Genesis 25 (BOYCB)
1 Abrahamu sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. 2 Ó sì bí Simrani, Jokṣani, Medani, Midiani, Iṣbaki, àti Ṣua 3 Jokṣani ni baba Ṣeba àti Dedani, àwọn ìran Dedani ni àwọn ara Asṣuri, Letusi àti Leumiti. 4 Àwọn ọmọ Midiani ni Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura. 5 Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki. 6 Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn. 7 Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175). 8 Abrahamu sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin ín sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀. 9 Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti, 10 inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí. 11 Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọ́run sì bùkún fún Isaaki ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòsí kànga Lahai-Roi ní ìgbà náà. 12 Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un. 13 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí: Nebaioti àkọ́bí,Kedari, Adbeeli, Mibsamu, 14 Miṣima, Duma, Massa, 15 Hadadi, Tema, Jeturi,Nafiṣi, àti Kedema. 16 Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn. 17 Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. 18 Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo. 19 Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki. 20 Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó. 21 Isaaki sì gbàdúrà sì OLÚWA, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLÚWA sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rebeka sì lóyún. 22 Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA. 23 OLÚWA sì wí fún un pé,“Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ,irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ;àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ,ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” 24 Nígbà tí ó tó àkókò fún un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n. 25 Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau. 26 Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn. 27 Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú. 28 Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu. 29 Ní ọjọ́ kan, Jakọbu sì pa ìpẹ̀tẹ̀, Esau sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́. 30 Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.) 31 Jakọbu dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.” 32 Esau sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?” 33 Ṣùgbọ́n, Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Esau búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jakọbu. 34 Nígbà náà ni Jakọbu fi àkàrà àti ìpẹ̀tẹ̀ lẹntili fún Esau. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì bá tirẹ̀ lọ.Báyìí ni Esau gan ogún ìbí rẹ̀.
In Other Versions
Genesis 25 in the ANGEFD
Genesis 25 in the ANTPNG2D
Genesis 25 in the AS21
Genesis 25 in the BAGH
Genesis 25 in the BBPNG
Genesis 25 in the BBT1E
Genesis 25 in the BDS
Genesis 25 in the BEV
Genesis 25 in the BHAD
Genesis 25 in the BIB
Genesis 25 in the BLPT
Genesis 25 in the BNT
Genesis 25 in the BNTABOOT
Genesis 25 in the BNTLV
Genesis 25 in the BOATCB
Genesis 25 in the BOATCB2
Genesis 25 in the BOBCV
Genesis 25 in the BOCNT
Genesis 25 in the BOECS
Genesis 25 in the BOGWICC
Genesis 25 in the BOHCB
