Jeremiah 44 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2 “Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3 Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5 Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró. 6 Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí. 7 “Báyìí tún ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8 Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9 Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10 Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín. 11 “Fún ìdí èyí, báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run. 12 Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn. 13 Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu. 14 Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.” 15 Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16 “Wọn sì wí pé, àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ OLÚWA. 17 Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi. 18 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.” 19 Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?” 20 Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, 21 “Ṣe OLÚWA kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú. 22 Nígbà tí OLÚWA kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí. 23 Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí OLÚWA àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.” 24 Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26 Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí, ‘pé kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra, “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27 Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán. 28 Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín. 29 “ ‘Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí OLÚWA ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’ 30 Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”

In Other Versions

Jeremiah 44 in the ANGEFD

Jeremiah 44 in the ANTPNG2D

Jeremiah 44 in the AS21

Jeremiah 44 in the BAGH

Jeremiah 44 in the BBPNG

Jeremiah 44 in the BBT1E

Jeremiah 44 in the BDS

Jeremiah 44 in the BEV

Jeremiah 44 in the BHAD

Jeremiah 44 in the BIB

Jeremiah 44 in the BLPT

Jeremiah 44 in the BNT

Jeremiah 44 in the BNTABOOT

Jeremiah 44 in the BNTLV

Jeremiah 44 in the BOATCB

Jeremiah 44 in the BOATCB2

Jeremiah 44 in the BOBCV

Jeremiah 44 in the BOCNT

Jeremiah 44 in the BOECS

Jeremiah 44 in the BOGWICC

Jeremiah 44 in the BOHCB

Jeremiah 44 in the BOHCV

Jeremiah 44 in the BOHLNT

Jeremiah 44 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 44 in the BOICB

Jeremiah 44 in the BOILNTAP

Jeremiah 44 in the BOITCV

Jeremiah 44 in the BOKCV

Jeremiah 44 in the BOKCV2

Jeremiah 44 in the BOKHWOG

Jeremiah 44 in the BOKSSV

Jeremiah 44 in the BOLCB

Jeremiah 44 in the BOLCB2

Jeremiah 44 in the BOMCV

Jeremiah 44 in the BONAV

Jeremiah 44 in the BONCB

Jeremiah 44 in the BONLT

Jeremiah 44 in the BONUT2

Jeremiah 44 in the BOPLNT

Jeremiah 44 in the BOSCB

Jeremiah 44 in the BOSNC

Jeremiah 44 in the BOTLNT

Jeremiah 44 in the BOVCB

Jeremiah 44 in the BPBB

Jeremiah 44 in the BPH

Jeremiah 44 in the BSB

Jeremiah 44 in the CCB

Jeremiah 44 in the CUV

Jeremiah 44 in the CUVS

Jeremiah 44 in the DBT

Jeremiah 44 in the DGDNT

Jeremiah 44 in the DHNT

Jeremiah 44 in the DNT

Jeremiah 44 in the ELBE

Jeremiah 44 in the EMTV

Jeremiah 44 in the ESV

Jeremiah 44 in the FBV

Jeremiah 44 in the FEB

Jeremiah 44 in the GGMNT

Jeremiah 44 in the GNT

Jeremiah 44 in the HARY

Jeremiah 44 in the HNT

Jeremiah 44 in the IRVA

Jeremiah 44 in the IRVB

Jeremiah 44 in the IRVG

Jeremiah 44 in the IRVH

Jeremiah 44 in the IRVK

Jeremiah 44 in the IRVM

Jeremiah 44 in the IRVM2

Jeremiah 44 in the IRVO

Jeremiah 44 in the IRVP

Jeremiah 44 in the IRVT

Jeremiah 44 in the IRVT2

Jeremiah 44 in the IRVU

Jeremiah 44 in the ISVN

Jeremiah 44 in the JSNT

Jeremiah 44 in the KAPI

Jeremiah 44 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 44 in the KBV

Jeremiah 44 in the KJV

Jeremiah 44 in the KNFD

Jeremiah 44 in the LBA

Jeremiah 44 in the LBLA

Jeremiah 44 in the LNT

Jeremiah 44 in the LSV

Jeremiah 44 in the MAAL

Jeremiah 44 in the MBV

Jeremiah 44 in the MBV2

Jeremiah 44 in the MHNT

Jeremiah 44 in the MKNFD

Jeremiah 44 in the MNG

Jeremiah 44 in the MNT

Jeremiah 44 in the MNT2

Jeremiah 44 in the MRS1T

Jeremiah 44 in the NAA

Jeremiah 44 in the NASB

Jeremiah 44 in the NBLA

Jeremiah 44 in the NBS

Jeremiah 44 in the NBVTP

Jeremiah 44 in the NET2

Jeremiah 44 in the NIV11

Jeremiah 44 in the NNT

Jeremiah 44 in the NNT2

Jeremiah 44 in the NNT3

Jeremiah 44 in the PDDPT

Jeremiah 44 in the PFNT

Jeremiah 44 in the RMNT

Jeremiah 44 in the SBIAS

Jeremiah 44 in the SBIBS

Jeremiah 44 in the SBIBS2

Jeremiah 44 in the SBICS

Jeremiah 44 in the SBIDS

Jeremiah 44 in the SBIGS

Jeremiah 44 in the SBIHS

Jeremiah 44 in the SBIIS

Jeremiah 44 in the SBIIS2

Jeremiah 44 in the SBIIS3

Jeremiah 44 in the SBIKS

Jeremiah 44 in the SBIKS2

Jeremiah 44 in the SBIMS

Jeremiah 44 in the SBIOS

Jeremiah 44 in the SBIPS

Jeremiah 44 in the SBISS

Jeremiah 44 in the SBITS

Jeremiah 44 in the SBITS2

Jeremiah 44 in the SBITS3

Jeremiah 44 in the SBITS4

Jeremiah 44 in the SBIUS

Jeremiah 44 in the SBIVS

Jeremiah 44 in the SBT

Jeremiah 44 in the SBT1E

Jeremiah 44 in the SCHL

Jeremiah 44 in the SNT

Jeremiah 44 in the SUSU

Jeremiah 44 in the SUSU2

Jeremiah 44 in the SYNO

Jeremiah 44 in the TBIAOTANT

Jeremiah 44 in the TBT1E

Jeremiah 44 in the TBT1E2

Jeremiah 44 in the TFTIP

Jeremiah 44 in the TFTU

Jeremiah 44 in the TGNTATF3T

Jeremiah 44 in the THAI

Jeremiah 44 in the TNFD

Jeremiah 44 in the TNT

Jeremiah 44 in the TNTIK

Jeremiah 44 in the TNTIL

Jeremiah 44 in the TNTIN

Jeremiah 44 in the TNTIP

Jeremiah 44 in the TNTIZ

Jeremiah 44 in the TOMA

Jeremiah 44 in the TTENT

Jeremiah 44 in the UBG

Jeremiah 44 in the UGV

Jeremiah 44 in the UGV2

Jeremiah 44 in the UGV3

Jeremiah 44 in the VBL

Jeremiah 44 in the VDCC

Jeremiah 44 in the YALU

Jeremiah 44 in the YAPE

Jeremiah 44 in the YBVTP

Jeremiah 44 in the ZBP