Numbers 13 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.” 3 Mose sì rán wọn jáde láti aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLÚWA. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli. 4 Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakkuri; 5 láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori; 6 láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne; 7 láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu; 8 láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni; 9 láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu; 10 láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi; 11 láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi; 12 láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli; 13 láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli. 14 láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi; 15 láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki. 16 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.) 17 Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè. 18 Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19 Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20 Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.) 21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22 Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23 Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24 Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25 Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. 26 Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. 28 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. 29 Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.” 30 Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.” 31 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.” 32 Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. 33 A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”
In Other Versions
Numbers 13 in the ANGEFD
Numbers 13 in the ANTPNG2D
Numbers 13 in the AS21
Numbers 13 in the BAGH
Numbers 13 in the BBPNG
Numbers 13 in the BBT1E
Numbers 13 in the BDS
Numbers 13 in the BEV
Numbers 13 in the BHAD
Numbers 13 in the BIB
Numbers 13 in the BLPT
Numbers 13 in the BNT
Numbers 13 in the BNTABOOT
Numbers 13 in the BNTLV
Numbers 13 in the BOATCB
Numbers 13 in the BOATCB2
Numbers 13 in the BOBCV
Numbers 13 in the BOCNT
Numbers 13 in the BOECS
Numbers 13 in the BOGWICC
Numbers 13 in the BOHCB
Numbers 13 in the BOHCV
Numbers 13 in the BOHLNT
Numbers 13 in the BOHNTLTAL
Numbers 13 in the BOICB
Numbers 13 in the BOILNTAP
Numbers 13 in the BOITCV
Numbers 13 in the BOKCV
Numbers 13 in the BOKCV2
Numbers 13 in the BOKHWOG
Numbers 13 in the BOKSSV
Numbers 13 in the BOLCB
Numbers 13 in the BOLCB2
Numbers 13 in the BOMCV
Numbers 13 in the BONAV
Numbers 13 in the BONCB
Numbers 13 in the BONLT
Numbers 13 in the BONUT2
Numbers 13 in the BOPLNT
Numbers 13 in the BOSCB
Numbers 13 in the BOSNC
Numbers 13 in the BOTLNT
Numbers 13 in the BOVCB
Numbers 13 in the BPBB
Numbers 13 in the BPH
Numbers 13 in the BSB
Numbers 13 in the CCB
Numbers 13 in the CUV
Numbers 13 in the CUVS
Numbers 13 in the DBT
Numbers 13 in the DGDNT
Numbers 13 in the DHNT
Numbers 13 in the DNT
Numbers 13 in the ELBE
Numbers 13 in the EMTV
Numbers 13 in the ESV
Numbers 13 in the FBV
Numbers 13 in the FEB
Numbers 13 in the GGMNT
Numbers 13 in the GNT
Numbers 13 in the HARY
Numbers 13 in the HNT
Numbers 13 in the IRVA
Numbers 13 in the IRVB
Numbers 13 in the IRVG
Numbers 13 in the IRVH
Numbers 13 in the IRVK
Numbers 13 in the IRVM
Numbers 13 in the IRVM2
Numbers 13 in the IRVO
Numbers 13 in the IRVP
Numbers 13 in the IRVT
Numbers 13 in the IRVT2
Numbers 13 in the IRVU
Numbers 13 in the ISVN
Numbers 13 in the JSNT
Numbers 13 in the KAPI
Numbers 13 in the KBT1ETNIK
Numbers 13 in the KBV
Numbers 13 in the KJV
Numbers 13 in the KNFD
Numbers 13 in the LBA
Numbers 13 in the LBLA
Numbers 13 in the LNT
Numbers 13 in the LSV
Numbers 13 in the MAAL
Numbers 13 in the MBV
Numbers 13 in the MBV2
Numbers 13 in the MHNT
Numbers 13 in the MKNFD
Numbers 13 in the MNG
Numbers 13 in the MNT
Numbers 13 in the MNT2
Numbers 13 in the MRS1T
Numbers 13 in the NAA
Numbers 13 in the NASB
Numbers 13 in the NBLA
Numbers 13 in the NBS
Numbers 13 in the NBVTP
Numbers 13 in the NET2
Numbers 13 in the NIV11
Numbers 13 in the NNT
Numbers 13 in the NNT2
Numbers 13 in the NNT3
Numbers 13 in the PDDPT
Numbers 13 in the PFNT
Numbers 13 in the RMNT
Numbers 13 in the SBIAS
Numbers 13 in the SBIBS
Numbers 13 in the SBIBS2
Numbers 13 in the SBICS
Numbers 13 in the SBIDS
Numbers 13 in the SBIGS
Numbers 13 in the SBIHS
Numbers 13 in the SBIIS
Numbers 13 in the SBIIS2
Numbers 13 in the SBIIS3
Numbers 13 in the SBIKS
Numbers 13 in the SBIKS2
Numbers 13 in the SBIMS
Numbers 13 in the SBIOS
Numbers 13 in the SBIPS
Numbers 13 in the SBISS
Numbers 13 in the SBITS
Numbers 13 in the SBITS2
Numbers 13 in the SBITS3
Numbers 13 in the SBITS4
Numbers 13 in the SBIUS
Numbers 13 in the SBIVS
Numbers 13 in the SBT
Numbers 13 in the SBT1E
Numbers 13 in the SCHL
Numbers 13 in the SNT
Numbers 13 in the SUSU
Numbers 13 in the SUSU2
Numbers 13 in the SYNO
Numbers 13 in the TBIAOTANT
Numbers 13 in the TBT1E
Numbers 13 in the TBT1E2
Numbers 13 in the TFTIP
Numbers 13 in the TFTU
Numbers 13 in the TGNTATF3T
Numbers 13 in the THAI
Numbers 13 in the TNFD
Numbers 13 in the TNT
Numbers 13 in the TNTIK
Numbers 13 in the TNTIL
Numbers 13 in the TNTIN
Numbers 13 in the TNTIP
Numbers 13 in the TNTIZ
Numbers 13 in the TOMA
Numbers 13 in the TTENT
Numbers 13 in the UBG
Numbers 13 in the UGV
Numbers 13 in the UGV2
Numbers 13 in the UGV3
Numbers 13 in the VBL
Numbers 13 in the VDCC
Numbers 13 in the YALU
Numbers 13 in the YAPE
Numbers 13 in the YBVTP
Numbers 13 in the ZBP