Genesis 25 in the BOHCV
Genesis 25 in the BOHLNT
Genesis 25 in the BOHNTLTAL
Genesis 25 in the BOICB
Genesis 25 in the BOILNTAP
Genesis 25 in the BOITCV
Genesis 25 in the BOKCV
Genesis 25 in the BOKCV2
Genesis 25 in the BOKHWOG
Genesis 25 in the BOKSSV
Genesis 25 in the BOLCB
Genesis 25 in the BOLCB2
Genesis 25 in the BOMCV
Genesis 25 in the BONAV
Genesis 25 in the BONCB
Genesis 25 in the BONLT
Genesis 25 in the BONUT2
Genesis 25 in the BOPLNT
Genesis 25 in the BOSCB
Genesis 25 in the BOSNC
Genesis 25 in the BOTLNT
Genesis 25 in the BOVCB
Genesis 25 in the BPBB
Genesis 25 in the BPH
Genesis 25 in the BSB
Genesis 25 in the CCB
Genesis 25 in the CUV
Genesis 25 in the CUVS
Genesis 25 in the DBT
Genesis 25 in the DGDNT
Genesis 25 in the DHNT
Genesis 25 in the DNT
Genesis 25 in the ELBE
Genesis 25 in the EMTV
Genesis 25 in the ESV
Genesis 25 in the FBV
Genesis 25 in the FEB
Genesis 25 in the GGMNT
Genesis 25 in the GNT
Genesis 25 in the HARY
Genesis 25 in the HNT
Genesis 25 in the IRVA
Genesis 25 in the IRVB
Genesis 25 in the IRVG
Genesis 25 in the IRVH
Genesis 25 in the IRVK
Genesis 25 in the IRVM
Genesis 25 in the IRVM2
Genesis 25 in the IRVO
Genesis 25 in the IRVP
Genesis 25 in the IRVT
Genesis 25 in the IRVT2
Genesis 25 in the IRVU
Genesis 25 in the ISVN
Genesis 25 in the JSNT
Genesis 25 in the KAPI
Genesis 25 in the KBT1ETNIK
Genesis 25 in the KBV
Genesis 25 in the KJV
Genesis 25 in the KNFD
Genesis 25 in the LBA
Genesis 25 in the LBLA
Genesis 25 in the LNT
Genesis 25 in the LSV
Genesis 25 in the MAAL
Genesis 25 in the MBV
Genesis 25 in the MBV2
Genesis 25 in the MHNT
Genesis 25 in the MKNFD
Genesis 25 in the MNG
Genesis 25 in the MNT
Genesis 25 in the MNT2
Genesis 25 in the MRS1T
Genesis 25 in the NAA
Genesis 25 in the NASB
Genesis 25 in the NBLA
Genesis 25 in the NBS
Genesis 25 in the NBVTP
Genesis 25 in the NET2
Genesis 25 in the NIV11
Genesis 25 in the NNT
Genesis 25 in the NNT2
Genesis 25 in the NNT3
Genesis 25 in the PDDPT
Genesis 25 in the PFNT
Genesis 25 in the RMNT
Genesis 25 in the SBIAS
Genesis 25 in the SBIBS
Genesis 25 in the SBIBS2
Genesis 25 in the SBICS
Genesis 25 in the SBIDS
Genesis 25 in the SBIGS
Genesis 25 in the SBIHS
Genesis 25 in the SBIIS
Genesis 25 in the SBIIS2
Genesis 25 in the SBIIS3
Genesis 25 in the SBIKS
Genesis 25 in the SBIKS2
Genesis 25 in the SBIMS
Genesis 25 in the SBIOS
Genesis 25 in the SBIPS
Genesis 25 in the SBISS
Genesis 25 in the SBITS
Genesis 25 in the SBITS2
Genesis 25 in the SBITS3
Genesis 25 in the SBITS4
Genesis 25 in the SBIUS
Genesis 25 in the SBIVS
Genesis 25 in the SBT
Genesis 25 in the SBT1E
Genesis 25 in the SCHL
Genesis 25 in the SNT
Genesis 25 in the SUSU
Genesis 25 in the SUSU2
Genesis 25 in the SYNO
Genesis 25 in the TBIAOTANT
Genesis 25 in the TBT1E
Genesis 25 in the TBT1E2
Genesis 25 in the TFTIP
Genesis 25 in the TFTU
Genesis 25 in the TGNTATF3T
Genesis 25 in the THAI
Genesis 25 in the TNFD
Genesis 25 in the TNT
Genesis 25 in the TNTIK
Genesis 25 in the TNTIL
Genesis 25 in the TNTIN
Genesis 25 in the TNTIP
Genesis 25 in the TNTIZ
Genesis 25 in the TOMA
Genesis 25 in the TTENT
Genesis 25 in the UBG
Genesis 25 in the UGV
Genesis 25 in the UGV2
Genesis 25 in the UGV3
Genesis 25 in the VBL
Genesis 25 in the VDCC
Genesis 25 in the YALU
Genesis 25 in the YAPE
Genesis 25 in the YBVTP
Genesis 25 in the ZBP