Ezekiel 47 (BOYCB)
1 Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn). Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ. 2 Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá. 3 Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ. 4 Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. 5 Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. 6 Ó bi mí léèrè pé, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. 7 Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. 8 Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá. 9 Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. 10 Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. 11 Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. 12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.” 13 Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu. 14 Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín. 15 “Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà: “Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi Òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hetiloni gbà tí Hamati lọ sí Sedadi, 16 Berota àti Sibraimu, èyí tí ó wà ní ààlà láàrín Damasku àti Hamati títí dé Hasari Hatikonu, èyí tí ó wà ní agbègbè Haurani. 17 Ààlà yóò fẹ̀ láti Òkun lọ sí Hasari Enanu, ní apá ààlà ti Damasku, pẹ̀lú ààlà tí Hamati lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá. 18 Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn. 19 Ní ìhà gúúsù yóò lọ láti Tamari títí dé ibi omi Meriba Kadeṣi, lẹ́yìn náà ni ìhà Wadi tí Ejibiti lọ sí Òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúúsù. 20 Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, Òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hamati. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀-oòrùn. 21 “Ìwọ ní láti pín ilẹ̀ yìí ní àárín ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Israẹli. 22 Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé ní àárín yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Israẹli; papọ̀ mọ́ yin ni kí ẹ pín ìní fún wọn ní àárín àwọn ẹ̀yà Israẹli. 23 Ní àárín gbogbo ẹ̀yà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún un,” ní OLÚWA Olódùmarè wí.
In Other Versions
Ezekiel 47 in the ANGEFD
Ezekiel 47 in the ANTPNG2D
Ezekiel 47 in the AS21
Ezekiel 47 in the BAGH
Ezekiel 47 in the BBPNG
Ezekiel 47 in the BBT1E
Ezekiel 47 in the BDS
Ezekiel 47 in the BEV
Ezekiel 47 in the BHAD
Ezekiel 47 in the BIB
Ezekiel 47 in the BLPT
Ezekiel 47 in the BNT
Ezekiel 47 in the BNTABOOT
Ezekiel 47 in the BNTLV
Ezekiel 47 in the BOATCB
Ezekiel 47 in the BOATCB2
Ezekiel 47 in the BOBCV
Ezekiel 47 in the BOCNT
Ezekiel 47 in the BOECS
Ezekiel 47 in the BOGWICC
Ezekiel 47 in the BOHCB
Ezekiel 47 in the BOHCV
Ezekiel 47 in the BOHLNT
Ezekiel 47 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 47 in the BOICB
Ezekiel 47 in the BOILNTAP
Ezekiel 47 in the BOITCV
Ezekiel 47 in the BOKCV
Ezekiel 47 in the BOKCV2
Ezekiel 47 in the BOKHWOG
Ezekiel 47 in the BOKSSV
Ezekiel 47 in the BOLCB
Ezekiel 47 in the BOLCB2
