Job 9 (BOYCB)

1 Jobu sì dáhùn ó sì wí pé, 2 “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run? 3 Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀rọ̀. 4 Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun.Ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí? 5 Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀. 6 Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì. 7 Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́. 8 Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun. 9 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni,Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù. 10 Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,àní ohun ìyanu láìní iye. 11 Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀. 12 Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì? 13 Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀. 14 “Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí? 15 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú. 16 Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. 17 Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. 18 Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi. 19 Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò? 20 Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi. 21 “Olóòótọ́ ni mo ṣe,síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,ayé mi ní èmi ìbá máa gàn. 22 Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’ 23 Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀. 24 Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni? 25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀. 26 Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ. 27 Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’ 28 Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀. 29 Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí? 30 Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́, 31 síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihòọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra. 32 “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́. 33 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì watí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára. 34 Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí. 35 Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.

In Other Versions

Job 9 in the ANGEFD

Job 9 in the ANTPNG2D

Job 9 in the AS21

Job 9 in the BAGH

Job 9 in the BBPNG

Job 9 in the BBT1E

Job 9 in the BDS

Job 9 in the BEV

Job 9 in the BHAD

Job 9 in the BIB

Job 9 in the BLPT

Job 9 in the BNT

Job 9 in the BNTABOOT

Job 9 in the BNTLV

Job 9 in the BOATCB

Job 9 in the BOATCB2

Job 9 in the BOBCV

Job 9 in the BOCNT

Job 9 in the BOECS

Job 9 in the BOGWICC

Job 9 in the BOHCB

Job 9 in the BOHCV

Job 9 in the BOHLNT

Job 9 in the BOHNTLTAL

Job 9 in the BOICB

Job 9 in the BOILNTAP

Job 9 in the BOITCV

Job 9 in the BOKCV

Job 9 in the BOKCV2

Job 9 in the BOKHWOG

Job 9 in the BOKSSV

Job 9 in the BOLCB

Job 9 in the BOLCB2

Job 9 in the BOMCV

Job 9 in the BONAV

Job 9 in the BONCB

Job 9 in the BONLT

Job 9 in the BONUT2

Job 9 in the BOPLNT

Job 9 in the BOSCB

Job 9 in the BOSNC

Job 9 in the BOTLNT

Job 9 in the BOVCB

Job 9 in the BPBB

Job 9 in the BPH

Job 9 in the BSB

Job 9 in the CCB

Job 9 in the CUV

Job 9 in the CUVS

Job 9 in the DBT

Job 9 in the DGDNT

Job 9 in the DHNT

Job 9 in the DNT

Job 9 in the ELBE

Job 9 in the EMTV

Job 9 in the ESV

Job 9 in the FBV

Job 9 in the FEB

Job 9 in the GGMNT

Job 9 in the GNT

Job 9 in the HARY

Job 9 in the HNT

Job 9 in the IRVA

Job 9 in the IRVB

Job 9 in the IRVG

Job 9 in the IRVH

Job 9 in the IRVK

Job 9 in the IRVM

Job 9 in the IRVM2

Job 9 in the IRVO

Job 9 in the IRVP

Job 9 in the IRVT

Job 9 in the IRVT2

Job 9 in the IRVU

Job 9 in the ISVN

Job 9 in the JSNT

Job 9 in the KAPI

Job 9 in the KBT1ETNIK

Job 9 in the KBV

Job 9 in the KJV

Job 9 in the KNFD

Job 9 in the LBA

Job 9 in the LBLA

Job 9 in the LNT

Job 9 in the LSV

Job 9 in the MAAL

Job 9 in the MBV

Job 9 in the MBV2

Job 9 in the MHNT

Job 9 in the MKNFD

Job 9 in the MNG

Job 9 in the MNT

Job 9 in the MNT2

Job 9 in the MRS1T

Job 9 in the NAA

Job 9 in the NASB

Job 9 in the NBLA

Job 9 in the NBS

Job 9 in the NBVTP

Job 9 in the NET2

Job 9 in the NIV11

Job 9 in the NNT

Job 9 in the NNT2

Job 9 in the NNT3

Job 9 in the PDDPT

Job 9 in the PFNT

Job 9 in the RMNT

Job 9 in the SBIAS

Job 9 in the SBIBS

Job 9 in the SBIBS2

Job 9 in the SBICS

Job 9 in the SBIDS

Job 9 in the SBIGS

Job 9 in the SBIHS

Job 9 in the SBIIS

Job 9 in the SBIIS2

Job 9 in the SBIIS3

Job 9 in the SBIKS

Job 9 in the SBIKS2

Job 9 in the SBIMS

Job 9 in the SBIOS

Job 9 in the SBIPS

Job 9 in the SBISS

Job 9 in the SBITS

Job 9 in the SBITS2

Job 9 in the SBITS3

Job 9 in the SBITS4

Job 9 in the SBIUS

Job 9 in the SBIVS

Job 9 in the SBT

Job 9 in the SBT1E

Job 9 in the SCHL

Job 9 in the SNT

Job 9 in the SUSU

Job 9 in the SUSU2

Job 9 in the SYNO

Job 9 in the TBIAOTANT

Job 9 in the TBT1E

Job 9 in the TBT1E2

Job 9 in the TFTIP

Job 9 in the TFTU

Job 9 in the TGNTATF3T

Job 9 in the THAI

Job 9 in the TNFD

Job 9 in the TNT

Job 9 in the TNTIK

Job 9 in the TNTIL

Job 9 in the TNTIN

Job 9 in the TNTIP

Job 9 in the TNTIZ

Job 9 in the TOMA

Job 9 in the TTENT

Job 9 in the UBG

Job 9 in the UGV

Job 9 in the UGV2

Job 9 in the UGV3

Job 9 in the VBL

Job 9 in the VDCC

Job 9 in the YALU

Job 9 in the YAPE

Job 9 in the YBVTP

Job 9 in the ZBP