Jeremiah 33 (BOYCB)
1 Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì: 2 “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ, ẹni tí ó dá ayé, OLÚWA tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, OLÚWA ni orúkọ rẹ̀: 3 ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’ 4 Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà 5 nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn. 6 “ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. 7 Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. 8 Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. 9 Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’ 10 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí. 11 Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé OLÚWA wí pé:“ ‘ “Yin OLÚWA àwọn ọmọ-ogun,nítorí OLÚWA dára,ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.”Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni OLÚWA wí. 12 “Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. 13 Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni OLÚWA wí. 14 “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni OLÚWA wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. 15 “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. 16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu.Orúkọ yìí ni a ó máa pè é OLÚWA wa olódodo.’ 17 Nítorí báyìí ni OLÚWA wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli. 18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ” 19 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Jeremiah wá wí pé: 20 “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́. 21 Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ” 23 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremiah wá wí pé: 24 “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsi pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘OLÚWA ti kọ àwọn ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. 25 Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀. 26 Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọ lẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”
In Other Versions
Jeremiah 33 in the ANGEFD
Jeremiah 33 in the ANTPNG2D
Jeremiah 33 in the AS21
Jeremiah 33 in the BAGH
Jeremiah 33 in the BBPNG
Jeremiah 33 in the BBT1E
Jeremiah 33 in the BDS
Jeremiah 33 in the BEV
Jeremiah 33 in the BHAD
Jeremiah 33 in the BIB
Jeremiah 33 in the BLPT
Jeremiah 33 in the BNT
Jeremiah 33 in the BNTABOOT
Jeremiah 33 in the BNTLV
Jeremiah 33 in the BOATCB
Jeremiah 33 in the BOATCB2
Jeremiah 33 in the BOBCV
Jeremiah 33 in the BOCNT
Jeremiah 33 in the BOECS
Jeremiah 33 in the BOGWICC
Jeremiah 33 in the BOHCB
Jeremiah 33 in the BOHCV
Jeremiah 33 in the BOHLNT
Jeremiah 33 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 33 in the BOICB
Jeremiah 33 in the BOILNTAP
Jeremiah 33 in the BOITCV
Jeremiah 33 in the BOKCV
Jeremiah 33 in the BOKCV2
Jeremiah 33 in the BOKHWOG
Jeremiah 33 in the BOKSSV
Jeremiah 33 in the BOLCB
Jeremiah 33 in the BOLCB2
Jeremiah 33 in the BOMCV
Jeremiah 33 in the BONAV
Jeremiah 33 in the BONCB
Jeremiah 33 in the BONLT
Jeremiah 33 in the BONUT2
Jeremiah 33 in the BOPLNT
Jeremiah 33 in the BOSCB
Jeremiah 33 in the BOSNC
Jeremiah 33 in the BOTLNT
Jeremiah 33 in the BOVCB
Jeremiah 33 in the BPBB
Jeremiah 33 in the BPH
Jeremiah 33 in the BSB
Jeremiah 33 in the CCB
Jeremiah 33 in the CUV
Jeremiah 33 in the CUVS
Jeremiah 33 in the DBT
Jeremiah 33 in the DGDNT
Jeremiah 33 in the DHNT
Jeremiah 33 in the DNT
Jeremiah 33 in the ELBE
Jeremiah 33 in the EMTV
Jeremiah 33 in the ESV
Jeremiah 33 in the FBV
Jeremiah 33 in the FEB
Jeremiah 33 in the GGMNT
Jeremiah 33 in the GNT
Jeremiah 33 in the HARY
Jeremiah 33 in the HNT
Jeremiah 33 in the IRVA
Jeremiah 33 in the IRVB
Jeremiah 33 in the IRVG
Jeremiah 33 in the IRVH
Jeremiah 33 in the IRVK
Jeremiah 33 in the IRVM
Jeremiah 33 in the IRVM2
Jeremiah 33 in the IRVO
Jeremiah 33 in the IRVP
Jeremiah 33 in the IRVT
Jeremiah 33 in the IRVT2
Jeremiah 33 in the IRVU
Jeremiah 33 in the ISVN
Jeremiah 33 in the JSNT
Jeremiah 33 in the KAPI
Jeremiah 33 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 33 in the KBV
Jeremiah 33 in the KJV
Jeremiah 33 in the KNFD
Jeremiah 33 in the LBA
Jeremiah 33 in the LBLA
Jeremiah 33 in the LNT
Jeremiah 33 in the LSV
Jeremiah 33 in the MAAL
Jeremiah 33 in the MBV
Jeremiah 33 in the MBV2
Jeremiah 33 in the MHNT
Jeremiah 33 in the MKNFD
Jeremiah 33 in the MNG
Jeremiah 33 in the MNT
Jeremiah 33 in the MNT2
Jeremiah 33 in the MRS1T
Jeremiah 33 in the NAA
Jeremiah 33 in the NASB
Jeremiah 33 in the NBLA
Jeremiah 33 in the NBS
Jeremiah 33 in the NBVTP
Jeremiah 33 in the NET2
Jeremiah 33 in the NIV11
Jeremiah 33 in the NNT
Jeremiah 33 in the NNT2
Jeremiah 33 in the NNT3
Jeremiah 33 in the PDDPT
Jeremiah 33 in the PFNT
Jeremiah 33 in the RMNT
Jeremiah 33 in the SBIAS
Jeremiah 33 in the SBIBS
Jeremiah 33 in the SBIBS2
Jeremiah 33 in the SBICS
Jeremiah 33 in the SBIDS
Jeremiah 33 in the SBIGS
Jeremiah 33 in the SBIHS
Jeremiah 33 in the SBIIS
Jeremiah 33 in the SBIIS2
Jeremiah 33 in the SBIIS3
Jeremiah 33 in the SBIKS
Jeremiah 33 in the SBIKS2
Jeremiah 33 in the SBIMS
Jeremiah 33 in the SBIOS
Jeremiah 33 in the SBIPS
Jeremiah 33 in the SBISS
Jeremiah 33 in the SBITS
Jeremiah 33 in the SBITS2
Jeremiah 33 in the SBITS3
Jeremiah 33 in the SBITS4
Jeremiah 33 in the SBIUS
Jeremiah 33 in the SBIVS
Jeremiah 33 in the SBT
Jeremiah 33 in the SBT1E
Jeremiah 33 in the SCHL
Jeremiah 33 in the SNT
Jeremiah 33 in the SUSU
Jeremiah 33 in the SUSU2
Jeremiah 33 in the SYNO
Jeremiah 33 in the TBIAOTANT
Jeremiah 33 in the TBT1E
Jeremiah 33 in the TBT1E2
Jeremiah 33 in the TFTIP
Jeremiah 33 in the TFTU
Jeremiah 33 in the TGNTATF3T
Jeremiah 33 in the THAI
Jeremiah 33 in the TNFD
Jeremiah 33 in the TNT
Jeremiah 33 in the TNTIK
Jeremiah 33 in the TNTIL
Jeremiah 33 in the TNTIN
Jeremiah 33 in the TNTIP
Jeremiah 33 in the TNTIZ
Jeremiah 33 in the TOMA
Jeremiah 33 in the TTENT
Jeremiah 33 in the UBG
Jeremiah 33 in the UGV
Jeremiah 33 in the UGV2
Jeremiah 33 in the UGV3
Jeremiah 33 in the VBL
Jeremiah 33 in the VDCC
Jeremiah 33 in the YALU
Jeremiah 33 in the YAPE
Jeremiah 33 in the YBVTP
Jeremiah 33 in the ZBP