Matthew 7 (BOYCB)
1 “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́. 2 Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín. 3 “Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 4 Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. 5 Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò. 6 “Ẹ má ṣe fi ohun mímọ́ fún ajá jẹ, ẹ má sì ṣe sọ ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yín fún ẹlẹ́dẹ̀, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má bà fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn a sì yí padà sí yín, wọn a sì bù yín jẹ. 7 “Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún. 9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? 10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? 12 Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì. 13 “Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín. 15 “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná. 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn. 21 “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’ 24 “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.” 28 Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, 29 nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.
In Other Versions
Matthew 7 in the ANGEFD
Matthew 7 in the ANTPNG2D
Matthew 7 in the AS21
Matthew 7 in the BAGH
Matthew 7 in the BBPNG
Matthew 7 in the BBT1E
Matthew 7 in the BDS
Matthew 7 in the BEV
Matthew 7 in the BHAD
Matthew 7 in the BIB
Matthew 7 in the BLPT
Matthew 7 in the BNT
Matthew 7 in the BNTABOOT
Matthew 7 in the BNTLV
Matthew 7 in the BOATCB
Matthew 7 in the BOATCB2
Matthew 7 in the BOBCV
Matthew 7 in the BOCNT
Matthew 7 in the BOECS
Matthew 7 in the BOGWICC
Matthew 7 in the BOHCB
Matthew 7 in the BOHCV
Matthew 7 in the BOHLNT
Matthew 7 in the BOHNTLTAL
Matthew 7 in the BOICB
Matthew 7 in the BOILNTAP
Matthew 7 in the BOITCV
Matthew 7 in the BOKCV
Matthew 7 in the BOKCV2
Matthew 7 in the BOKHWOG
Matthew 7 in the BOKSSV
Matthew 7 in the BOLCB
Matthew 7 in the BOLCB2
Matthew 7 in the BOMCV
Matthew 7 in the BONAV
Matthew 7 in the BONCB
Matthew 7 in the BONLT
Matthew 7 in the BONUT2
Matthew 7 in the BOPLNT
Matthew 7 in the BOSCB
Matthew 7 in the BOSNC
Matthew 7 in the BOTLNT
Matthew 7 in the BOVCB
Matthew 7 in the BPBB
Matthew 7 in the BPH
Matthew 7 in the BSB
Matthew 7 in the CCB
Matthew 7 in the CUV
Matthew 7 in the CUVS
Matthew 7 in the DBT
Matthew 7 in the DGDNT
Matthew 7 in the DHNT
Matthew 7 in the DNT
Matthew 7 in the ELBE
Matthew 7 in the EMTV
Matthew 7 in the ESV
Matthew 7 in the FBV
Matthew 7 in the FEB
Matthew 7 in the GGMNT
Matthew 7 in the GNT
Matthew 7 in the HARY
Matthew 7 in the HNT
Matthew 7 in the IRVA
Matthew 7 in the IRVB
Matthew 7 in the IRVG
Matthew 7 in the IRVH
Matthew 7 in the IRVK
Matthew 7 in the IRVM
Matthew 7 in the IRVM2
Matthew 7 in the IRVO
Matthew 7 in the IRVP
Matthew 7 in the IRVT
Matthew 7 in the IRVT2
Matthew 7 in the IRVU
Matthew 7 in the ISVN
Matthew 7 in the JSNT
Matthew 7 in the KAPI
Matthew 7 in the KBT1ETNIK
Matthew 7 in the KBV
Matthew 7 in the KJV
Matthew 7 in the KNFD
Matthew 7 in the LBA
Matthew 7 in the LBLA
Matthew 7 in the LNT
Matthew 7 in the LSV
Matthew 7 in the MAAL
Matthew 7 in the MBV
Matthew 7 in the MBV2
Matthew 7 in the MHNT
Matthew 7 in the MKNFD
Matthew 7 in the MNG
Matthew 7 in the MNT
Matthew 7 in the MNT2
Matthew 7 in the MRS1T
Matthew 7 in the NAA
Matthew 7 in the NASB
Matthew 7 in the NBLA
Matthew 7 in the NBS
Matthew 7 in the NBVTP
Matthew 7 in the NET2
Matthew 7 in the NIV11
Matthew 7 in the NNT
Matthew 7 in the NNT2
Matthew 7 in the NNT3
Matthew 7 in the PDDPT
Matthew 7 in the PFNT
Matthew 7 in the RMNT
Matthew 7 in the SBIAS
Matthew 7 in the SBIBS
Matthew 7 in the SBIBS2
Matthew 7 in the SBICS
Matthew 7 in the SBIDS
Matthew 7 in the SBIGS
Matthew 7 in the SBIHS
Matthew 7 in the SBIIS
Matthew 7 in the SBIIS2
Matthew 7 in the SBIIS3
Matthew 7 in the SBIKS
Matthew 7 in the SBIKS2
Matthew 7 in the SBIMS
Matthew 7 in the SBIOS
Matthew 7 in the SBIPS
Matthew 7 in the SBISS
Matthew 7 in the SBITS
Matthew 7 in the SBITS2
Matthew 7 in the SBITS3
Matthew 7 in the SBITS4
Matthew 7 in the SBIUS
Matthew 7 in the SBIVS
Matthew 7 in the SBT
Matthew 7 in the SBT1E
Matthew 7 in the SCHL
Matthew 7 in the SNT
Matthew 7 in the SUSU
Matthew 7 in the SUSU2
Matthew 7 in the SYNO
Matthew 7 in the TBIAOTANT
Matthew 7 in the TBT1E
Matthew 7 in the TBT1E2
Matthew 7 in the TFTIP
Matthew 7 in the TFTU
Matthew 7 in the TGNTATF3T
Matthew 7 in the THAI
Matthew 7 in the TNFD
Matthew 7 in the TNT
Matthew 7 in the TNTIK
Matthew 7 in the TNTIL
Matthew 7 in the TNTIN
Matthew 7 in the TNTIP
Matthew 7 in the TNTIZ
Matthew 7 in the TOMA
Matthew 7 in the TTENT
Matthew 7 in the UBG
Matthew 7 in the UGV
Matthew 7 in the UGV2
Matthew 7 in the UGV3
Matthew 7 in the VBL
Matthew 7 in the VDCC
Matthew 7 in the YALU
Matthew 7 in the YAPE
Matthew 7 in the YBVTP
Matthew 7 in the ZBP