Leviticus 20 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín Israẹli, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Moleki, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. 3 Èmi tìkára mi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà Moleki ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú. 4 Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà Moleki tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀. 5 Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn, òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn. 6 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 7 “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín. 8 Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLÚWA tí ó sọ yín di mímọ́. 9 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀. 10 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa. 11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 12 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 13 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra, pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn. 14 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀, ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín. 15 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà. 16 “ ‘Bí obìnrin kan bá súnmọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn. 17 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí, ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn, ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀. 18 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn. 19 “ ‘Má ṣe bá arábìnrin baba tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòhò ìbátan rẹ, ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín. 20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin baba rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin baba rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ. 21 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ. 22 “ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má ba à pọ̀ yín jáde. 23 Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kórìíra wọn. 24 Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn, Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù. 25 “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrín ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrín ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́. 26 Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé, Èmi OLÚWA fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi. 27 “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”
In Other Versions
Leviticus 20 in the ANGEFD
Leviticus 20 in the ANTPNG2D
Leviticus 20 in the AS21
Leviticus 20 in the BAGH
Leviticus 20 in the BBPNG
Leviticus 20 in the BBT1E
Leviticus 20 in the BDS
Leviticus 20 in the BEV
Leviticus 20 in the BHAD
Leviticus 20 in the BIB
Leviticus 20 in the BLPT
Leviticus 20 in the BNT
Leviticus 20 in the BNTABOOT
Leviticus 20 in the BNTLV
Leviticus 20 in the BOATCB
Leviticus 20 in the BOATCB2
Leviticus 20 in the BOBCV
Leviticus 20 in the BOCNT
Leviticus 20 in the BOECS
Leviticus 20 in the BOGWICC
Leviticus 20 in the BOHCB
Leviticus 20 in the BOHCV
Leviticus 20 in the BOHLNT
Leviticus 20 in the BOHNTLTAL
Leviticus 20 in the BOICB
Leviticus 20 in the BOILNTAP
Leviticus 20 in the BOITCV
Leviticus 20 in the BOKCV
Leviticus 20 in the BOKCV2
Leviticus 20 in the BOKHWOG
Leviticus 20 in the BOKSSV
Leviticus 20 in the BOLCB
Leviticus 20 in the BOLCB2
Leviticus 20 in the BOMCV
Leviticus 20 in the BONAV
Leviticus 20 in the BONCB
Leviticus 20 in the BONLT
Leviticus 20 in the BONUT2
Leviticus 20 in the BOPLNT
Leviticus 20 in the BOSCB
Leviticus 20 in the BOSNC
Leviticus 20 in the BOTLNT
Leviticus 20 in the BOVCB
Leviticus 20 in the BPBB
Leviticus 20 in the BPH
Leviticus 20 in the BSB
Leviticus 20 in the CCB
Leviticus 20 in the CUV
Leviticus 20 in the CUVS
Leviticus 20 in the DBT
Leviticus 20 in the DGDNT
Leviticus 20 in the DHNT
Leviticus 20 in the DNT
Leviticus 20 in the ELBE
Leviticus 20 in the EMTV
Leviticus 20 in the ESV
Leviticus 20 in the FBV
Leviticus 20 in the FEB
Leviticus 20 in the GGMNT
Leviticus 20 in the GNT
Leviticus 20 in the HARY
Leviticus 20 in the HNT
Leviticus 20 in the IRVA
Leviticus 20 in the IRVB
Leviticus 20 in the IRVG
Leviticus 20 in the IRVH
Leviticus 20 in the IRVK
Leviticus 20 in the IRVM
Leviticus 20 in the IRVM2
Leviticus 20 in the IRVO
Leviticus 20 in the IRVP
Leviticus 20 in the IRVT
Leviticus 20 in the IRVT2
Leviticus 20 in the IRVU
Leviticus 20 in the ISVN
Leviticus 20 in the JSNT
Leviticus 20 in the KAPI
Leviticus 20 in the KBT1ETNIK
Leviticus 20 in the KBV
Leviticus 20 in the KJV
Leviticus 20 in the KNFD
Leviticus 20 in the LBA
Leviticus 20 in the LBLA
Leviticus 20 in the LNT
Leviticus 20 in the LSV
Leviticus 20 in the MAAL
Leviticus 20 in the MBV
Leviticus 20 in the MBV2
Leviticus 20 in the MHNT
Leviticus 20 in the MKNFD
Leviticus 20 in the MNG
Leviticus 20 in the MNT
Leviticus 20 in the MNT2
Leviticus 20 in the MRS1T
Leviticus 20 in the NAA
Leviticus 20 in the NASB
Leviticus 20 in the NBLA
Leviticus 20 in the NBS
Leviticus 20 in the NBVTP
Leviticus 20 in the NET2
Leviticus 20 in the NIV11
Leviticus 20 in the NNT
Leviticus 20 in the NNT2
Leviticus 20 in the NNT3
Leviticus 20 in the PDDPT
Leviticus 20 in the PFNT
Leviticus 20 in the RMNT
Leviticus 20 in the SBIAS
Leviticus 20 in the SBIBS
Leviticus 20 in the SBIBS2
Leviticus 20 in the SBICS
Leviticus 20 in the SBIDS
Leviticus 20 in the SBIGS
Leviticus 20 in the SBIHS
Leviticus 20 in the SBIIS
Leviticus 20 in the SBIIS2
Leviticus 20 in the SBIIS3
Leviticus 20 in the SBIKS
Leviticus 20 in the SBIKS2
Leviticus 20 in the SBIMS
Leviticus 20 in the SBIOS
Leviticus 20 in the SBIPS
Leviticus 20 in the SBISS
Leviticus 20 in the SBITS
Leviticus 20 in the SBITS2
Leviticus 20 in the SBITS3
Leviticus 20 in the SBITS4
Leviticus 20 in the SBIUS
Leviticus 20 in the SBIVS
Leviticus 20 in the SBT
Leviticus 20 in the SBT1E
Leviticus 20 in the SCHL
Leviticus 20 in the SNT
Leviticus 20 in the SUSU
Leviticus 20 in the SUSU2
Leviticus 20 in the SYNO
Leviticus 20 in the TBIAOTANT
Leviticus 20 in the TBT1E
Leviticus 20 in the TBT1E2
Leviticus 20 in the TFTIP
Leviticus 20 in the TFTU
Leviticus 20 in the TGNTATF3T
Leviticus 20 in the THAI
Leviticus 20 in the TNFD
Leviticus 20 in the TNT
Leviticus 20 in the TNTIK
Leviticus 20 in the TNTIL
Leviticus 20 in the TNTIN
Leviticus 20 in the TNTIP
Leviticus 20 in the TNTIZ
Leviticus 20 in the TOMA
Leviticus 20 in the TTENT
Leviticus 20 in the UBG
Leviticus 20 in the UGV
Leviticus 20 in the UGV2
Leviticus 20 in the UGV3
Leviticus 20 in the VBL
Leviticus 20 in the VDCC
Leviticus 20 in the YALU
Leviticus 20 in the YAPE
Leviticus 20 in the YBVTP
Leviticus 20 in the ZBP