Jeremiah 14 (BOYCB)
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn: 2 “Juda káàánú,àwọn ìlú rẹ̀ kérorawọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu. 3 Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,wọ́n lọ sí ìdí àmùṣùgbọ́n wọn kò rí omi.Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,wọ́n sì bo orí wọn. 4 Ilẹ̀ náà sánnítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,wọ́n sì bo orí wọn. 5 Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápáfi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,torí pé kò sí koríko. 6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfowọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookòojú wọn kò rírannítorí pé kò sí koríko jíjẹ.” 7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,wá nǹkan kan ṣe sí i OLÚWA, nítorí orúkọ rẹ.Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,a ti ṣẹ̀ sí ọ. 8 Ìrètí Israẹli;ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náàbí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré? 9 Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?Ìwọ wà láàrín wa, OLÚWA,orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;má ṣe fi wá sílẹ̀. 10 Báyìí ni OLÚWA sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.Nítorí náà OLÚWA kò gbà wọ́n;yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” 11 Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.” 13 Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! OLÚWA Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ” 14 Nígbà náà OLÚWA sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni OLÚWA sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijéní ọ̀sán àti ní òru láìdá;nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlápẹ̀lú lílù bolẹ̀. 18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.Wòlíì àti Àlùfáàti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ” 19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?Ṣé o ti ṣá Sioni tì?Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójútí a kò fi le wò wá sàn?A ń retí àlàáfíàṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,ní àsìkò ìwòsànìpayà là ń rí. 20 OLÚWA, a jẹ́wọ́ ìwà ibi waàti àìṣedéédéé àwọn baba wa;lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ. 21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dákí o má ṣe dà á. 22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí?Rárá, ìwọ ni, OLÚWA Ọlọ́run wa.Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
In Other Versions
Jeremiah 14 in the ANGEFD
Jeremiah 14 in the ANTPNG2D
Jeremiah 14 in the AS21
Jeremiah 14 in the BAGH
Jeremiah 14 in the BBPNG
Jeremiah 14 in the BBT1E
Jeremiah 14 in the BDS
Jeremiah 14 in the BEV
Jeremiah 14 in the BHAD
Jeremiah 14 in the BIB
Jeremiah 14 in the BLPT
Jeremiah 14 in the BNT
Jeremiah 14 in the BNTABOOT
Jeremiah 14 in the BNTLV
Jeremiah 14 in the BOATCB
Jeremiah 14 in the BOATCB2
Jeremiah 14 in the BOBCV
Jeremiah 14 in the BOCNT
Jeremiah 14 in the BOECS
Jeremiah 14 in the BOGWICC
Jeremiah 14 in the BOHCB
Jeremiah 14 in the BOHCV
Jeremiah 14 in the BOHLNT
Jeremiah 14 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 14 in the BOICB
Jeremiah 14 in the BOILNTAP
Jeremiah 14 in the BOITCV
Jeremiah 14 in the BOKCV
Jeremiah 14 in the BOKCV2
