Psalms 93 (BOYCB)
1 OLÚWA ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;ọláńlá ni OLÚWA wọ̀ ní aṣọàti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì le è yí. 2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;ìwọ wà títí ayérayé. 3 A ti gbé òkun sókè, OLÚWA,òkun ti gbé ohùn wọn sókè;òkun ti gbé rírú omi wọn sókè. 4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,ó ni ògo ju òkun rírú lọ OLÚWA ga ní ògo. 5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́fún ọjọ́ àìlópin, OLÚWA.