Job 14 (BOYCB)

1 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. 2 Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́. 3 Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ? 4 Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?Kò sí ẹnìkan! 5 Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ,ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀. 6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi,títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe. 7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a báké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ. 8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀, 9 síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn. 10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù,àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́. 11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ, 12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn. 13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi! 14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé. 15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi? 17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀. 18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀. 19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sìmú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo. 20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò. 21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn. 22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìroraọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

In Other Versions

Job 14 in the ANGEFD

Job 14 in the ANTPNG2D

Job 14 in the AS21

Job 14 in the BAGH

Job 14 in the BBPNG

Job 14 in the BBT1E

Job 14 in the BDS

Job 14 in the BEV

Job 14 in the BHAD

Job 14 in the BIB

Job 14 in the BLPT

Job 14 in the BNT

Job 14 in the BNTABOOT

Job 14 in the BNTLV

Job 14 in the BOATCB

Job 14 in the BOATCB2

Job 14 in the BOBCV

Job 14 in the BOCNT

Job 14 in the BOECS

Job 14 in the BOGWICC

Job 14 in the BOHCB

Job 14 in the BOHCV

Job 14 in the BOHLNT

Job 14 in the BOHNTLTAL

Job 14 in the BOICB

Job 14 in the BOILNTAP

Job 14 in the BOITCV

Job 14 in the BOKCV

Job 14 in the BOKCV2

Job 14 in the BOKHWOG

Job 14 in the BOKSSV

Job 14 in the BOLCB

Job 14 in the BOLCB2

Job 14 in the BOMCV

Job 14 in the BONAV

Job 14 in the BONCB

Job 14 in the BONLT

Job 14 in the BONUT2

Job 14 in the BOPLNT

Job 14 in the BOSCB

Job 14 in the BOSNC

Job 14 in the BOTLNT

Job 14 in the BOVCB

Job 14 in the BPBB

Job 14 in the BPH

Job 14 in the BSB

Job 14 in the CCB

Job 14 in the CUV

Job 14 in the CUVS

Job 14 in the DBT

Job 14 in the DGDNT

Job 14 in the DHNT

Job 14 in the DNT

Job 14 in the ELBE

Job 14 in the EMTV

Job 14 in the ESV

Job 14 in the FBV

Job 14 in the FEB

Job 14 in the GGMNT

Job 14 in the GNT

Job 14 in the HARY

Job 14 in the HNT

Job 14 in the IRVA

Job 14 in the IRVB

Job 14 in the IRVG

Job 14 in the IRVH

Job 14 in the IRVK

Job 14 in the IRVM

Job 14 in the IRVM2

Job 14 in the IRVO

Job 14 in the IRVP

Job 14 in the IRVT

Job 14 in the IRVT2

Job 14 in the IRVU

Job 14 in the ISVN

Job 14 in the JSNT

Job 14 in the KAPI

Job 14 in the KBT1ETNIK

Job 14 in the KBV

Job 14 in the KJV

Job 14 in the KNFD

Job 14 in the LBA

Job 14 in the LBLA

Job 14 in the LNT

Job 14 in the LSV

Job 14 in the MAAL

Job 14 in the MBV

Job 14 in the MBV2

Job 14 in the MHNT

Job 14 in the MKNFD

Job 14 in the MNG

Job 14 in the MNT

Job 14 in the MNT2

Job 14 in the MRS1T

Job 14 in the NAA

Job 14 in the NASB

Job 14 in the NBLA

Job 14 in the NBS

Job 14 in the NBVTP

Job 14 in the NET2

Job 14 in the NIV11

Job 14 in the NNT

Job 14 in the NNT2

Job 14 in the NNT3

Job 14 in the PDDPT

Job 14 in the PFNT

Job 14 in the RMNT

Job 14 in the SBIAS

Job 14 in the SBIBS

Job 14 in the SBIBS2

Job 14 in the SBICS

Job 14 in the SBIDS

Job 14 in the SBIGS

Job 14 in the SBIHS

Job 14 in the SBIIS

Job 14 in the SBIIS2

Job 14 in the SBIIS3

Job 14 in the SBIKS

Job 14 in the SBIKS2

Job 14 in the SBIMS

Job 14 in the SBIOS

Job 14 in the SBIPS

Job 14 in the SBISS

Job 14 in the SBITS

Job 14 in the SBITS2

Job 14 in the SBITS3

Job 14 in the SBITS4

Job 14 in the SBIUS

Job 14 in the SBIVS

Job 14 in the SBT

Job 14 in the SBT1E

Job 14 in the SCHL

Job 14 in the SNT

Job 14 in the SUSU

Job 14 in the SUSU2

Job 14 in the SYNO

Job 14 in the TBIAOTANT

Job 14 in the TBT1E

Job 14 in the TBT1E2

Job 14 in the TFTIP

Job 14 in the TFTU

Job 14 in the TGNTATF3T

Job 14 in the THAI

Job 14 in the TNFD

Job 14 in the TNT

Job 14 in the TNTIK

Job 14 in the TNTIL

Job 14 in the TNTIN

Job 14 in the TNTIP

Job 14 in the TNTIZ

Job 14 in the TOMA

Job 14 in the TTENT

Job 14 in the UBG

Job 14 in the UGV

Job 14 in the UGV2

Job 14 in the UGV3

Job 14 in the VBL

Job 14 in the VDCC

Job 14 in the YALU

Job 14 in the YAPE

Job 14 in the YBVTP

Job 14 in the ZBP