Ezekiel 5 (BOYCB)

1 “Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in. 2 Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká. 3 Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ. 4 Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli. 5 “Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn Orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká. 6 Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́. 7 “Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. 8 “Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká. 9 Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́. 10 Nítorí náà láàrín rẹ àwọn baba yóò máa jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. Èmi yóò jẹ ọ́ ní yà, èmi yóò sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú ẹ̀fúùfù. 11 Nítorí náà, OLÚWA Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́. 12 Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn. 13 “Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé, Èmi OLÚWA ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi. 14 “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá. 15 O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi OLÚWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀. 16 Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín. 17 Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi OLÚWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

In Other Versions

Ezekiel 5 in the ANGEFD

Ezekiel 5 in the ANTPNG2D

Ezekiel 5 in the AS21

Ezekiel 5 in the BAGH

Ezekiel 5 in the BBPNG

Ezekiel 5 in the BBT1E

Ezekiel 5 in the BDS

Ezekiel 5 in the BEV

Ezekiel 5 in the BHAD

Ezekiel 5 in the BIB

Ezekiel 5 in the BLPT

Ezekiel 5 in the BNT

Ezekiel 5 in the BNTABOOT

Ezekiel 5 in the BNTLV

Ezekiel 5 in the BOATCB

Ezekiel 5 in the BOATCB2

Ezekiel 5 in the BOBCV

Ezekiel 5 in the BOCNT

Ezekiel 5 in the BOECS

Ezekiel 5 in the BOGWICC

Ezekiel 5 in the BOHCB

Ezekiel 5 in the BOHCV

Ezekiel 5 in the BOHLNT

Ezekiel 5 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 5 in the BOICB

Ezekiel 5 in the BOILNTAP

Ezekiel 5 in the BOITCV

Ezekiel 5 in the BOKCV

Ezekiel 5 in the BOKCV2

Ezekiel 5 in the BOKHWOG

Ezekiel 5 in the BOKSSV

Ezekiel 5 in the BOLCB

Ezekiel 5 in the BOLCB2

Ezekiel 5 in the BOMCV

Ezekiel 5 in the BONAV

Ezekiel 5 in the BONCB

Ezekiel 5 in the BONLT

Ezekiel 5 in the BONUT2

Ezekiel 5 in the BOPLNT

Ezekiel 5 in the BOSCB

Ezekiel 5 in the BOSNC

Ezekiel 5 in the BOTLNT

Ezekiel 5 in the BOVCB

Ezekiel 5 in the BPBB

Ezekiel 5 in the BPH

Ezekiel 5 in the BSB

Ezekiel 5 in the CCB

Ezekiel 5 in the CUV

Ezekiel 5 in the CUVS

Ezekiel 5 in the DBT

Ezekiel 5 in the DGDNT

Ezekiel 5 in the DHNT

Ezekiel 5 in the DNT

Ezekiel 5 in the ELBE

Ezekiel 5 in the EMTV

Ezekiel 5 in the ESV

Ezekiel 5 in the FBV

Ezekiel 5 in the FEB

Ezekiel 5 in the GGMNT

Ezekiel 5 in the GNT

Ezekiel 5 in the HARY

Ezekiel 5 in the HNT

Ezekiel 5 in the IRVA

Ezekiel 5 in the IRVB

Ezekiel 5 in the IRVG

Ezekiel 5 in the IRVH

Ezekiel 5 in the IRVK

Ezekiel 5 in the IRVM

Ezekiel 5 in the IRVM2

Ezekiel 5 in the IRVO

Ezekiel 5 in the IRVP

Ezekiel 5 in the IRVT

Ezekiel 5 in the IRVT2

Ezekiel 5 in the IRVU

Ezekiel 5 in the ISVN

Ezekiel 5 in the JSNT

Ezekiel 5 in the KAPI

Ezekiel 5 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 5 in the KBV

Ezekiel 5 in the KJV

Ezekiel 5 in the KNFD

Ezekiel 5 in the LBA

Ezekiel 5 in the LBLA

Ezekiel 5 in the LNT

Ezekiel 5 in the LSV

Ezekiel 5 in the MAAL

Ezekiel 5 in the MBV

Ezekiel 5 in the MBV2

Ezekiel 5 in the MHNT

Ezekiel 5 in the MKNFD

Ezekiel 5 in the MNG

Ezekiel 5 in the MNT

Ezekiel 5 in the MNT2

Ezekiel 5 in the MRS1T

Ezekiel 5 in the NAA

Ezekiel 5 in the NASB

Ezekiel 5 in the NBLA

Ezekiel 5 in the NBS

Ezekiel 5 in the NBVTP

Ezekiel 5 in the NET2

Ezekiel 5 in the NIV11

Ezekiel 5 in the NNT

Ezekiel 5 in the NNT2

Ezekiel 5 in the NNT3

Ezekiel 5 in the PDDPT

Ezekiel 5 in the PFNT

Ezekiel 5 in the RMNT

Ezekiel 5 in the SBIAS

Ezekiel 5 in the SBIBS

Ezekiel 5 in the SBIBS2

Ezekiel 5 in the SBICS

Ezekiel 5 in the SBIDS

Ezekiel 5 in the SBIGS

Ezekiel 5 in the SBIHS

Ezekiel 5 in the SBIIS

Ezekiel 5 in the SBIIS2

Ezekiel 5 in the SBIIS3

Ezekiel 5 in the SBIKS

Ezekiel 5 in the SBIKS2

Ezekiel 5 in the SBIMS

Ezekiel 5 in the SBIOS

Ezekiel 5 in the SBIPS

Ezekiel 5 in the SBISS

Ezekiel 5 in the SBITS

Ezekiel 5 in the SBITS2

Ezekiel 5 in the SBITS3

Ezekiel 5 in the SBITS4

Ezekiel 5 in the SBIUS

Ezekiel 5 in the SBIVS

Ezekiel 5 in the SBT

Ezekiel 5 in the SBT1E

Ezekiel 5 in the SCHL

Ezekiel 5 in the SNT

Ezekiel 5 in the SUSU

Ezekiel 5 in the SUSU2

Ezekiel 5 in the SYNO

Ezekiel 5 in the TBIAOTANT

Ezekiel 5 in the TBT1E

Ezekiel 5 in the TBT1E2

Ezekiel 5 in the TFTIP

Ezekiel 5 in the TFTU

Ezekiel 5 in the TGNTATF3T

Ezekiel 5 in the THAI

Ezekiel 5 in the TNFD

Ezekiel 5 in the TNT

Ezekiel 5 in the TNTIK

Ezekiel 5 in the TNTIL

Ezekiel 5 in the TNTIN

Ezekiel 5 in the TNTIP

Ezekiel 5 in the TNTIZ

Ezekiel 5 in the TOMA

Ezekiel 5 in the TTENT

Ezekiel 5 in the UBG

Ezekiel 5 in the UGV

Ezekiel 5 in the UGV2

Ezekiel 5 in the UGV3

Ezekiel 5 in the VBL

Ezekiel 5 in the VDCC

Ezekiel 5 in the YALU

Ezekiel 5 in the YAPE

Ezekiel 5 in the YBVTP

Ezekiel 5 in the ZBP