Genesis 17 (BOYCB)
1 Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún, OLÚWA farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. 2 Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.” 3 Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé. 4 “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. 5 A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. 6 Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. 7 Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. 8 Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé. Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.” 9 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. 10 Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. 11 Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12 Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13 Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14 Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.” 15 Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara. 16 Èmi yóò bùkún fún un, èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.” 17 Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?” 18 Abrahamu sì wí fún Ọlọ́run pé, “Sá à jẹ́ kí Iṣmaeli kí ó wà láààyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.” 19 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Sara aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isaaki, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 20 Ṣùgbọ́n ní ti Iṣmaeli, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún un nítòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. 21 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.” 22 Nígbà tí ó ti bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 23 Ní ọjọ́ náà gan an ni Abrahamu mú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run. 24 Abrahamu jẹ́ ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà. 25 Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlá. 26 Ní ọjọ́ náà gan an ni a kọ Abrahamu ní ilà pẹ̀lú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 27 Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Abrahamu, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ilà pẹ̀lú rẹ̀.
In Other Versions
Genesis 17 in the ANGEFD
Genesis 17 in the ANTPNG2D
Genesis 17 in the AS21
Genesis 17 in the BAGH
Genesis 17 in the BBPNG
Genesis 17 in the BBT1E
Genesis 17 in the BDS
Genesis 17 in the BEV
Genesis 17 in the BHAD
Genesis 17 in the BIB
Genesis 17 in the BLPT
Genesis 17 in the BNT
Genesis 17 in the BNTABOOT
Genesis 17 in the BNTLV
Genesis 17 in the BOATCB
Genesis 17 in the BOATCB2
Genesis 17 in the BOBCV
Genesis 17 in the BOCNT
Genesis 17 in the BOECS
Genesis 17 in the BOGWICC
Genesis 17 in the BOHCB
Genesis 17 in the BOHCV
Genesis 17 in the BOHLNT
Genesis 17 in the BOHNTLTAL
Genesis 17 in the BOICB
Genesis 17 in the BOILNTAP
Genesis 17 in the BOITCV
Genesis 17 in the BOKCV
Genesis 17 in the BOKCV2
Genesis 17 in the BOKHWOG
Genesis 17 in the BOKSSV
Genesis 17 in the BOLCB
Genesis 17 in the BOLCB2
Genesis 17 in the BOMCV
Genesis 17 in the BONAV
Genesis 17 in the BONCB
Genesis 17 in the BONLT
Genesis 17 in the BONUT2
Genesis 17 in the BOPLNT
Genesis 17 in the BOSCB
Genesis 17 in the BOSNC
Genesis 17 in the BOTLNT
Genesis 17 in the BOVCB
Genesis 17 in the BPBB
Genesis 17 in the BPH
Genesis 17 in the BSB
Genesis 17 in the CCB
Genesis 17 in the CUV
Genesis 17 in the CUVS
Genesis 17 in the DBT
Genesis 17 in the DGDNT
Genesis 17 in the DHNT
Genesis 17 in the DNT
Genesis 17 in the ELBE
Genesis 17 in the EMTV
Genesis 17 in the ESV
Genesis 17 in the FBV
Genesis 17 in the FEB
Genesis 17 in the GGMNT
Genesis 17 in the GNT
Genesis 17 in the HARY
Genesis 17 in the HNT
Genesis 17 in the IRVA
Genesis 17 in the IRVB
Genesis 17 in the IRVG
Genesis 17 in the IRVH
Genesis 17 in the IRVK
Genesis 17 in the IRVM
Genesis 17 in the IRVM2
Genesis 17 in the IRVO
Genesis 17 in the IRVP
Genesis 17 in the IRVT
Genesis 17 in the IRVT2
Genesis 17 in the IRVU
Genesis 17 in the ISVN
Genesis 17 in the JSNT
Genesis 17 in the KAPI
Genesis 17 in the KBT1ETNIK
Genesis 17 in the KBV
Genesis 17 in the KJV
Genesis 17 in the KNFD
Genesis 17 in the LBA
Genesis 17 in the LBLA
Genesis 17 in the LNT
Genesis 17 in the LSV
Genesis 17 in the MAAL
Genesis 17 in the MBV
Genesis 17 in the MBV2
Genesis 17 in the MHNT
Genesis 17 in the MKNFD
Genesis 17 in the MNG
Genesis 17 in the MNT
Genesis 17 in the MNT2
Genesis 17 in the MRS1T
Genesis 17 in the NAA
Genesis 17 in the NASB
Genesis 17 in the NBLA
Genesis 17 in the NBS
Genesis 17 in the NBVTP
Genesis 17 in the NET2
Genesis 17 in the NIV11
Genesis 17 in the NNT
Genesis 17 in the NNT2
Genesis 17 in the NNT3
Genesis 17 in the PDDPT
Genesis 17 in the PFNT
Genesis 17 in the RMNT
Genesis 17 in the SBIAS
Genesis 17 in the SBIBS
Genesis 17 in the SBIBS2
Genesis 17 in the SBICS
Genesis 17 in the SBIDS
Genesis 17 in the SBIGS
Genesis 17 in the SBIHS
Genesis 17 in the SBIIS
Genesis 17 in the SBIIS2
Genesis 17 in the SBIIS3
Genesis 17 in the SBIKS
Genesis 17 in the SBIKS2
Genesis 17 in the SBIMS
Genesis 17 in the SBIOS
Genesis 17 in the SBIPS
Genesis 17 in the SBISS
Genesis 17 in the SBITS
Genesis 17 in the SBITS2
Genesis 17 in the SBITS3
Genesis 17 in the SBITS4
Genesis 17 in the SBIUS
Genesis 17 in the SBIVS
Genesis 17 in the SBT
Genesis 17 in the SBT1E
Genesis 17 in the SCHL
Genesis 17 in the SNT
Genesis 17 in the SUSU
Genesis 17 in the SUSU2
Genesis 17 in the SYNO
Genesis 17 in the TBIAOTANT
Genesis 17 in the TBT1E
Genesis 17 in the TBT1E2
Genesis 17 in the TFTIP
Genesis 17 in the TFTU
Genesis 17 in the TGNTATF3T
Genesis 17 in the THAI
Genesis 17 in the TNFD
Genesis 17 in the TNT
Genesis 17 in the TNTIK
Genesis 17 in the TNTIL
Genesis 17 in the TNTIN
Genesis 17 in the TNTIP
Genesis 17 in the TNTIZ
Genesis 17 in the TOMA
Genesis 17 in the TTENT
Genesis 17 in the UBG
Genesis 17 in the UGV
Genesis 17 in the UGV2
Genesis 17 in the UGV3
Genesis 17 in the VBL
Genesis 17 in the VDCC
Genesis 17 in the YALU
Genesis 17 in the YAPE
Genesis 17 in the YBVTP
Genesis 17 in the ZBP