Psalms 123 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run. 2 Kíyèsi, bí ojú àwọnìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo OLÚWA Ọlọ́run wa,títí yóò fi ṣàánú fún wa. 3 OLÚWA, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀. 4 Ọkàn wa kún púpọ̀fún ẹ̀gàn àwọn onírera,àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.