Jeremiah 14 in the BOKHWOG
Jeremiah 14 in the BOKSSV
Jeremiah 14 in the BOLCB
Jeremiah 14 in the BOLCB2
Jeremiah 14 in the BOMCV
Jeremiah 14 in the BONAV
Jeremiah 14 in the BONCB
Jeremiah 14 in the BONLT
Jeremiah 14 in the BONUT2
Jeremiah 14 in the BOPLNT
Jeremiah 14 in the BOSCB
Jeremiah 14 in the BOSNC
Jeremiah 14 in the BOTLNT
Jeremiah 14 in the BOVCB
Jeremiah 14 in the BPBB
Jeremiah 14 in the BPH
Jeremiah 14 in the BSB
Jeremiah 14 in the CCB
Jeremiah 14 in the CUV
Jeremiah 14 in the CUVS
Jeremiah 14 in the DBT
Jeremiah 14 in the DGDNT
Jeremiah 14 in the DHNT
Jeremiah 14 in the DNT
Jeremiah 14 in the ELBE
Jeremiah 14 in the EMTV
Jeremiah 14 in the ESV
Jeremiah 14 in the FBV
Jeremiah 14 in the FEB
Jeremiah 14 in the GGMNT
Jeremiah 14 in the GNT
Jeremiah 14 in the HARY
Jeremiah 14 in the HNT
Jeremiah 14 in the IRVA
Jeremiah 14 in the IRVB
Jeremiah 14 in the IRVG
Jeremiah 14 in the IRVH
Jeremiah 14 in the IRVK
Jeremiah 14 in the IRVM
Jeremiah 14 in the IRVM2
Jeremiah 14 in the IRVO
Jeremiah 14 in the IRVP
Jeremiah 14 in the IRVT
Jeremiah 14 in the IRVT2
Jeremiah 14 in the IRVU
Jeremiah 14 in the ISVN
Jeremiah 14 in the JSNT
Jeremiah 14 in the KAPI
Jeremiah 14 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 14 in the KBV
Jeremiah 14 in the KJV
Jeremiah 14 in the KNFD
Jeremiah 14 in the LBA
Jeremiah 14 in the LBLA
Jeremiah 14 in the LNT
Jeremiah 14 in the LSV
Jeremiah 14 in the MAAL
Jeremiah 14 in the MBV
Jeremiah 14 in the MBV2
Jeremiah 14 in the MHNT
Jeremiah 14 in the MKNFD
Jeremiah 14 in the MNG
Jeremiah 14 in the MNT
Jeremiah 14 in the MNT2
Jeremiah 14 in the MRS1T
Jeremiah 14 in the NAA
Jeremiah 14 in the NASB
Jeremiah 14 in the NBLA
Jeremiah 14 in the NBS
Jeremiah 14 in the NBVTP
Jeremiah 14 in the NET2
Jeremiah 14 in the NIV11
Jeremiah 14 in the NNT
Jeremiah 14 in the NNT2
Jeremiah 14 in the NNT3
Jeremiah 14 in the PDDPT
Jeremiah 14 in the PFNT
Jeremiah 14 in the RMNT
Jeremiah 14 in the SBIAS
Jeremiah 14 in the SBIBS
Jeremiah 14 in the SBIBS2
Jeremiah 14 in the SBICS
Jeremiah 14 in the SBIDS
Jeremiah 14 in the SBIGS
Jeremiah 14 in the SBIHS
Jeremiah 14 in the SBIIS
Jeremiah 14 in the SBIIS2
Jeremiah 14 in the SBIIS3
Jeremiah 14 in the SBIKS
Jeremiah 14 in the SBIKS2
Jeremiah 14 in the SBIMS
Jeremiah 14 in the SBIOS
Jeremiah 14 in the SBIPS
Jeremiah 14 in the SBISS
Jeremiah 14 in the SBITS
Jeremiah 14 in the SBITS2
Jeremiah 14 in the SBITS3
Jeremiah 14 in the SBITS4
Jeremiah 14 in the SBIUS
Jeremiah 14 in the SBIVS
Jeremiah 14 in the SBT
Jeremiah 14 in the SBT1E
Jeremiah 14 in the SCHL
Jeremiah 14 in the SNT
Jeremiah 14 in the SUSU
Jeremiah 14 in the SUSU2
Jeremiah 14 in the SYNO
Jeremiah 14 in the TBIAOTANT
Jeremiah 14 in the TBT1E
Jeremiah 14 in the TBT1E2
Jeremiah 14 in the TFTIP
Jeremiah 14 in the TFTU
Jeremiah 14 in the TGNTATF3T
Jeremiah 14 in the THAI
Jeremiah 14 in the TNFD
Jeremiah 14 in the TNT
Jeremiah 14 in the TNTIK
Jeremiah 14 in the TNTIL
Jeremiah 14 in the TNTIN
Jeremiah 14 in the TNTIP
Jeremiah 14 in the TNTIZ
Jeremiah 14 in the TOMA
Jeremiah 14 in the TTENT
Jeremiah 14 in the UBG
Jeremiah 14 in the UGV
Jeremiah 14 in the UGV2
Jeremiah 14 in the UGV3
Jeremiah 14 in the VBL
Jeremiah 14 in the VDCC
Jeremiah 14 in the YALU
Jeremiah 14 in the YAPE
Jeremiah 14 in the YBVTP
Jeremiah 14 in the ZBP