Job 28 (BOYCB)

1 Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ,àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà. 2 Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá. 3 Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn,ó sì ṣe àwárí ìṣúraláti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo. 4 Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè,àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀,wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn. 5 Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná; 6 òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire,o sì ní erùpẹ̀ wúrà. 7 Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀,àti ojú gúnnugún kò rí i rí. 8 Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí. 9 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá. 10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo. 11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,níbo sì ni òye ń gbe? 13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.” 15 A kò le è fi wúrà rà á,bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀. 16 A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye,tàbí òkúta safire díye lé e. 17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀. 18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ. 19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀. 20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?Tàbí níbo ni òye ń gbé? 21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run. 22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀. 23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé. 24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run, 25 láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi. 26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, 27 nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí. 28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,“Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

In Other Versions

Job 28 in the ANGEFD

Job 28 in the ANTPNG2D

Job 28 in the AS21

Job 28 in the BAGH

Job 28 in the BBPNG

Job 28 in the BBT1E

Job 28 in the BDS

Job 28 in the BEV

Job 28 in the BHAD

Job 28 in the BIB

Job 28 in the BLPT

Job 28 in the BNT

Job 28 in the BNTABOOT

Job 28 in the BNTLV

Job 28 in the BOATCB

Job 28 in the BOATCB2

Job 28 in the BOBCV

Job 28 in the BOCNT

Job 28 in the BOECS

Job 28 in the BOGWICC

Job 28 in the BOHCB

Job 28 in the BOHCV

Job 28 in the BOHLNT

Job 28 in the BOHNTLTAL

Job 28 in the BOICB

Job 28 in the BOILNTAP

Job 28 in the BOITCV

Job 28 in the BOKCV

Job 28 in the BOKCV2

Job 28 in the BOKHWOG

Job 28 in the BOKSSV

Job 28 in the BOLCB

Job 28 in the BOLCB2

Job 28 in the BOMCV

Job 28 in the BONAV

Job 28 in the BONCB

Job 28 in the BONLT

Job 28 in the BONUT2

Job 28 in the BOPLNT

Job 28 in the BOSCB

Job 28 in the BOSNC

Job 28 in the BOTLNT

Job 28 in the BOVCB

Job 28 in the BPBB

Job 28 in the BPH

Job 28 in the BSB

Job 28 in the CCB

Job 28 in the CUV

Job 28 in the CUVS

Job 28 in the DBT

Job 28 in the DGDNT

Job 28 in the DHNT

Job 28 in the DNT

Job 28 in the ELBE

Job 28 in the EMTV

Job 28 in the ESV

Job 28 in the FBV

Job 28 in the FEB

Job 28 in the GGMNT

Job 28 in the GNT

Job 28 in the HARY

Job 28 in the HNT

Job 28 in the IRVA

Job 28 in the IRVB

Job 28 in the IRVG

Job 28 in the IRVH

Job 28 in the IRVK

Job 28 in the IRVM

Job 28 in the IRVM2

Job 28 in the IRVO

Job 28 in the IRVP

Job 28 in the IRVT

Job 28 in the IRVT2

Job 28 in the IRVU

Job 28 in the ISVN

Job 28 in the JSNT

Job 28 in the KAPI

Job 28 in the KBT1ETNIK

Job 28 in the KBV

Job 28 in the KJV

Job 28 in the KNFD

Job 28 in the LBA

Job 28 in the LBLA

Job 28 in the LNT

Job 28 in the LSV

Job 28 in the MAAL

Job 28 in the MBV

Job 28 in the MBV2

Job 28 in the MHNT

Job 28 in the MKNFD

Job 28 in the MNG

Job 28 in the MNT

Job 28 in the MNT2

Job 28 in the MRS1T

Job 28 in the NAA

Job 28 in the NASB

Job 28 in the NBLA

Job 28 in the NBS

Job 28 in the NBVTP

Job 28 in the NET2

Job 28 in the NIV11

Job 28 in the NNT

Job 28 in the NNT2

Job 28 in the NNT3

Job 28 in the PDDPT

Job 28 in the PFNT

Job 28 in the RMNT

Job 28 in the SBIAS

Job 28 in the SBIBS

Job 28 in the SBIBS2

Job 28 in the SBICS

Job 28 in the SBIDS

Job 28 in the SBIGS

Job 28 in the SBIHS

Job 28 in the SBIIS

Job 28 in the SBIIS2

Job 28 in the SBIIS3

Job 28 in the SBIKS

Job 28 in the SBIKS2

Job 28 in the SBIMS

Job 28 in the SBIOS

Job 28 in the SBIPS

Job 28 in the SBISS

Job 28 in the SBITS

Job 28 in the SBITS2

Job 28 in the SBITS3

Job 28 in the SBITS4

Job 28 in the SBIUS

Job 28 in the SBIVS

Job 28 in the SBT

Job 28 in the SBT1E

Job 28 in the SCHL

Job 28 in the SNT

Job 28 in the SUSU

Job 28 in the SUSU2

Job 28 in the SYNO

Job 28 in the TBIAOTANT

Job 28 in the TBT1E

Job 28 in the TBT1E2

Job 28 in the TFTIP

Job 28 in the TFTU

Job 28 in the TGNTATF3T

Job 28 in the THAI

Job 28 in the TNFD

Job 28 in the TNT

Job 28 in the TNTIK

Job 28 in the TNTIL

Job 28 in the TNTIN

Job 28 in the TNTIP

Job 28 in the TNTIZ

Job 28 in the TOMA

Job 28 in the TTENT

Job 28 in the UBG

Job 28 in the UGV

Job 28 in the UGV2

Job 28 in the UGV3

Job 28 in the VBL

Job 28 in the VDCC

Job 28 in the YALU

Job 28 in the YAPE

Job 28 in the YBVTP

Job 28 in the ZBP