Exodus 33 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ 2 Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, Èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde. 3 Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.” 4 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀. 5 Nítorí OLÚWA ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn Ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí Èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, Èmi lè pa yín run. Nísìnsinyìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, Èmi yóò sì gbèrò ohun tí Èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ” 6 Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu. 7 Mose máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń béèrè OLÚWA yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó. 8 Nígbàkígbà tí Mose bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mose títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà. 9 Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí OLÚWA ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. 10 Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. 11 OLÚWA máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀. 12 Mose sọ fún OLÚWA pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’ 13 Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.” 14 OLÚWA dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.” 15 Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16 Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?” 17 OLÚWA sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, Èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.” 18 Mose sì wí pé, “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.” 19 OLÚWA sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ OLÚWA níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí Èmi yóò ṣàánú fún, Èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí Èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún. 20 Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.” 21 OLÚWA sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta. 22 Nígbà tí ògo mi bá kọjá, Èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, Èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí Èmi yóò fi rékọjá. 23 Nígbà tí Èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”
In Other Versions
Exodus 33 in the ANGEFD
Exodus 33 in the ANTPNG2D
Exodus 33 in the AS21
Exodus 33 in the BAGH
Exodus 33 in the BBPNG
Exodus 33 in the BBT1E
Exodus 33 in the BDS
Exodus 33 in the BEV
Exodus 33 in the BHAD
Exodus 33 in the BIB
Exodus 33 in the BLPT
Exodus 33 in the BNT
Exodus 33 in the BNTABOOT
Exodus 33 in the BNTLV
Exodus 33 in the BOATCB
Exodus 33 in the BOATCB2
Exodus 33 in the BOBCV
Exodus 33 in the BOCNT
Exodus 33 in the BOECS
Exodus 33 in the BOGWICC
Exodus 33 in the BOHCB
Exodus 33 in the BOHCV
Exodus 33 in the BOHLNT
Exodus 33 in the BOHNTLTAL
Exodus 33 in the BOICB
Exodus 33 in the BOILNTAP
Exodus 33 in the BOITCV
Exodus 33 in the BOKCV
Exodus 33 in the BOKCV2
Exodus 33 in the BOKHWOG
Exodus 33 in the BOKSSV
Exodus 33 in the BOLCB
Exodus 33 in the BOLCB2
Exodus 33 in the BOMCV
Exodus 33 in the BONAV
Exodus 33 in the BONCB
Exodus 33 in the BONLT
Exodus 33 in the BONUT2
Exodus 33 in the BOPLNT
Exodus 33 in the BOSCB
Exodus 33 in the BOSNC
Exodus 33 in the BOTLNT
Exodus 33 in the BOVCB
Exodus 33 in the BPBB
Exodus 33 in the BPH
Exodus 33 in the BSB
Exodus 33 in the CCB
Exodus 33 in the CUV
Exodus 33 in the CUVS
Exodus 33 in the DBT
Exodus 33 in the DGDNT
Exodus 33 in the DHNT
Exodus 33 in the DNT
Exodus 33 in the ELBE
Exodus 33 in the EMTV
Exodus 33 in the ESV
Exodus 33 in the FBV
Exodus 33 in the FEB
Exodus 33 in the GGMNT
Exodus 33 in the GNT
Exodus 33 in the HARY
Exodus 33 in the HNT
Exodus 33 in the IRVA
Exodus 33 in the IRVB
Exodus 33 in the IRVG
Exodus 33 in the IRVH
Exodus 33 in the IRVK
Exodus 33 in the IRVM
Exodus 33 in the IRVM2
Exodus 33 in the IRVO
Exodus 33 in the IRVP
Exodus 33 in the IRVT
Exodus 33 in the IRVT2
Exodus 33 in the IRVU
Exodus 33 in the ISVN
Exodus 33 in the JSNT
Exodus 33 in the KAPI
Exodus 33 in the KBT1ETNIK
Exodus 33 in the KBV
Exodus 33 in the KJV
Exodus 33 in the KNFD
Exodus 33 in the LBA
Exodus 33 in the LBLA
Exodus 33 in the LNT
Exodus 33 in the LSV
Exodus 33 in the MAAL
Exodus 33 in the MBV
Exodus 33 in the MBV2
Exodus 33 in the MHNT
Exodus 33 in the MKNFD
Exodus 33 in the MNG
Exodus 33 in the MNT
Exodus 33 in the MNT2
Exodus 33 in the MRS1T
Exodus 33 in the NAA
Exodus 33 in the NASB
Exodus 33 in the NBLA
Exodus 33 in the NBS
Exodus 33 in the NBVTP
Exodus 33 in the NET2
Exodus 33 in the NIV11
Exodus 33 in the NNT
Exodus 33 in the NNT2
Exodus 33 in the NNT3
Exodus 33 in the PDDPT
Exodus 33 in the PFNT
Exodus 33 in the RMNT
Exodus 33 in the SBIAS
Exodus 33 in the SBIBS
Exodus 33 in the SBIBS2
Exodus 33 in the SBICS
Exodus 33 in the SBIDS
Exodus 33 in the SBIGS
Exodus 33 in the SBIHS
Exodus 33 in the SBIIS
Exodus 33 in the SBIIS2
Exodus 33 in the SBIIS3
Exodus 33 in the SBIKS
Exodus 33 in the SBIKS2
Exodus 33 in the SBIMS
Exodus 33 in the SBIOS
Exodus 33 in the SBIPS
Exodus 33 in the SBISS
Exodus 33 in the SBITS
Exodus 33 in the SBITS2
Exodus 33 in the SBITS3
Exodus 33 in the SBITS4
Exodus 33 in the SBIUS
Exodus 33 in the SBIVS
Exodus 33 in the SBT
Exodus 33 in the SBT1E
Exodus 33 in the SCHL
Exodus 33 in the SNT
Exodus 33 in the SUSU
Exodus 33 in the SUSU2
Exodus 33 in the SYNO
Exodus 33 in the TBIAOTANT
Exodus 33 in the TBT1E
Exodus 33 in the TBT1E2
Exodus 33 in the TFTIP
Exodus 33 in the TFTU
Exodus 33 in the TGNTATF3T
Exodus 33 in the THAI
Exodus 33 in the TNFD
Exodus 33 in the TNT
Exodus 33 in the TNTIK
Exodus 33 in the TNTIL
Exodus 33 in the TNTIN
Exodus 33 in the TNTIP
Exodus 33 in the TNTIZ
Exodus 33 in the TOMA
Exodus 33 in the TTENT
Exodus 33 in the UBG
Exodus 33 in the UGV
Exodus 33 in the UGV2
Exodus 33 in the UGV3
Exodus 33 in the VBL
Exodus 33 in the VDCC
Exodus 33 in the YALU
Exodus 33 in the YAPE
Exodus 33 in the YBVTP
Exodus 33 in the ZBP