Numbers 10 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. 3 Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 4 Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ. 5 Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. 6 Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra. 7 Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀. 8 “Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. 9 Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú OLÚWA, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10 Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.” 11 Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí. 12 Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani. 13 Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ OLÚWA láti ẹnu Mose. 14 Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn. 15 Netaneli ọmọ Suari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari; 16 Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni. 17 Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra. 18 Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn. 19 Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni. 20 Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi. 21 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé. 22 Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn. 23 Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase. 24 Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini. 25 Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn. 26 Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, 27 Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali. 28 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. 29 Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí OLÚWA sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé OLÚWA ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.” 30 Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.” 31 Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa. 32 Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí OLÚWA bá fún wa.” 33 Wọ́n sì gbéra láti orí òkè OLÚWA ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí OLÚWA ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn. 34 Ìkùùkuu OLÚWA wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó. 35 Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé,“Dìde, OLÚWA!Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká,kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.” 36 Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé,“Padà, OLÚWA,sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”
In Other Versions
Numbers 10 in the ANGEFD
Numbers 10 in the ANTPNG2D
Numbers 10 in the AS21
Numbers 10 in the BAGH
Numbers 10 in the BBPNG
Numbers 10 in the BBT1E
Numbers 10 in the BDS
Numbers 10 in the BEV
Numbers 10 in the BHAD
Numbers 10 in the BIB
Numbers 10 in the BLPT
Numbers 10 in the BNT
Numbers 10 in the BNTABOOT
Numbers 10 in the BNTLV
Numbers 10 in the BOATCB
Numbers 10 in the BOATCB2
Numbers 10 in the BOBCV
Numbers 10 in the BOCNT
Numbers 10 in the BOECS
Numbers 10 in the BOGWICC
Numbers 10 in the BOHCB
Numbers 10 in the BOHCV
Numbers 10 in the BOHLNT
Numbers 10 in the BOHNTLTAL
Numbers 10 in the BOICB
Numbers 10 in the BOILNTAP
Numbers 10 in the BOITCV
Numbers 10 in the BOKCV
Numbers 10 in the BOKCV2
Numbers 10 in the BOKHWOG
Numbers 10 in the BOKSSV
Numbers 10 in the BOLCB
Numbers 10 in the BOLCB2
Numbers 10 in the BOMCV
Numbers 10 in the BONAV
Numbers 10 in the BONCB
Numbers 10 in the BONLT
Numbers 10 in the BONUT2
Numbers 10 in the BOPLNT
Numbers 10 in the BOSCB
Numbers 10 in the BOSNC
Numbers 10 in the BOTLNT
Numbers 10 in the BOVCB
Numbers 10 in the BPBB
Numbers 10 in the BPH
Numbers 10 in the BSB
Numbers 10 in the CCB
Numbers 10 in the CUV
Numbers 10 in the CUVS
Numbers 10 in the DBT
Numbers 10 in the DGDNT
Numbers 10 in the DHNT
Numbers 10 in the DNT
Numbers 10 in the ELBE
Numbers 10 in the EMTV
Numbers 10 in the ESV
Numbers 10 in the FBV
Numbers 10 in the FEB
Numbers 10 in the GGMNT
Numbers 10 in the GNT
Numbers 10 in the HARY
Numbers 10 in the HNT
Numbers 10 in the IRVA
Numbers 10 in the IRVB
Numbers 10 in the IRVG
Numbers 10 in the IRVH
Numbers 10 in the IRVK
Numbers 10 in the IRVM
Numbers 10 in the IRVM2
Numbers 10 in the IRVO
Numbers 10 in the IRVP
Numbers 10 in the IRVT
Numbers 10 in the IRVT2
Numbers 10 in the IRVU
Numbers 10 in the ISVN
Numbers 10 in the JSNT
Numbers 10 in the KAPI
Numbers 10 in the KBT1ETNIK
Numbers 10 in the KBV
Numbers 10 in the KJV
Numbers 10 in the KNFD
Numbers 10 in the LBA
Numbers 10 in the LBLA
Numbers 10 in the LNT
Numbers 10 in the LSV
Numbers 10 in the MAAL
Numbers 10 in the MBV
Numbers 10 in the MBV2
Numbers 10 in the MHNT
Numbers 10 in the MKNFD
Numbers 10 in the MNG
Numbers 10 in the MNT
Numbers 10 in the MNT2
Numbers 10 in the MRS1T
Numbers 10 in the NAA
Numbers 10 in the NASB
Numbers 10 in the NBLA
Numbers 10 in the NBS
Numbers 10 in the NBVTP
Numbers 10 in the NET2
Numbers 10 in the NIV11
Numbers 10 in the NNT
Numbers 10 in the NNT2
Numbers 10 in the NNT3
Numbers 10 in the PDDPT
Numbers 10 in the PFNT
Numbers 10 in the RMNT
Numbers 10 in the SBIAS
Numbers 10 in the SBIBS
Numbers 10 in the SBIBS2
Numbers 10 in the SBICS
Numbers 10 in the SBIDS
Numbers 10 in the SBIGS
Numbers 10 in the SBIHS
Numbers 10 in the SBIIS
Numbers 10 in the SBIIS2
Numbers 10 in the SBIIS3
Numbers 10 in the SBIKS
Numbers 10 in the SBIKS2
Numbers 10 in the SBIMS
Numbers 10 in the SBIOS
Numbers 10 in the SBIPS
Numbers 10 in the SBISS
Numbers 10 in the SBITS
Numbers 10 in the SBITS2
Numbers 10 in the SBITS3
Numbers 10 in the SBITS4
Numbers 10 in the SBIUS
Numbers 10 in the SBIVS
Numbers 10 in the SBT
Numbers 10 in the SBT1E
Numbers 10 in the SCHL
Numbers 10 in the SNT
Numbers 10 in the SUSU
Numbers 10 in the SUSU2
Numbers 10 in the SYNO
Numbers 10 in the TBIAOTANT
Numbers 10 in the TBT1E
Numbers 10 in the TBT1E2
Numbers 10 in the TFTIP
Numbers 10 in the TFTU
Numbers 10 in the TGNTATF3T
Numbers 10 in the THAI
Numbers 10 in the TNFD
Numbers 10 in the TNT
Numbers 10 in the TNTIK
Numbers 10 in the TNTIL
Numbers 10 in the TNTIN
Numbers 10 in the TNTIP
Numbers 10 in the TNTIZ
Numbers 10 in the TOMA
Numbers 10 in the TTENT
Numbers 10 in the UBG
Numbers 10 in the UGV
Numbers 10 in the UGV2
Numbers 10 in the UGV3
Numbers 10 in the VBL
Numbers 10 in the VDCC
Numbers 10 in the YALU
Numbers 10 in the YAPE
Numbers 10 in the YBVTP
Numbers 10 in the ZBP