Genesis 4 (BOYCB)
1 Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ OLÚWA ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” 2 Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli.Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. 3 Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún OLÚWA nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. 4 Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún OLÚWA nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. OLÚWA sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, 5 ṣùgbọ́n OLÚWA kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro. 6 Nígbà náà ni OLÚWA bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? 7 Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” 8 Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. 9 Nígbà náà ni OLÚWA béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?”Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” 10 OLÚWA wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. 11 Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. 12 Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.” 13 Kaini wí fún OLÚWA pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. 14 Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.” 15 Ṣùgbọ́n, OLÚWA wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. 16 Kaini sì kúrò níwájú OLÚWA, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni. 17 Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà. 18 Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki. 19 Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla. 20 Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. 21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. 22 Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. 23 Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀,“Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi;ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí,ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. 24 Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje,ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).” 25 Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.” 26 Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi.Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ OLÚWA.
In Other Versions
Genesis 4 in the ANGEFD
Genesis 4 in the ANTPNG2D
Genesis 4 in the AS21
Genesis 4 in the BAGH
Genesis 4 in the BBPNG
Genesis 4 in the BBT1E
Genesis 4 in the BDS
Genesis 4 in the BEV
Genesis 4 in the BHAD
Genesis 4 in the BIB
Genesis 4 in the BLPT
Genesis 4 in the BNT
Genesis 4 in the BNTABOOT
Genesis 4 in the BNTLV
Genesis 4 in the BOATCB
Genesis 4 in the BOATCB2
Genesis 4 in the BOBCV
Genesis 4 in the BOCNT
Genesis 4 in the BOECS
Genesis 4 in the BOGWICC
Genesis 4 in the BOHCB
Genesis 4 in the BOHCV
Genesis 4 in the BOHLNT
Genesis 4 in the BOHNTLTAL
Genesis 4 in the BOICB
Genesis 4 in the BOILNTAP
Genesis 4 in the BOITCV
Genesis 4 in the BOKCV
Genesis 4 in the BOKCV2
Genesis 4 in the BOKHWOG
Genesis 4 in the BOKSSV
Genesis 4 in the BOLCB
Genesis 4 in the BOLCB2
Genesis 4 in the BOMCV
Genesis 4 in the BONAV
Genesis 4 in the BONCB
Genesis 4 in the BONLT
Genesis 4 in the BONUT2
Genesis 4 in the BOPLNT
Genesis 4 in the BOSCB
Genesis 4 in the BOSNC
Genesis 4 in the BOTLNT
Genesis 4 in the BOVCB
Genesis 4 in the BPBB
Genesis 4 in the BPH
Genesis 4 in the BSB
Genesis 4 in the CCB
Genesis 4 in the CUV
Genesis 4 in the CUVS
Genesis 4 in the DBT
Genesis 4 in the DGDNT
Genesis 4 in the DHNT
Genesis 4 in the DNT
Genesis 4 in the ELBE
Genesis 4 in the EMTV
Genesis 4 in the ESV
Genesis 4 in the FBV
Genesis 4 in the FEB
Genesis 4 in the GGMNT
Genesis 4 in the GNT
Genesis 4 in the HARY
Genesis 4 in the HNT
Genesis 4 in the IRVA
Genesis 4 in the IRVB
Genesis 4 in the IRVG
Genesis 4 in the IRVH
Genesis 4 in the IRVK
Genesis 4 in the IRVM
Genesis 4 in the IRVM2
Genesis 4 in the IRVO
Genesis 4 in the IRVP
Genesis 4 in the IRVT
Genesis 4 in the IRVT2
Genesis 4 in the IRVU
Genesis 4 in the ISVN
Genesis 4 in the JSNT
Genesis 4 in the KAPI
Genesis 4 in the KBT1ETNIK
Genesis 4 in the KBV
Genesis 4 in the KJV
Genesis 4 in the KNFD
Genesis 4 in the LBA
Genesis 4 in the LBLA
Genesis 4 in the LNT
Genesis 4 in the LSV
Genesis 4 in the MAAL
Genesis 4 in the MBV
Genesis 4 in the MBV2
Genesis 4 in the MHNT
Genesis 4 in the MKNFD
Genesis 4 in the MNG
Genesis 4 in the MNT
Genesis 4 in the MNT2
Genesis 4 in the MRS1T
Genesis 4 in the NAA
Genesis 4 in the NASB
Genesis 4 in the NBLA
Genesis 4 in the NBS
Genesis 4 in the NBVTP
Genesis 4 in the NET2
Genesis 4 in the NIV11
Genesis 4 in the NNT
Genesis 4 in the NNT2
Genesis 4 in the NNT3
Genesis 4 in the PDDPT
Genesis 4 in the PFNT
Genesis 4 in the RMNT
Genesis 4 in the SBIAS
Genesis 4 in the SBIBS
Genesis 4 in the SBIBS2
Genesis 4 in the SBICS
Genesis 4 in the SBIDS
Genesis 4 in the SBIGS
Genesis 4 in the SBIHS
Genesis 4 in the SBIIS
Genesis 4 in the SBIIS2
Genesis 4 in the SBIIS3
Genesis 4 in the SBIKS
Genesis 4 in the SBIKS2
Genesis 4 in the SBIMS
Genesis 4 in the SBIOS
Genesis 4 in the SBIPS
Genesis 4 in the SBISS
Genesis 4 in the SBITS
Genesis 4 in the SBITS2
Genesis 4 in the SBITS3
Genesis 4 in the SBITS4
Genesis 4 in the SBIUS
Genesis 4 in the SBIVS
Genesis 4 in the SBT
Genesis 4 in the SBT1E
Genesis 4 in the SCHL
Genesis 4 in the SNT
Genesis 4 in the SUSU
Genesis 4 in the SUSU2
Genesis 4 in the SYNO
Genesis 4 in the TBIAOTANT
Genesis 4 in the TBT1E
Genesis 4 in the TBT1E2
Genesis 4 in the TFTIP
Genesis 4 in the TFTU
Genesis 4 in the TGNTATF3T
Genesis 4 in the THAI
Genesis 4 in the TNFD
Genesis 4 in the TNT
Genesis 4 in the TNTIK
Genesis 4 in the TNTIL
Genesis 4 in the TNTIN
Genesis 4 in the TNTIP
Genesis 4 in the TNTIZ
Genesis 4 in the TOMA
Genesis 4 in the TTENT
Genesis 4 in the UBG
Genesis 4 in the UGV
Genesis 4 in the UGV2
Genesis 4 in the UGV3
Genesis 4 in the VBL
Genesis 4 in the VDCC
Genesis 4 in the YALU
Genesis 4 in the YAPE
Genesis 4 in the YBVTP
Genesis 4 in the ZBP