Psalms 1 (BOYCB)
1 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn. 2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin OLÚWAàti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru. 3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere. 4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkàtí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù. 5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo. 6 Nítorí OLÚWA ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.