1 Samuel 13 (BOYCB)

1 Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì. 2 Saulu yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn. 3 Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” 4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali. 5 Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) kẹ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. 6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. 7 Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. 8 Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. 9 Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. 10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i. 11 Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, 12 mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere OLÚWA.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.” 13 Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. 14 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, OLÚWA ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin OLÚWA mọ́.” 15 Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600). 16 Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gibeah ti Benjamini, nígbà tí àwọn Filistini dó ní Mikmasi. 17 Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, 18 òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Seboimu tí ó kọjú sí ijù. 19 A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” 20 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. 21 Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù. 22 Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n. 23 Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi.

In Other Versions

1 Samuel 13 in the ANGEFD

1 Samuel 13 in the ANTPNG2D

1 Samuel 13 in the AS21

1 Samuel 13 in the BAGH

1 Samuel 13 in the BBPNG

1 Samuel 13 in the BBT1E

1 Samuel 13 in the BDS

1 Samuel 13 in the BEV

1 Samuel 13 in the BHAD

1 Samuel 13 in the BIB

1 Samuel 13 in the BLPT

1 Samuel 13 in the BNT

1 Samuel 13 in the BNTABOOT

1 Samuel 13 in the BNTLV

1 Samuel 13 in the BOATCB

1 Samuel 13 in the BOATCB2

1 Samuel 13 in the BOBCV

1 Samuel 13 in the BOCNT

1 Samuel 13 in the BOECS

1 Samuel 13 in the BOGWICC

1 Samuel 13 in the BOHCB

1 Samuel 13 in the BOHCV

1 Samuel 13 in the BOHLNT

1 Samuel 13 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 13 in the BOICB

1 Samuel 13 in the BOILNTAP

1 Samuel 13 in the BOITCV

1 Samuel 13 in the BOKCV

1 Samuel 13 in the BOKCV2

1 Samuel 13 in the BOKHWOG

1 Samuel 13 in the BOKSSV

1 Samuel 13 in the BOLCB

1 Samuel 13 in the BOLCB2

1 Samuel 13 in the BOMCV

1 Samuel 13 in the BONAV

1 Samuel 13 in the BONCB

1 Samuel 13 in the BONLT

1 Samuel 13 in the BONUT2

1 Samuel 13 in the BOPLNT

1 Samuel 13 in the BOSCB

1 Samuel 13 in the BOSNC

1 Samuel 13 in the BOTLNT

1 Samuel 13 in the BOVCB

1 Samuel 13 in the BPBB

1 Samuel 13 in the BPH

1 Samuel 13 in the BSB

1 Samuel 13 in the CCB

1 Samuel 13 in the CUV

1 Samuel 13 in the CUVS

1 Samuel 13 in the DBT

1 Samuel 13 in the DGDNT

1 Samuel 13 in the DHNT

1 Samuel 13 in the DNT

1 Samuel 13 in the ELBE

1 Samuel 13 in the EMTV

1 Samuel 13 in the ESV

1 Samuel 13 in the FBV

1 Samuel 13 in the FEB

1 Samuel 13 in the GGMNT

1 Samuel 13 in the GNT

1 Samuel 13 in the HARY

1 Samuel 13 in the HNT

1 Samuel 13 in the IRVA

1 Samuel 13 in the IRVB

1 Samuel 13 in the IRVG

1 Samuel 13 in the IRVH

1 Samuel 13 in the IRVK

1 Samuel 13 in the IRVM

1 Samuel 13 in the IRVM2

1 Samuel 13 in the IRVO

1 Samuel 13 in the IRVP

1 Samuel 13 in the IRVT

1 Samuel 13 in the IRVT2

1 Samuel 13 in the IRVU

1 Samuel 13 in the ISVN

1 Samuel 13 in the JSNT

1 Samuel 13 in the KAPI

1 Samuel 13 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 13 in the KBV

1 Samuel 13 in the KJV

1 Samuel 13 in the KNFD

1 Samuel 13 in the LBA

1 Samuel 13 in the LBLA

1 Samuel 13 in the LNT

1 Samuel 13 in the LSV

1 Samuel 13 in the MAAL

1 Samuel 13 in the MBV

1 Samuel 13 in the MBV2

1 Samuel 13 in the MHNT

1 Samuel 13 in the MKNFD

1 Samuel 13 in the MNG

1 Samuel 13 in the MNT

1 Samuel 13 in the MNT2

1 Samuel 13 in the MRS1T

1 Samuel 13 in the NAA

1 Samuel 13 in the NASB

1 Samuel 13 in the NBLA

1 Samuel 13 in the NBS

1 Samuel 13 in the NBVTP

1 Samuel 13 in the NET2

1 Samuel 13 in the NIV11

1 Samuel 13 in the NNT

1 Samuel 13 in the NNT2

1 Samuel 13 in the NNT3

1 Samuel 13 in the PDDPT

1 Samuel 13 in the PFNT

1 Samuel 13 in the RMNT

1 Samuel 13 in the SBIAS

1 Samuel 13 in the SBIBS

1 Samuel 13 in the SBIBS2

1 Samuel 13 in the SBICS

1 Samuel 13 in the SBIDS

1 Samuel 13 in the SBIGS

1 Samuel 13 in the SBIHS

1 Samuel 13 in the SBIIS

1 Samuel 13 in the SBIIS2

1 Samuel 13 in the SBIIS3

1 Samuel 13 in the SBIKS

1 Samuel 13 in the SBIKS2

1 Samuel 13 in the SBIMS

1 Samuel 13 in the SBIOS

1 Samuel 13 in the SBIPS

1 Samuel 13 in the SBISS

1 Samuel 13 in the SBITS

1 Samuel 13 in the SBITS2

1 Samuel 13 in the SBITS3

1 Samuel 13 in the SBITS4

1 Samuel 13 in the SBIUS

1 Samuel 13 in the SBIVS

1 Samuel 13 in the SBT

1 Samuel 13 in the SBT1E

1 Samuel 13 in the SCHL

1 Samuel 13 in the SNT

1 Samuel 13 in the SUSU

1 Samuel 13 in the SUSU2

1 Samuel 13 in the SYNO

1 Samuel 13 in the TBIAOTANT

1 Samuel 13 in the TBT1E

1 Samuel 13 in the TBT1E2

1 Samuel 13 in the TFTIP

1 Samuel 13 in the TFTU

1 Samuel 13 in the TGNTATF3T

1 Samuel 13 in the THAI

1 Samuel 13 in the TNFD

1 Samuel 13 in the TNT

1 Samuel 13 in the TNTIK

1 Samuel 13 in the TNTIL

1 Samuel 13 in the TNTIN

1 Samuel 13 in the TNTIP

1 Samuel 13 in the TNTIZ

1 Samuel 13 in the TOMA

1 Samuel 13 in the TTENT

1 Samuel 13 in the UBG

1 Samuel 13 in the UGV

1 Samuel 13 in the UGV2

1 Samuel 13 in the UGV3

1 Samuel 13 in the VBL

1 Samuel 13 in the VDCC

1 Samuel 13 in the YALU

1 Samuel 13 in the YAPE

1 Samuel 13 in the YBVTP

1 Samuel 13 in the ZBP