Malachi 3 (BOYCB)
1 “Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni OLÚWA, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 2 Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀. 3 Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún OLÚWA, 4 nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì. 5 “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 6 “Èmi OLÚWA kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu. 7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò ṣe padà?’ 8 “Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’“Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. 9 Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. 10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á. 11 Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 12 “Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 13 “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.“Síbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’ 14 “Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú OLÚWA àwọn ọmọ-ogun? 15 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ” 16 Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù OLÚWA ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, OLÚWA sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù OLÚWA, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀. 17 “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí. 18 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.
In Other Versions
Malachi 3 in the ANGEFD
Malachi 3 in the ANTPNG2D
Malachi 3 in the AS21
Malachi 3 in the BAGH
Malachi 3 in the BBPNG
Malachi 3 in the BBT1E
Malachi 3 in the BDS
Malachi 3 in the BEV
Malachi 3 in the BHAD
Malachi 3 in the BIB
Malachi 3 in the BLPT
Malachi 3 in the BNT
Malachi 3 in the BNTABOOT
Malachi 3 in the BNTLV
Malachi 3 in the BOATCB
Malachi 3 in the BOATCB2
Malachi 3 in the BOBCV
Malachi 3 in the BOCNT
Malachi 3 in the BOECS
Malachi 3 in the BOGWICC
Malachi 3 in the BOHCB
Malachi 3 in the BOHCV
Malachi 3 in the BOHLNT
Malachi 3 in the BOHNTLTAL
Malachi 3 in the BOICB
Malachi 3 in the BOILNTAP
Malachi 3 in the BOITCV
Malachi 3 in the BOKCV
Malachi 3 in the BOKCV2
Malachi 3 in the BOKHWOG
Malachi 3 in the BOKSSV
Malachi 3 in the BOLCB
Malachi 3 in the BOLCB2
Malachi 3 in the BOMCV
Malachi 3 in the BONAV
Malachi 3 in the BONCB
Malachi 3 in the BONLT
Malachi 3 in the BONUT2
Malachi 3 in the BOPLNT
Malachi 3 in the BOSCB
Malachi 3 in the BOSNC
Malachi 3 in the BOTLNT
Malachi 3 in the BOVCB
Malachi 3 in the BPBB
Malachi 3 in the BPH
Malachi 3 in the BSB
Malachi 3 in the CCB
Malachi 3 in the CUV
Malachi 3 in the CUVS
Malachi 3 in the DBT
Malachi 3 in the DGDNT
Malachi 3 in the DHNT
Malachi 3 in the DNT
Malachi 3 in the ELBE
Malachi 3 in the EMTV
Malachi 3 in the ESV
Malachi 3 in the FBV
Malachi 3 in the FEB
Malachi 3 in the GGMNT
Malachi 3 in the GNT
Malachi 3 in the HARY
Malachi 3 in the HNT
Malachi 3 in the IRVA
Malachi 3 in the IRVB
Malachi 3 in the IRVG
Malachi 3 in the IRVH
Malachi 3 in the IRVK
Malachi 3 in the IRVM
Malachi 3 in the IRVM2
Malachi 3 in the IRVO
Malachi 3 in the IRVP
Malachi 3 in the IRVT
Malachi 3 in the IRVT2
Malachi 3 in the IRVU
Malachi 3 in the ISVN
Malachi 3 in the JSNT
Malachi 3 in the KAPI
Malachi 3 in the KBT1ETNIK
Malachi 3 in the KBV
Malachi 3 in the KJV
Malachi 3 in the KNFD
Malachi 3 in the LBA
Malachi 3 in the LBLA
Malachi 3 in the LNT
Malachi 3 in the LSV
Malachi 3 in the MAAL
Malachi 3 in the MBV
Malachi 3 in the MBV2
Malachi 3 in the MHNT
Malachi 3 in the MKNFD
Malachi 3 in the MNG
Malachi 3 in the MNT
Malachi 3 in the MNT2
Malachi 3 in the MRS1T
Malachi 3 in the NAA
Malachi 3 in the NASB
Malachi 3 in the NBLA
Malachi 3 in the NBS
Malachi 3 in the NBVTP
Malachi 3 in the NET2
Malachi 3 in the NIV11
Malachi 3 in the NNT
Malachi 3 in the NNT2
Malachi 3 in the NNT3
Malachi 3 in the PDDPT
Malachi 3 in the PFNT
Malachi 3 in the RMNT
Malachi 3 in the SBIAS
Malachi 3 in the SBIBS
Malachi 3 in the SBIBS2
Malachi 3 in the SBICS
Malachi 3 in the SBIDS
Malachi 3 in the SBIGS
Malachi 3 in the SBIHS
Malachi 3 in the SBIIS
Malachi 3 in the SBIIS2
Malachi 3 in the SBIIS3
Malachi 3 in the SBIKS
Malachi 3 in the SBIKS2
Malachi 3 in the SBIMS
Malachi 3 in the SBIOS
Malachi 3 in the SBIPS
Malachi 3 in the SBISS
Malachi 3 in the SBITS
Malachi 3 in the SBITS2
Malachi 3 in the SBITS3
Malachi 3 in the SBITS4
Malachi 3 in the SBIUS
Malachi 3 in the SBIVS
Malachi 3 in the SBT
Malachi 3 in the SBT1E
Malachi 3 in the SCHL
Malachi 3 in the SNT
Malachi 3 in the SUSU
Malachi 3 in the SUSU2
Malachi 3 in the SYNO
Malachi 3 in the TBIAOTANT
Malachi 3 in the TBT1E
Malachi 3 in the TBT1E2
Malachi 3 in the TFTIP
Malachi 3 in the TFTU
Malachi 3 in the TGNTATF3T
Malachi 3 in the THAI
Malachi 3 in the TNFD
Malachi 3 in the TNT
Malachi 3 in the TNTIK
Malachi 3 in the TNTIL
Malachi 3 in the TNTIN
Malachi 3 in the TNTIP
Malachi 3 in the TNTIZ
Malachi 3 in the TOMA
Malachi 3 in the TTENT
Malachi 3 in the UBG
Malachi 3 in the UGV
Malachi 3 in the UGV2
Malachi 3 in the UGV3
Malachi 3 in the VBL
Malachi 3 in the VDCC
Malachi 3 in the YALU
Malachi 3 in the YAPE
Malachi 3 in the YBVTP
Malachi 3 in the ZBP