1 Timothy 6 (BOYCB)
1 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 2 Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́.Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú. 3 Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, 4 Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá, 5 àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí. 6 Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. 7 Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. 8 Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. 9 Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. 10 Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀. 11 Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. 12 Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. 13 Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu, 14 kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa. 16 Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín. 17 Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; 18 kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19 kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú. 20 Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀; 21 èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.
In Other Versions
1 Timothy 6 in the ANGEFD
1 Timothy 6 in the ANTPNG2D
1 Timothy 6 in the AS21
1 Timothy 6 in the BAGH
1 Timothy 6 in the BBPNG
1 Timothy 6 in the BBT1E
1 Timothy 6 in the BDS
1 Timothy 6 in the BEV
1 Timothy 6 in the BHAD
1 Timothy 6 in the BIB
1 Timothy 6 in the BLPT
1 Timothy 6 in the BNT
1 Timothy 6 in the BNTABOOT
1 Timothy 6 in the BNTLV
1 Timothy 6 in the BOATCB
1 Timothy 6 in the BOATCB2
1 Timothy 6 in the BOBCV
1 Timothy 6 in the BOCNT
1 Timothy 6 in the BOECS
1 Timothy 6 in the BOGWICC
1 Timothy 6 in the BOHCB
1 Timothy 6 in the BOHCV
1 Timothy 6 in the BOHLNT
1 Timothy 6 in the BOHNTLTAL
1 Timothy 6 in the BOICB
1 Timothy 6 in the BOILNTAP
1 Timothy 6 in the BOITCV
1 Timothy 6 in the BOKCV
1 Timothy 6 in the BOKCV2
1 Timothy 6 in the BOKHWOG
1 Timothy 6 in the BOKSSV
1 Timothy 6 in the BOLCB
1 Timothy 6 in the BOLCB2
1 Timothy 6 in the BOMCV
1 Timothy 6 in the BONAV
1 Timothy 6 in the BONCB
1 Timothy 6 in the BONLT
1 Timothy 6 in the BONUT2
1 Timothy 6 in the BOPLNT
1 Timothy 6 in the BOSCB
1 Timothy 6 in the BOSNC
1 Timothy 6 in the BOTLNT
1 Timothy 6 in the BOVCB
1 Timothy 6 in the BPBB
1 Timothy 6 in the BPH
1 Timothy 6 in the BSB
1 Timothy 6 in the CCB
1 Timothy 6 in the CUV
1 Timothy 6 in the CUVS
1 Timothy 6 in the DBT
1 Timothy 6 in the DGDNT
1 Timothy 6 in the DHNT
1 Timothy 6 in the DNT
1 Timothy 6 in the ELBE
1 Timothy 6 in the EMTV
1 Timothy 6 in the ESV
1 Timothy 6 in the FBV
1 Timothy 6 in the FEB
1 Timothy 6 in the GGMNT
1 Timothy 6 in the GNT
1 Timothy 6 in the HARY
1 Timothy 6 in the HNT
1 Timothy 6 in the IRVA
1 Timothy 6 in the IRVB
1 Timothy 6 in the IRVG
1 Timothy 6 in the IRVH
1 Timothy 6 in the IRVK
1 Timothy 6 in the IRVM
1 Timothy 6 in the IRVM2
1 Timothy 6 in the IRVO
1 Timothy 6 in the IRVP
1 Timothy 6 in the IRVT
1 Timothy 6 in the IRVT2
1 Timothy 6 in the IRVU
1 Timothy 6 in the ISVN
1 Timothy 6 in the JSNT
1 Timothy 6 in the KAPI
1 Timothy 6 in the KBT1ETNIK
1 Timothy 6 in the KBV
1 Timothy 6 in the KJV
1 Timothy 6 in the KNFD
1 Timothy 6 in the LBA
1 Timothy 6 in the LBLA
1 Timothy 6 in the LNT
1 Timothy 6 in the LSV
1 Timothy 6 in the MAAL
1 Timothy 6 in the MBV
1 Timothy 6 in the MBV2
1 Timothy 6 in the MHNT
1 Timothy 6 in the MKNFD
1 Timothy 6 in the MNG
1 Timothy 6 in the MNT
1 Timothy 6 in the MNT2
1 Timothy 6 in the MRS1T
1 Timothy 6 in the NAA
1 Timothy 6 in the NASB
1 Timothy 6 in the NBLA
1 Timothy 6 in the NBS
1 Timothy 6 in the NBVTP
1 Timothy 6 in the NET2
1 Timothy 6 in the NIV11
1 Timothy 6 in the NNT
1 Timothy 6 in the NNT2
1 Timothy 6 in the NNT3
1 Timothy 6 in the PDDPT
1 Timothy 6 in the PFNT
1 Timothy 6 in the RMNT
1 Timothy 6 in the SBIAS
1 Timothy 6 in the SBIBS
1 Timothy 6 in the SBIBS2
1 Timothy 6 in the SBICS
1 Timothy 6 in the SBIDS
1 Timothy 6 in the SBIGS
1 Timothy 6 in the SBIHS
1 Timothy 6 in the SBIIS
1 Timothy 6 in the SBIIS2
1 Timothy 6 in the SBIIS3
1 Timothy 6 in the SBIKS
1 Timothy 6 in the SBIKS2
1 Timothy 6 in the SBIMS
1 Timothy 6 in the SBIOS
1 Timothy 6 in the SBIPS
1 Timothy 6 in the SBISS
1 Timothy 6 in the SBITS
1 Timothy 6 in the SBITS2
1 Timothy 6 in the SBITS3
1 Timothy 6 in the SBITS4
1 Timothy 6 in the SBIUS
1 Timothy 6 in the SBIVS
1 Timothy 6 in the SBT
1 Timothy 6 in the SBT1E
1 Timothy 6 in the SCHL
1 Timothy 6 in the SNT
1 Timothy 6 in the SUSU
1 Timothy 6 in the SUSU2
1 Timothy 6 in the SYNO
1 Timothy 6 in the TBIAOTANT
1 Timothy 6 in the TBT1E
1 Timothy 6 in the TBT1E2
1 Timothy 6 in the TFTIP
1 Timothy 6 in the TFTU
1 Timothy 6 in the TGNTATF3T
1 Timothy 6 in the THAI
1 Timothy 6 in the TNFD
1 Timothy 6 in the TNT
1 Timothy 6 in the TNTIK
1 Timothy 6 in the TNTIL
1 Timothy 6 in the TNTIN
1 Timothy 6 in the TNTIP
1 Timothy 6 in the TNTIZ
1 Timothy 6 in the TOMA
1 Timothy 6 in the TTENT
1 Timothy 6 in the UBG
1 Timothy 6 in the UGV
1 Timothy 6 in the UGV2
1 Timothy 6 in the UGV3
1 Timothy 6 in the VBL
1 Timothy 6 in the VDCC
1 Timothy 6 in the YALU
1 Timothy 6 in the YAPE
1 Timothy 6 in the YBVTP
1 Timothy 6 in the ZBP