Isaiah 37 (BOYCB)

1 Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili OLÚWA lọ. 2 Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí, ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn. 4 Ó lè jẹ́ pé OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.” 5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah, 6 Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí OLÚWA sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi. 7 Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ” 8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà. 9 Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, 10 “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’ 11 Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí? 12 Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13 Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?” 14 Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili OLÚWA ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLÚWA. 15 Hesekiah sì gbàdúrà sí OLÚWA: 16 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 17 Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ OLÚWA, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ OLÚWA, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè. 18 “Òtítọ́ ni OLÚWA pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán. 19 Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe. 20 Nísinsin yìí, ìwọ OLÚWA, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, OLÚWA ni Ọlọ́run.” 21 Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria, 22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA ti sọ nípa rẹ̀:“Wúńdíá ọmọbìnrin Sioniti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.Ọmọbìnrin Jerusalẹmuti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ. 23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókètí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli! 24 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ,ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí OLÚWA.Tì wọ sì wí pé,‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mini èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,àti ààyò igi firi rẹ̀.Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ. 25 Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjìmo sì mu omi ní ibẹ̀,pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ miÈmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’ 26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́?Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,pé o ti sọ àwọn ìlú olódi diàkójọpọ̀ àwọn òkúta. 27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè. 28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wààti ìgbà tí o wá tí o sì lọàti bí inú rẹ ṣe ru sí mi. 29 Nítorí pé inú rẹ ru sí miàti nítorí pé orí kunkun rẹ tidé etí ìgbọ́ mi,Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,èmi yóò sì jẹ́ kí o padàláti ọ̀nà tí o gbà wá. 30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn. 31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Judayóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè. 32 Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.Ìtara OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ. 33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA wí nípa ọba Asiria,“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wátàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ínÒun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asàtàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un. 34 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ;òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”ni OLÚWA wí. 35 “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là,nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!” 36 Lẹ́yìn náà ni angẹli OLÚWA jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú! 37 Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀. 38 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

