomy 3 in the FEB

Deuteronomy 3 in the GGMNT

Deuteronomy 3 in the GNT

Deuteronomy 3 in the HARY

Deuteronomy 3 in the HNT

Deuteronomy 3 in the IRVA

Deuteronomy 3 in the IRVB

Deuteronomy 3 in the IRVG

Deuteronomy 3 in the IRVH

Deuteronomy 3 in the IRVK

Deuteronomy 3 in the IRVM

Deuteronomy 3 in the IRVM2

Deuteronomy 3 in the IRVO

Deuteronomy 3 in the IRVP

Deuteronomy 3 in the IRVT

Deuteronomy 3 in the IRVT2

Deuteronomy 3 in the IRVU

Deuteronomy 3 in the ISVN

Deuteronomy 3 in the JSNT

Deuteronomy 3 in the KAPI

Deuteronomy 3 in the KBT1ETNIK

Deuteronomy 3 in the KBV

Deuteronomy 3 in the KJV

Deuteronomy 3 in the KNFD

Deuteronomy 3 in the LBA

Deuteronomy 3 in the LBLA

Deuteronomy 3 in the LNT

Deuteronomy 3 in the LSV

Deuteronomy 3 in the MAAL

Deuteronomy 3 in the MBV

Deuteronomy 3 in the MBV2

Deuteronomy 3 in the MHNT

Deuteronomy 3 in the MKNFD

Deuteronomy 3 in the MNG

Deuteronomy 3 in the MNT

Deuteronomy 3 in the MNT2

Deuteronomy 3 in the MRS1T

Deuteronomy 3 in the NAA

Deuteronomy 3 in the NASB

Deuteronomy 3 in the NBLA

Deuteronomy 3 in the NBS

Deuteronomy 3 in the NBVTP

Deuteronomy 3 in the NET2

Deuteronomy 3 in the NIV11

Deuteronomy 3 in the NNT

Deuteronomy 3 in the NNT2

Deuteronomy 3 in the NNT3

Deuteronomy 3 in the PDDPT

Deuteronomy 3 in the PFNT

Deuteronomy 3 in the RMNT

Deuteronomy 3 in the SBIAS

Deuteronomy 3 in the SBIBS

Deuteronomy 3 in the SBIBS2

Deuteronomy 3 in the SBICS

Deuteronomy 3 in the SBIDS

Deuteronomy 3 in the SBIGS

Deuteronomy 3 in the SBIHS

Deuteronomy 3 in the SBIIS

Deuteronomy 3 in the SBIIS2

Deuteronomy 3 in the SBIIS3

Deuteronomy 3 in the SBIKS

Deuteronomy 3 in the SBIKS2

Deuteronomy 3 in the SBIMS

Deuteronomy 3 in the SBIOS

Deuteronomy 3 in the SBIPS

Deuteronomy 3 in the SBISS

Deuteronomy 3 in the SBITS

Deuteronomy 3 in the SBITS2

Deuteronomy 3 in the SBITS3

Deuteronomy 3 in the SBITS4

Deuteronomy 3 in the SBIUS

Deuteronomy 3 in the SBIVS

Deuteronomy 3 in the SBT

Deuteronomy 3 in the SBT1E

Deuteronomy 3 in the SCHL

Deuteronomy 3 in the SNT

Deuteronomy 3 in the SUSU

Deuteronomy 3 in the SUSU2

Deuteronomy 3 in the SYNO

Deuteronomy 3 in the TBIAOTANT

Deuteronomy 3 in the TBT1E

Deuteronomy 3 in the TBT1E2

Deuteronomy 3 in the TFTIP

Deuteronomy 3 in the TFTU

Deuteronomy 3 in the TGNTATF3T

Deuteronomy 3 in the THAI

Deuteronomy 3 in the TNFD

Deuteronomy 3 in the TNT

Deuteronomy 3 in the TNTIK

Deuteronomy 3 in the TNTIL

Deuteronomy 3 in the TNTIN

Deuteronomy 3 in the TNTIP

Deuteronomy 3 in the TNTIZ

Deuteronomy 3 in the TOMA

Deuteronomy 3 in the TTENT

Deuteronomy 3 in the UBG

Deuteronomy 3 in the UGV

Deuteronomy 3 in the UGV2

Deuteronomy 3 in the UGV3

Deuteronomy 3 in the VBL

Deuteronomy 3 in the VDCC

Deuteronomy 3 in the YALU

Deuteronomy 3 in the YAPE

Deuteronomy 3 in the YBVTP

Deuteronomy 3 in the ZBP