Zechariah 9 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀.Ọ̀rọ̀ OLÚWA kọjú ìjà sí Hadiraki,Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀;nítorí ojú OLÚWA ń bẹ lára ènìyàn,àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli. 2 Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi. 3 Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,ó sì kó fàdákà jọ bí eruku,àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. 4 Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,a ó sì fi iná jó o run. 5 Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,Aṣkeloni yóò sì di ahoro. 6 Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu,Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò. 7 Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀:ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda,àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi. 8 Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi kánítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́:nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn. 9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ:òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu,àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu,a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun.Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí.Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun,àti láti odò títí de òpin ayé. 11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ,Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun. 12 Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí:àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì. 13 Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le,mo sì fi Efraimu kún un,Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni,sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki,mo ṣe ọ́ bí idà alágbára. 14 OLÚWA yóò sì fi ara hàn ní orí wọn;ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. OLÚWA Olódùmarè yóò sì fọn ìpè,Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù. 15 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;wọn ó sì jẹ ni run,wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀;wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,wọn ó sì kún bí ọpọ́n,wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ. 16 OLÚWA Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náàbí agbo ènìyàn rẹ̀:nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀. 17 Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀!Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

In Other Versions

Zechariah 9 in the ANGEFD

Zechariah 9 in the ANTPNG2D

Zechariah 9 in the AS21

Zechariah 9 in the BAGH

Zechariah 9 in the BBPNG

Zechariah 9 in the BBT1E

Zechariah 9 in the BDS

Zechariah 9 in the BEV

Zechariah 9 in the BHAD

Zechariah 9 in the BIB

Zechariah 9 in the BLPT

Zechariah 9 in the BNT

Zechariah 9 in the BNTABOOT

Zechariah 9 in the BNTLV

Zechariah 9 in the BOATCB

Zechariah 9 in the BOATCB2

Zechariah 9 in the BOBCV

Zechariah 9 in the BOCNT

Zechariah 9 in the BOECS

Zechariah 9 in the BOGWICC

Zechariah 9 in the BOHCB

Zechariah 9 in the BOHCV

Zechariah 9 in the BOHLNT

Zechariah 9 in the BOHNTLTAL

Zechariah 9 in the BOICB

Zechariah 9 in the BOILNTAP

Zechariah 9 in the BOITCV

Zechariah 9 in the BOKCV

Zechariah 9 in the BOKCV2

Zechariah 9 in the BOKHWOG

Zechariah 9 in the BOKSSV

Zechariah 9 in the BOLCB

Zechariah 9 in the BOLCB2

Zechariah 9 in the BOMCV

Zechariah 9 in the BONAV

Zechariah 9 in the BONCB

Zechariah 9 in the BONLT

Zechariah 9 in the BONUT2

Zechariah 9 in the BOPLNT

Zechariah 9 in the BOSCB

Zechariah 9 in the BOSNC

Zechariah 9 in the BOTLNT

Zechariah 9 in the BOVCB

Zechariah 9 in the BPBB

Zechariah 9 in the BPH

Zechariah 9 in the BSB

Zechariah 9 in the CCB

Zechariah 9 in the CUV

Zechariah 9 in the CUVS

Zechariah 9 in the DBT

Zechariah 9 in the DGDNT

Zechariah 9 in the DHNT

Zechariah 9 in the DNT

Zechariah 9 in the ELBE

Zechariah 9 in the EMTV

Zechariah 9 in the ESV

Zechariah 9 in the FBV

Zechariah 9 in the FEB

Zechariah 9 in the GGMNT

Zechariah 9 in the GNT

Zechariah 9 in the HARY

Zechariah 9 in the HNT

Zechariah 9 in the IRVA

Zechariah 9 in the IRVB

Zechariah 9 in the IRVG

Zechariah 9 in the IRVH

Zechariah 9 in the IRVK

Zechariah 9 in the IRVM

Zechariah 9 in the IRVM2

Zechariah 9 in the IRVO

Zechariah 9 in the IRVP

Zechariah 9 in the IRVT

Zechariah 9 in the IRVT2

Zechariah 9 in the IRVU

Zechariah 9 in the ISVN

Zechariah 9 in the JSNT

Zechariah 9 in the KAPI

Zechariah 9 in the KBT1ETNIK

Zechariah 9 in the KBV

Zechariah 9 in the KJV

Zechariah 9 in the KNFD

Zechariah 9 in the LBA

Zechariah 9 in the LBLA

Zechariah 9 in the LNT

Zechariah 9 in the LSV

Zechariah 9 in the MAAL

Zechariah 9 in the MBV

Zechariah 9 in the MBV2

Zechariah 9 in the MHNT

Zechariah 9 in the MKNFD

Zechariah 9 in the MNG

Zechariah 9 in the MNT

Zechariah 9 in the MNT2

Zechariah 9 in the MRS1T

Zechariah 9 in the NAA

Zechariah 9 in the NASB

Zechariah 9 in the NBLA

Zechariah 9 in the NBS

Zechariah 9 in the NBVTP

Zechariah 9 in the NET2

Zechariah 9 in the NIV11

Zechariah 9 in the NNT

Zechariah 9 in the NNT2

Zechariah 9 in the NNT3

Zechariah 9 in the PDDPT

Zechariah 9 in the PFNT

Zechariah 9 in the RMNT

Zechariah 9 in the SBIAS

Zechariah 9 in the SBIBS

Zechariah 9 in the SBIBS2

Zechariah 9 in the SBICS

Zechariah 9 in the SBIDS

Zechariah 9 in the SBIGS

Zechariah 9 in the SBIHS

Zechariah 9 in the SBIIS

Zechariah 9 in the SBIIS2

Zechariah 9 in the SBIIS3

Zechariah 9 in the SBIKS

Zechariah 9 in the SBIKS2

Zechariah 9 in the SBIMS

Zechariah 9 in the SBIOS

Zechariah 9 in the SBIPS

Zechariah 9 in the SBISS

Zechariah 9 in the SBITS

Zechariah 9 in the SBITS2

Zechariah 9 in the SBITS3

Zechariah 9 in the SBITS4

Zechariah 9 in the SBIUS

Zechariah 9 in the SBIVS

Zechariah 9 in the SBT

Zechariah 9 in the SBT1E

Zechariah 9 in the SCHL

Zechariah 9 in the SNT

Zechariah 9 in the SUSU

Zechariah 9 in the SUSU2

Zechariah 9 in the SYNO

Zechariah 9 in the TBIAOTANT

Zechariah 9 in the TBT1E

Zechariah 9 in the TBT1E2

Zechariah 9 in the TFTIP

Zechariah 9 in the TFTU

Zechariah 9 in the TGNTATF3T

Zechariah 9 in the THAI

Zechariah 9 in the TNFD

Zechariah 9 in the TNT

Zechariah 9 in the TNTIK

Zechariah 9 in the TNTIL

Zechariah 9 in the TNTIN

Zechariah 9 in the TNTIP

Zechariah 9 in the TNTIZ

Zechariah 9 in the TOMA

Zechariah 9 in the TTENT

Zechariah 9 in the UBG

Zechariah 9 in the UGV

Zechariah 9 in the UGV2

Zechariah 9 in the UGV3

Zechariah 9 in the VBL

Zechariah 9 in the VDCC

Zechariah 9 in the YALU

Zechariah 9 in the YAPE

Zechariah 9 in the YBVTP

Zechariah 9 in the ZBP