2 Kings 16 (BOYCB)

1 Ní ọdún kẹtàdínlógún Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ ọba. 2 Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jerusalẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí OLÚWA lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 5 Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. 6 Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí. 7 Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.” 8 Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé OLÚWA, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ. 9 Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini. 10 Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀. 11 Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku. 12 Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13 Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú OLÚWA kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé OLÚWA, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà. 15 Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.” 16 Báyìí ni Uriah àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ahasi ọba pàṣẹ. 17 Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́. 18 Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé OLÚWA nítorí ọba Asiria. 19 Àti ìyókù ìṣe Ahasi tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? 20 Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

In Other Versions

2 Kings 16 in the ANGEFD

2 Kings 16 in the ANTPNG2D

2 Kings 16 in the AS21

2 Kings 16 in the BAGH

2 Kings 16 in the BBPNG

2 Kings 16 in the BBT1E

2 Kings 16 in the BDS

2 Kings 16 in the BEV

2 Kings 16 in the BHAD

2 Kings 16 in the BIB

2 Kings 16 in the BLPT

2 Kings 16 in the BNT

2 Kings 16 in the BNTABOOT

2 Kings 16 in the BNTLV

2 Kings 16 in the BOATCB

2 Kings 16 in the BOATCB2

2 Kings 16 in the BOBCV

2 Kings 16 in the BOCNT

2 Kings 16 in the BOECS

2 Kings 16 in the BOGWICC

2 Kings 16 in the BOHCB

2 Kings 16 in the BOHCV

2 Kings 16 in the BOHLNT

2 Kings 16 in the BOHNTLTAL

2 Kings 16 in the BOICB

2 Kings 16 in the BOILNTAP

2 Kings 16 in the BOITCV

2 Kings 16 in the BOKCV

2 Kings 16 in the BOKCV2

2 Kings 16 in the BOKHWOG

2 Kings 16 in the BOKSSV

2 Kings 16 in the BOLCB

2 Kings 16 in the BOLCB2

2 Kings 16 in the BOMCV

2 Kings 16 in the BONAV

2 Kings 16 in the BONCB

2 Kings 16 in the BONLT

2 Kings 16 in the BONUT2

2 Kings 16 in the BOPLNT

2 Kings 16 in the BOSCB

2 Kings 16 in the BOSNC

2 Kings 16 in the BOTLNT

2 Kings 16 in the BOVCB

2 Kings 16 in the BPBB

2 Kings 16 in the BPH

2 Kings 16 in the BSB

2 Kings 16 in the CCB

2 Kings 16 in the CUV

2 Kings 16 in the CUVS

2 Kings 16 in the DBT

2 Kings 16 in the DGDNT

2 Kings 16 in the DHNT

2 Kings 16 in the DNT

2 Kings 16 in the ELBE

2 Kings 16 in the EMTV

2 Kings 16 in the ESV

2 Kings 16 in the FBV

2 Kings 16 in the FEB

2 Kings 16 in the GGMNT

2 Kings 16 in the GNT

2 Kings 16 in the HARY

2 Kings 16 in the HNT

2 Kings 16 in the IRVA

2 Kings 16 in the IRVB

2 Kings 16 in the IRVG

2 Kings 16 in the IRVH

2 Kings 16 in the IRVK

2 Kings 16 in the IRVM

2 Kings 16 in the IRVM2

2 Kings 16 in the IRVO

2 Kings 16 in the IRVP

2 Kings 16 in the IRVT

2 Kings 16 in the IRVT2

2 Kings 16 in the IRVU

2 Kings 16 in the ISVN

2 Kings 16 in the JSNT

2 Kings 16 in the KAPI

2 Kings 16 in the KBT1ETNIK

2 Kings 16 in the KBV

2 Kings 16 in the KJV

2 Kings 16 in the KNFD

2 Kings 16 in the LBA

2 Kings 16 in the LBLA

2 Kings 16 in the LNT

2 Kings 16 in the LSV

2 Kings 16 in the MAAL

2 Kings 16 in the MBV

2 Kings 16 in the MBV2

2 Kings 16 in the MHNT

2 Kings 16 in the MKNFD

2 Kings 16 in the MNG

2 Kings 16 in the MNT

2 Kings 16 in the MNT2

2 Kings 16 in the MRS1T

2 Kings 16 in the NAA

2 Kings 16 in the NASB

2 Kings 16 in the NBLA

2 Kings 16 in the NBS

2 Kings 16 in the NBVTP

2 Kings 16 in the NET2

2 Kings 16 in the NIV11

2 Kings 16 in the NNT

2 Kings 16 in the NNT2

2 Kings 16 in the NNT3

2 Kings 16 in the PDDPT

2 Kings 16 in the PFNT

2 Kings 16 in the RMNT

2 Kings 16 in the SBIAS

2 Kings 16 in the SBIBS

2 Kings 16 in the SBIBS2

2 Kings 16 in the SBICS

2 Kings 16 in the SBIDS

2 Kings 16 in the SBIGS

2 Kings 16 in the SBIHS

2 Kings 16 in the SBIIS

2 Kings 16 in the SBIIS2

2 Kings 16 in the SBIIS3

2 Kings 16 in the SBIKS

2 Kings 16 in the SBIKS2

2 Kings 16 in the SBIMS

2 Kings 16 in the SBIOS

2 Kings 16 in the SBIPS

2 Kings 16 in the SBISS

2 Kings 16 in the SBITS

2 Kings 16 in the SBITS2

2 Kings 16 in the SBITS3

2 Kings 16 in the SBITS4

2 Kings 16 in the SBIUS

2 Kings 16 in the SBIVS

2 Kings 16 in the SBT

2 Kings 16 in the SBT1E

2 Kings 16 in the SCHL

2 Kings 16 in the SNT

2 Kings 16 in the SUSU

2 Kings 16 in the SUSU2

2 Kings 16 in the SYNO

2 Kings 16 in the TBIAOTANT

2 Kings 16 in the TBT1E

2 Kings 16 in the TBT1E2

2 Kings 16 in the TFTIP

2 Kings 16 in the TFTU

2 Kings 16 in the TGNTATF3T

2 Kings 16 in the THAI

2 Kings 16 in the TNFD

2 Kings 16 in the TNT

2 Kings 16 in the TNTIK

2 Kings 16 in the TNTIL

2 Kings 16 in the TNTIN

2 Kings 16 in the TNTIP

2 Kings 16 in the TNTIZ

2 Kings 16 in the TOMA

2 Kings 16 in the TTENT

2 Kings 16 in the UBG

2 Kings 16 in the UGV

2 Kings 16 in the UGV2

2 Kings 16 in the UGV3

2 Kings 16 in the VBL

2 Kings 16 in the VDCC

2 Kings 16 in the YALU

2 Kings 16 in the YAPE

2 Kings 16 in the YBVTP

2 Kings 16 in the ZBP