Psalms 124 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 1 “Ìbá má ṣe pé OLÚWA tí ó ti wà fún wa,”kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí; 2 ìbá má ṣe pé OLÚWA tó wà ní tiwa,nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa, 3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyènígbà tí ìbínú wọn ru sí wa, 4 nígbà náà ni omiwọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀, 5 nígbà náà ni agbéragaomi ìbá borí ọkàn wa. 6 Olùbùkún ni OLÚWA, tí kò fi wá fún wọ́nbí ohun ọdẹ fún eyín wọn. 7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;okùn já àwa sì yọ. 8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ OLÚWA,tí ó dá ọ̀run òun ayé.