Haggai 1 (BOYCB)
1 Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ OLÚWA wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 2 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé OLÚWA.’ ” 3 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé, 4 “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?” 5 Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 6 Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.” 7 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 8 Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni OLÚWA wí. 9 “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀. 10 Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde. 11 Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.” 12 Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn OLÚWA Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí OLÚWA Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù OLÚWA. 13 Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ OLÚWA ń jíṣẹ́ OLÚWA fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni OLÚWA wí. 14 Nítorí náà, OLÚWA ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, 15 ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.
In Other Versions
Haggai 1 in the ANGEFD
Haggai 1 in the ANTPNG2D
Haggai 1 in the AS21
Haggai 1 in the BAGH
Haggai 1 in the BBPNG
Haggai 1 in the BBT1E
Haggai 1 in the BDS
Haggai 1 in the BEV
Haggai 1 in the BHAD
Haggai 1 in the BIB
Haggai 1 in the BLPT
Haggai 1 in the BNT
Haggai 1 in the BNTABOOT
Haggai 1 in the BNTLV
Haggai 1 in the BOATCB
Haggai 1 in the BOATCB2
Haggai 1 in the BOBCV
Haggai 1 in the BOCNT
Haggai 1 in the BOECS
Haggai 1 in the BOGWICC
Haggai 1 in the BOHCB
Haggai 1 in the BOHCV
Haggai 1 in the BOHLNT
Haggai 1 in the BOHNTLTAL
Haggai 1 in the BOICB
Haggai 1 in the BOILNTAP
Haggai 1 in the BOITCV
Haggai 1 in the BOKCV
Haggai 1 in the BOKCV2
Haggai 1 in the BOKHWOG
Haggai 1 in the BOKSSV
Haggai 1 in the BOLCB
Haggai 1 in the BOLCB2
Haggai 1 in the BOMCV
Haggai 1 in the BONAV
Haggai 1 in the BONCB
Haggai 1 in the BONLT
Haggai 1 in the BONUT2
Haggai 1 in the BOPLNT
Haggai 1 in the BOSCB
Haggai 1 in the BOSNC
Haggai 1 in the BOTLNT
Haggai 1 in the BOVCB
Haggai 1 in the BPBB
Haggai 1 in the BPH
Haggai 1 in the BSB
Haggai 1 in the CCB
Haggai 1 in the CUV
Haggai 1 in the CUVS
Haggai 1 in the DBT
Haggai 1 in the DGDNT
Haggai 1 in the DHNT
Haggai 1 in the DNT
Haggai 1 in the ELBE
Haggai 1 in the EMTV
Haggai 1 in the ESV
Haggai 1 in the FBV
Haggai 1 in the FEB
Haggai 1 in the GGMNT
Haggai 1 in the GNT
Haggai 1 in the HARY
Haggai 1 in the HNT
Haggai 1 in the IRVA
Haggai 1 in the IRVB
Haggai 1 in the IRVG
Haggai 1 in the IRVH
Haggai 1 in the IRVK
Haggai 1 in the IRVM
Haggai 1 in the IRVM2
Haggai 1 in the IRVO
Haggai 1 in the IRVP
Haggai 1 in the IRVT
Haggai 1 in the IRVT2
Haggai 1 in the IRVU
Haggai 1 in the ISVN
Haggai 1 in the JSNT
Haggai 1 in the KAPI
Haggai 1 in the KBT1ETNIK
Haggai 1 in the KBV
Haggai 1 in the KJV
Haggai 1 in the KNFD
Haggai 1 in the LBA
Haggai 1 in the LBLA
Haggai 1 in the LNT
Haggai 1 in the LSV
Haggai 1 in the MAAL
Haggai 1 in the MBV
Haggai 1 in the MBV2
Haggai 1 in the MHNT
Haggai 1 in the MKNFD
Haggai 1 in the MNG
Haggai 1 in the MNT
Haggai 1 in the MNT2
Haggai 1 in the MRS1T
Haggai 1 in the NAA
Haggai 1 in the NASB
Haggai 1 in the NBLA
Haggai 1 in the NBS
Haggai 1 in the NBVTP
Haggai 1 in the NET2
Haggai 1 in the NIV11
Haggai 1 in the NNT
Haggai 1 in the NNT2
Haggai 1 in the NNT3
Haggai 1 in the PDDPT
Haggai 1 in the PFNT
Haggai 1 in the RMNT
Haggai 1 in the SBIAS
Haggai 1 in the SBIBS
Haggai 1 in the SBIBS2
Haggai 1 in the SBICS
Haggai 1 in the SBIDS
Haggai 1 in the SBIGS
Haggai 1 in the SBIHS
Haggai 1 in the SBIIS
Haggai 1 in the SBIIS2
Haggai 1 in the SBIIS3
Haggai 1 in the SBIKS
Haggai 1 in the SBIKS2
Haggai 1 in the SBIMS
Haggai 1 in the SBIOS
Haggai 1 in the SBIPS
Haggai 1 in the SBISS
Haggai 1 in the SBITS
Haggai 1 in the SBITS2
Haggai 1 in the SBITS3
Haggai 1 in the SBITS4
Haggai 1 in the SBIUS
Haggai 1 in the SBIVS
Haggai 1 in the SBT
Haggai 1 in the SBT1E
Haggai 1 in the SCHL
Haggai 1 in the SNT
Haggai 1 in the SUSU
Haggai 1 in the SUSU2
Haggai 1 in the SYNO
Haggai 1 in the TBIAOTANT
Haggai 1 in the TBT1E
Haggai 1 in the TBT1E2
Haggai 1 in the TFTIP
Haggai 1 in the TFTU
Haggai 1 in the TGNTATF3T
Haggai 1 in the THAI
Haggai 1 in the TNFD
Haggai 1 in the TNT
Haggai 1 in the TNTIK
Haggai 1 in the TNTIL
Haggai 1 in the TNTIN
Haggai 1 in the TNTIP
Haggai 1 in the TNTIZ
Haggai 1 in the TOMA
Haggai 1 in the TTENT
Haggai 1 in the UBG
Haggai 1 in the UGV
Haggai 1 in the UGV2
Haggai 1 in the UGV3
Haggai 1 in the VBL
Haggai 1 in the VDCC
Haggai 1 in the YALU
Haggai 1 in the YAPE
Haggai 1 in the YBVTP
Haggai 1 in the ZBP