Proverbs 6 (BOYCB)

1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn, 2 bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté. 3 Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹníwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;bẹ aládùúgbò rẹ dáradára. 4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá. 5 Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ. 6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n! 7 Kò ní olùdarí,kò sí alábojútó tàbí ọba, 8 síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjòyóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè. 9 Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ? 10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀. 11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣààti àìní bí adigunjalè. 12 Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú,tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, 13 tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò,ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe, 14 tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀. 15 Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn;yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. 16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLÚWA kórìíra,ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i, 17 Ojú ìgbéraga,ahọ́n tó ń parọ́ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, 18 ọkàn tí ń pète ohun búburú,ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà, 19 ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nuàti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan. 20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. 21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. 22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. 23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwíni ọ̀nà sí ìyè. 24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì. 25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹtàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra. 26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára. 27 Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itankí aṣọ rẹ̀ má sì jóná? 28 Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná? 29 Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà. 30 Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalènítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. 31 Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méjebí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà. 32 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú;ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni. 33 Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé. 34 Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san. 35 Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn;yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.

In Other Versions

Proverbs 6 in the ANGEFD

Proverbs 6 in the ANTPNG2D

Proverbs 6 in the AS21

Proverbs 6 in the BAGH

Proverbs 6 in the BBPNG

Proverbs 6 in the BBT1E

Proverbs 6 in the BDS

Proverbs 6 in the BEV

Proverbs 6 in the BHAD

Proverbs 6 in the BIB

Proverbs 6 in the BLPT

Proverbs 6 in the BNT

Proverbs 6 in the BNTABOOT

Proverbs 6 in the BNTLV

Proverbs 6 in the BOATCB

Proverbs 6 in the BOATCB2

Proverbs 6 in the BOBCV

Proverbs 6 in the BOCNT

Proverbs 6 in the BOECS

Proverbs 6 in the BOGWICC

Proverbs 6 in the BOHCB

Proverbs 6 in the BOHCV

Proverbs 6 in the BOHLNT

Proverbs 6 in the BOHNTLTAL

Proverbs 6 in the BOICB

Proverbs 6 in the BOILNTAP

Proverbs 6 in the BOITCV

Proverbs 6 in the BOKCV

Proverbs 6 in the BOKCV2

Proverbs 6 in the BOKHWOG

Proverbs 6 in the BOKSSV

Proverbs 6 in the BOLCB

Proverbs 6 in the BOLCB2

Proverbs 6 in the BOMCV

Proverbs 6 in the BONAV

Proverbs 6 in the BONCB

Proverbs 6 in the BONLT

Proverbs 6 in the BONUT2

Proverbs 6 in the BOPLNT

Proverbs 6 in the BOSCB

Proverbs 6 in the BOSNC

Proverbs 6 in the BOTLNT

Proverbs 6 in the BOVCB

Proverbs 6 in the BPBB

Proverbs 6 in the BPH

Proverbs 6 in the BSB

Proverbs 6 in the CCB

Proverbs 6 in the CUV

Proverbs 6 in the CUVS

Proverbs 6 in the DBT

Proverbs 6 in the DGDNT

Proverbs 6 in the DHNT

Proverbs 6 in the DNT

Proverbs 6 in the ELBE

Proverbs 6 in the EMTV

Proverbs 6 in the ESV

Proverbs 6 in the FBV

Proverbs 6 in the FEB

Proverbs 6 in the GGMNT

Proverbs 6 in the GNT

Proverbs 6 in the HARY

Proverbs 6 in the HNT

Proverbs 6 in the IRVA

Proverbs 6 in the IRVB

Proverbs 6 in the IRVG

Proverbs 6 in the IRVH

Proverbs 6 in the IRVK

Proverbs 6 in the IRVM

Proverbs 6 in the IRVM2

Proverbs 6 in the IRVO

Proverbs 6 in the IRVP

Proverbs 6 in the IRVT

Proverbs 6 in the IRVT2

Proverbs 6 in the IRVU

Proverbs 6 in the ISVN

Proverbs 6 in the JSNT

Proverbs 6 in the KAPI

Proverbs 6 in the KBT1ETNIK

Proverbs 6 in the KBV

Proverbs 6 in the KJV

Proverbs 6 in the KNFD

Proverbs 6 in the LBA

Proverbs 6 in the LBLA

Proverbs 6 in the LNT

Proverbs 6 in the LSV

Proverbs 6 in the MAAL

Proverbs 6 in the MBV

Proverbs 6 in the MBV2

Proverbs 6 in the MHNT

Proverbs 6 in the MKNFD

Proverbs 6 in the MNG

Proverbs 6 in the MNT

Proverbs 6 in the MNT2

Proverbs 6 in the MRS1T

Proverbs 6 in the NAA

Proverbs 6 in the NASB

Proverbs 6 in the NBLA

Proverbs 6 in the NBS

Proverbs 6 in the NBVTP

Proverbs 6 in the NET2

Proverbs 6 in the NIV11

Proverbs 6 in the NNT

Proverbs 6 in the NNT2

Proverbs 6 in the NNT3

Proverbs 6 in the PDDPT

Proverbs 6 in the PFNT

Proverbs 6 in the RMNT

Proverbs 6 in the SBIAS

Proverbs 6 in the SBIBS

Proverbs 6 in the SBIBS2

Proverbs 6 in the SBICS

Proverbs 6 in the SBIDS

Proverbs 6 in the SBIGS

Proverbs 6 in the SBIHS

Proverbs 6 in the SBIIS

Proverbs 6 in the SBIIS2

Proverbs 6 in the SBIIS3

Proverbs 6 in the SBIKS

Proverbs 6 in the SBIKS2

Proverbs 6 in the SBIMS

Proverbs 6 in the SBIOS

Proverbs 6 in the SBIPS

Proverbs 6 in the SBISS

Proverbs 6 in the SBITS

Proverbs 6 in the SBITS2

Proverbs 6 in the SBITS3

Proverbs 6 in the SBITS4

Proverbs 6 in the SBIUS

Proverbs 6 in the SBIVS

Proverbs 6 in the SBT

Proverbs 6 in the SBT1E

Proverbs 6 in the SCHL

Proverbs 6 in the SNT

Proverbs 6 in the SUSU

Proverbs 6 in the SUSU2

Proverbs 6 in the SYNO

Proverbs 6 in the TBIAOTANT

Proverbs 6 in the TBT1E

Proverbs 6 in the TBT1E2

Proverbs 6 in the TFTIP

Proverbs 6 in the TFTU

Proverbs 6 in the TGNTATF3T

Proverbs 6 in the THAI

Proverbs 6 in the TNFD

Proverbs 6 in the TNT

Proverbs 6 in the TNTIK

Proverbs 6 in the TNTIL

Proverbs 6 in the TNTIN

Proverbs 6 in the TNTIP

Proverbs 6 in the TNTIZ

Proverbs 6 in the TOMA

Proverbs 6 in the TTENT

Proverbs 6 in the UBG

Proverbs 6 in the UGV

Proverbs 6 in the UGV2

Proverbs 6 in the UGV3

Proverbs 6 in the VBL

Proverbs 6 in the VDCC

Proverbs 6 in the YALU

Proverbs 6 in the YAPE

Proverbs 6 in the YBVTP

Proverbs 6 in the ZBP