Ezekiel 47 in the BOMCV
Ezekiel 47 in the BONAV
Ezekiel 47 in the BONCB
Ezekiel 47 in the BONLT
Ezekiel 47 in the BONUT2
Ezekiel 47 in the BOPLNT
Ezekiel 47 in the BOSCB
Ezekiel 47 in the BOSNC
Ezekiel 47 in the BOTLNT
Ezekiel 47 in the BOVCB
Ezekiel 47 in the BPBB
Ezekiel 47 in the BPH
Ezekiel 47 in the BSB
Ezekiel 47 in the CCB
Ezekiel 47 in the CUV
Ezekiel 47 in the CUVS
Ezekiel 47 in the DBT
Ezekiel 47 in the DGDNT
Ezekiel 47 in the DHNT
Ezekiel 47 in the DNT
Ezekiel 47 in the ELBE
Ezekiel 47 in the EMTV
Ezekiel 47 in the ESV
Ezekiel 47 in the FBV
Ezekiel 47 in the FEB
Ezekiel 47 in the GGMNT
Ezekiel 47 in the GNT
Ezekiel 47 in the HARY
Ezekiel 47 in the HNT
Ezekiel 47 in the IRVA
Ezekiel 47 in the IRVB
Ezekiel 47 in the IRVG
Ezekiel 47 in the IRVH
Ezekiel 47 in the IRVK
Ezekiel 47 in the IRVM
Ezekiel 47 in the IRVM2
Ezekiel 47 in the IRVO
Ezekiel 47 in the IRVP
Ezekiel 47 in the IRVT
Ezekiel 47 in the IRVT2
Ezekiel 47 in the IRVU
Ezekiel 47 in the ISVN
Ezekiel 47 in the JSNT
Ezekiel 47 in the KAPI
Ezekiel 47 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 47 in the KBV
Ezekiel 47 in the KJV
Ezekiel 47 in the KNFD
Ezekiel 47 in the LBA
Ezekiel 47 in the LBLA
Ezekiel 47 in the LNT
Ezekiel 47 in the LSV
Ezekiel 47 in the MAAL
Ezekiel 47 in the MBV
Ezekiel 47 in the MBV2
Ezekiel 47 in the MHNT
Ezekiel 47 in the MKNFD
Ezekiel 47 in the MNG
Ezekiel 47 in the MNT
Ezekiel 47 in the MNT2
Ezekiel 47 in the MRS1T
Ezekiel 47 in the NAA
Ezekiel 47 in the NASB
Ezekiel 47 in the NBLA
Ezekiel 47 in the NBS
Ezekiel 47 in the NBVTP
Ezekiel 47 in the NET2
Ezekiel 47 in the NIV11
Ezekiel 47 in the NNT
Ezekiel 47 in the NNT2
Ezekiel 47 in the NNT3
Ezekiel 47 in the PDDPT
Ezekiel 47 in the PFNT
Ezekiel 47 in the RMNT
Ezekiel 47 in the SBIAS
Ezekiel 47 in the SBIBS
Ezekiel 47 in the SBIBS2
Ezekiel 47 in the SBICS
Ezekiel 47 in the SBIDS
Ezekiel 47 in the SBIGS
Ezekiel 47 in the SBIHS
Ezekiel 47 in the SBIIS
Ezekiel 47 in the SBIIS2
Ezekiel 47 in the SBIIS3
Ezekiel 47 in the SBIKS
Ezekiel 47 in the SBIKS2
Ezekiel 47 in the SBIMS
Ezekiel 47 in the SBIOS
Ezekiel 47 in the SBIPS
Ezekiel 47 in the SBISS
Ezekiel 47 in the SBITS
Ezekiel 47 in the SBITS2
Ezekiel 47 in the SBITS3
Ezekiel 47 in the SBITS4
Ezekiel 47 in the SBIUS
Ezekiel 47 in the SBIVS
Ezekiel 47 in the SBT
Ezekiel 47 in the SBT1E
Ezekiel 47 in the SCHL
Ezekiel 47 in the SNT
Ezekiel 47 in the SUSU
Ezekiel 47 in the SUSU2
Ezekiel 47 in the SYNO
Ezekiel 47 in the TBIAOTANT
Ezekiel 47 in the TBT1E
Ezekiel 47 in the TBT1E2
Ezekiel 47 in the TFTIP
Ezekiel 47 in the TFTU
Ezekiel 47 in the TGNTATF3T
Ezekiel 47 in the THAI
Ezekiel 47 in the TNFD
Ezekiel 47 in the TNT
Ezekiel 47 in the TNTIK
Ezekiel 47 in the TNTIL
Ezekiel 47 in the TNTIN
Ezekiel 47 in the TNTIP
Ezekiel 47 in the TNTIZ
Ezekiel 47 in the TOMA
Ezekiel 47 in the TTENT
Ezekiel 47 in the UBG
Ezekiel 47 in the UGV
Ezekiel 47 in the UGV2
Ezekiel 47 in the UGV3
Ezekiel 47 in the VBL
Ezekiel 47 in the VDCC
Ezekiel 47 in the YALU
Ezekiel 47 in the YAPE
Ezekiel 47 in the YBVTP
Ezekiel 47 in the ZBP