In Other Versions

Isaiah 37 in the ANGEFD

Isaiah 37 in the ANTPNG2D

Isaiah 37 in the AS21

Isaiah 37 in the BAGH

Isaiah 37 in the BBPNG

Isaiah 37 in the BBT1E

Isaiah 37 in the BDS

Isaiah 37 in the BEV

Isaiah 37 in the BHAD

Isaiah 37 in the BIB

Isaiah 37 in the BLPT

Isaiah 37 in the BNT

Isaiah 37 in the BNTABOOT

Isaiah 37 in the BNTLV

Isaiah 37 in the BOATCB

Isaiah 37 in the BOATCB2

Isaiah 37 in the BOBCV

Isaiah 37 in the BOCNT

Isaiah 37 in the BOECS

Isaiah 37 in the BOGWICC

Isaiah 37 in the BOHCB

Isaiah 37 in the BOHCV

Isaiah 37 in the BOHLNT

Isaiah 37 in the BOHNTLTAL

Isaiah 37 in the BOICB

Isaiah 37 in the BOILNTAP

Isaiah 37 in the BOITCV

Isaiah 37 in the BOKCV

Isaiah 37 in the BOKCV2

Isaiah 37 in the BOKHWOG

Isaiah 37 in the BOKSSV

Isaiah 37 in the BOLCB

Isaiah 37 in the BOLCB2

Isaiah 37 in the BOMCV

Isaiah 37 in the BONAV

Isaiah 37 in the BONCB

Isaiah 37 in the BONLT

Isaiah 37 in the BONUT2

Isaiah 37 in the BOPLNT

Isaiah 37 in the BOSCB

Isaiah 37 in the BOSNC

Isaiah 37 in the BOTLNT

Isaiah 37 in the BOVCB

Isaiah 37 in the BPBB

Isaiah 37 in the BPH

Isaiah 37 in the BSB

Isaiah 37 in the CCB

Isaiah 37 in the CUV

Isaiah 37 in the CUVS

Isaiah 37 in the DBT

Isaiah 37 in the DGDNT

Isaiah 37 in the DHNT

Isaiah 37 in the DNT

Isaiah 37 in the ELBE

Isaiah 37 in the EMTV

Isaiah 37 in the ESV

Isaiah 37 in the FBV

Isaiah 37 in the FEB

Isaiah 37 in the GGMNT

Isaiah 37 in the GNT

Isaiah 37 in the HARY

Isaiah 37 in the HNT

Isaiah 37 in the IRVA

Isaiah 37 in the IRVB

Isaiah 37 in the IRVG

Isaiah 37 in the IRVH

Isaiah 37 in the IRVK

Isaiah 37 in the IRVM

Isaiah 37 in the IRVM2

Isaiah 37 in the IRVO

Isaiah 37 in the IRVP

Isaiah 37 in the IRVT

Isaiah 37 in the IRVT2

Isaiah 37 in the IRVU

Isaiah 37 in the ISVN

Isaiah 37 in the JSNT

Isaiah 37 in the KAPI

Isaiah 37 in the KBT1ETNIK

Isaiah 37 in the KBV

Isaiah 37 in the KJV

Isaiah 37 in the KNFD

Isaiah 37 in the LBA

Isaiah 37 in the LBLA

Isaiah 37 in the LNT

Isaiah 37 in the LSV

Isaiah 37 in the MAAL

Isaiah 37 in the MBV

Isaiah 37 in the MBV2

Isaiah 37 in the MHNT

Isaiah 37 in the MKNFD

Isaiah 37 in the MNG

Isaiah 37 in the MNT

Isaiah 37 in the MNT2

Isaiah 37 in the MRS1T

Isaiah 37 in the NAA

Isaiah 37 in the NASB

Isaiah 37 in the NBLA

Isaiah 37 in the NBS

Isaiah 37 in the NBVTP

Isaiah 37 in the NET2

Isaiah 37 in the NIV11

Isaiah 37 in the NNT

Isaiah 37 in the NNT2

Isaiah 37 in the NNT3

Isaiah 37 in the PDDPT

Isaiah 37 in the PFNT

Isaiah 37 in the RMNT

Isaiah 37 in the SBIAS

Isaiah 37 in the SBIBS

Isaiah 37 in the SBIBS2

Isaiah 37 in the SBICS

Isaiah 37 in the SBIDS

Isaiah 37 in the SBIGS

Isaiah 37 in the SBIHS

Isaiah 37 in the SBIIS

Isaiah 37 in the SBIIS2

Isaiah 37 in the SBIIS3

Isaiah 37 in the SBIKS

Isaiah 37 in the SBIKS2

Isaiah 37 in the SBIMS

Isaiah 37 in the SBIOS

Isaiah 37 in the SBIPS

Isaiah 37 in the SBISS

Isaiah 37 in the SBITS

Isaiah 37 in the SBITS2

Isaiah 37 in the SBITS3

Isaiah 37 in the SBITS4

Isaiah 37 in the SBIUS

Isaiah 37 in the SBIVS

Isaiah 37 in the SBT

Isaiah 37 in the SBT1E

Isaiah 37 in the SCHL

Isaiah 37 in the SNT

Isaiah 37 in the SUSU

Isaiah 37 in the SUSU2

Isaiah 37 in the SYNO

Isaiah 37 in the TBIAOTANT

Isaiah 37 in the TBT1E

Isaiah 37 in the TBT1E2

Isaiah 37 in the TFTIP

Isaiah 37 in the TFTU

Isaiah 37 in the TGNTATF3T

Isaiah 37 in the THAI

Isaiah 37 in the TNFD

Isaiah 37 in the TNT

Isaiah 37 in the TNTIK

Isaiah 37 in the TNTIL

Isaiah 37 in the TNTIN

Isaiah 37 in the TNTIP

Isaiah 37 in the TNTIZ

Isaiah 37 in the TOMA

Isaiah 37 in the TTENT

Isaiah 37 in the UBG

Isaiah 37 in the UGV

Isaiah 37 in the UGV2

Isaiah 37 in the UGV3

Isaiah 37 in the VBL

Isaiah 37 in the VDCC

Isaiah 37 in the YALU

Isaiah 37 in the YAPE

Isaiah 37 in the YBVTP

Isaiah 37 in the ZBP