Joshua 5 (BOYCB)
1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí OLÚWA ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli. 2 Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kejì.” 3 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà, ní Gibiati-Haralotu. 4 Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà. 6 Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí OLÚWA. Nítorí OLÚWA ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin. 7 Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. 8 Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná. 9 Nígbà náà ní OLÚWA wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Ejibiti kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gilgali títí ó fi di òní yìí. 10 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gilgali ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko, àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ọdún àjọ ìrékọjá. 11 Ní ọjọ́ kejì àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan. 12 Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani. 13 Nígbà tí Joṣua súnmọ́ Jeriko, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?” 14 “Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun OLÚWA ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” 15 Olórí ogun OLÚWA sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.
In Other Versions
Joshua 5 in the ANGEFD
Joshua 5 in the ANTPNG2D
Joshua 5 in the AS21
Joshua 5 in the BAGH
Joshua 5 in the BBPNG
Joshua 5 in the BBT1E
Joshua 5 in the BDS
Joshua 5 in the BEV
Joshua 5 in the BHAD
Joshua 5 in the BIB
Joshua 5 in the BLPT
Joshua 5 in the BNT
Joshua 5 in the BNTABOOT
Joshua 5 in the BNTLV
Joshua 5 in the BOATCB
Joshua 5 in the BOATCB2
Joshua 5 in the BOBCV
Joshua 5 in the BOCNT
Joshua 5 in the BOECS
Joshua 5 in the BOGWICC
Joshua 5 in the BOHCB
Joshua 5 in the BOHCV
Joshua 5 in the BOHLNT
Joshua 5 in the BOHNTLTAL
Joshua 5 in the BOICB
Joshua 5 in the BOILNTAP
Joshua 5 in the BOITCV
Joshua 5 in the BOKCV
Joshua 5 in the BOKCV2
Joshua 5 in the BOKHWOG
Joshua 5 in the BOKSSV
Joshua 5 in the BOLCB
Joshua 5 in the BOLCB2
Joshua 5 in the BOMCV
Joshua 5 in the BONAV
Joshua 5 in the BONCB
Joshua 5 in the BONLT
Joshua 5 in the BONUT2
Joshua 5 in the BOPLNT
Joshua 5 in the BOSCB
Joshua 5 in the BOSNC
Joshua 5 in the BOTLNT
Joshua 5 in the BOVCB
Joshua 5 in the BPBB
Joshua 5 in the BPH
Joshua 5 in the BSB
Joshua 5 in the CCB
Joshua 5 in the CUV
Joshua 5 in the CUVS
Joshua 5 in the DBT
Joshua 5 in the DGDNT
Joshua 5 in the DHNT
Joshua 5 in the DNT
Joshua 5 in the ELBE
Joshua 5 in the EMTV
Joshua 5 in the ESV
Joshua 5 in the FBV
Joshua 5 in the FEB
Joshua 5 in the GGMNT
Joshua 5 in the GNT
Joshua 5 in the HARY
Joshua 5 in the HNT
Joshua 5 in the IRVA
Joshua 5 in the IRVB
Joshua 5 in the IRVG
Joshua 5 in the IRVH
Joshua 5 in the IRVK
Joshua 5 in the IRVM
Joshua 5 in the IRVM2
Joshua 5 in the IRVO
Joshua 5 in the IRVP
Joshua 5 in the IRVT
Joshua 5 in the IRVT2
Joshua 5 in the IRVU
Joshua 5 in the ISVN
Joshua 5 in the JSNT
Joshua 5 in the KAPI
Joshua 5 in the KBT1ETNIK
Joshua 5 in the KBV
Joshua 5 in the KJV
Joshua 5 in the KNFD
Joshua 5 in the LBA
Joshua 5 in the LBLA
Joshua 5 in the LNT
Joshua 5 in the LSV
Joshua 5 in the MAAL
Joshua 5 in the MBV
Joshua 5 in the MBV2
Joshua 5 in the MHNT
Joshua 5 in the MKNFD
Joshua 5 in the MNG
Joshua 5 in the MNT
Joshua 5 in the MNT2
Joshua 5 in the MRS1T
Joshua 5 in the NAA
Joshua 5 in the NASB
Joshua 5 in the NBLA
Joshua 5 in the NBS
Joshua 5 in the NBVTP
Joshua 5 in the NET2
Joshua 5 in the NIV11
Joshua 5 in the NNT
Joshua 5 in the NNT2
Joshua 5 in the NNT3
Joshua 5 in the PDDPT
Joshua 5 in the PFNT
Joshua 5 in the RMNT
Joshua 5 in the SBIAS
Joshua 5 in the SBIBS
Joshua 5 in the SBIBS2
Joshua 5 in the SBICS
Joshua 5 in the SBIDS
Joshua 5 in the SBIGS
Joshua 5 in the SBIHS
Joshua 5 in the SBIIS
Joshua 5 in the SBIIS2
Joshua 5 in the SBIIS3
Joshua 5 in the SBIKS
Joshua 5 in the SBIKS2
Joshua 5 in the SBIMS
Joshua 5 in the SBIOS
Joshua 5 in the SBIPS
Joshua 5 in the SBISS
Joshua 5 in the SBITS
Joshua 5 in the SBITS2
Joshua 5 in the SBITS3
Joshua 5 in the SBITS4
Joshua 5 in the SBIUS
Joshua 5 in the SBIVS
Joshua 5 in the SBT
Joshua 5 in the SBT1E
Joshua 5 in the SCHL
Joshua 5 in the SNT
Joshua 5 in the SUSU
Joshua 5 in the SUSU2
Joshua 5 in the SYNO
Joshua 5 in the TBIAOTANT
Joshua 5 in the TBT1E
Joshua 5 in the TBT1E2
Joshua 5 in the TFTIP
Joshua 5 in the TFTU
Joshua 5 in the TGNTATF3T
Joshua 5 in the THAI
Joshua 5 in the TNFD
Joshua 5 in the TNT
Joshua 5 in the TNTIK
Joshua 5 in the TNTIL
Joshua 5 in the TNTIN
Joshua 5 in the TNTIP
Joshua 5 in the TNTIZ
Joshua 5 in the TOMA
Joshua 5 in the TTENT
Joshua 5 in the UBG
Joshua 5 in the UGV
Joshua 5 in the UGV2
Joshua 5 in the UGV3
Joshua 5 in the VBL
Joshua 5 in the VDCC
Joshua 5 in the YALU
Joshua 5 in the YAPE
Joshua 5 in the YBVTP
Joshua 5 in the ZBP