2 Samuel 16 (BOYCB)
1 Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan. 2 Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?”Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.” 3 Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?”Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ” 4 Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.”Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.” 5 Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. 6 Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 7 Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. 8 OLÚWA mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; OLÚWA ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.” 9 Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.” 10 Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí OLÚWA ti wí fún un pé, ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘Kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ” 11 Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri, ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé OLÚWA ni ó sọ fún un. 12 Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, OLÚWA yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.” 13 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀. 14 Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀. 15 Absalomu àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Israẹli sì wá sí Jerusalẹmu, Ahitofeli sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16 Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.” 17 Absalomu sì wí fún Huṣai pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?” 18 Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí OLÚWA, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó. 19 Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.” 20 Absalomu sì wí fún Ahitofeli pé, “Ẹ bá ará yín gbìmọ̀ ohun tí àwa ó ṣe.” 21 Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ yóò sì le.” 22 Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Absalomu ní òrùlé; Absalomu sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Israẹli. 23 Ìmọ̀ Ahitofeli tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Ahitofeli fún Dafidi àti fún Absalomu sì rí.
In Other Versions
2 Samuel 16 in the ANGEFD
2 Samuel 16 in the ANTPNG2D
2 Samuel 16 in the AS21
2 Samuel 16 in the BAGH
2 Samuel 16 in the BBPNG
2 Samuel 16 in the BBT1E
2 Samuel 16 in the BDS
2 Samuel 16 in the BEV
2 Samuel 16 in the BHAD
2 Samuel 16 in the BIB
2 Samuel 16 in the BLPT
2 Samuel 16 in the BNT
2 Samuel 16 in the BNTABOOT
2 Samuel 16 in the BNTLV
2 Samuel 16 in the BOATCB
2 Samuel 16 in the BOATCB2
2 Samuel 16 in the BOBCV
2 Samuel 16 in the BOCNT
2 Samuel 16 in the BOECS
2 Samuel 16 in the BOGWICC
2 Samuel 16 in the BOHCB
2 Samuel 16 in the BOHCV
2 Samuel 16 in the BOHLNT
2 Samuel 16 in the BOHNTLTAL
2 Samuel 16 in the BOICB
2 Samuel 16 in the BOILNTAP
2 Samuel 16 in the BOITCV
2 Samuel 16 in the BOKCV
2 Samuel 16 in the BOKCV2
2 Samuel 16 in the BOKHWOG
2 Samuel 16 in the BOKSSV
2 Samuel 16 in the BOLCB
2 Samuel 16 in the BOLCB2
2 Samuel 16 in the BOMCV
2 Samuel 16 in the BONAV
2 Samuel 16 in the BONCB
2 Samuel 16 in the BONLT
2 Samuel 16 in the BONUT2
2 Samuel 16 in the BOPLNT
2 Samuel 16 in the BOSCB
2 Samuel 16 in the BOSNC
2 Samuel 16 in the BOTLNT
2 Samuel 16 in the BOVCB
2 Samuel 16 in the BPBB
2 Samuel 16 in the BPH
2 Samuel 16 in the BSB
2 Samuel 16 in the CCB
2 Samuel 16 in the CUV
2 Samuel 16 in the CUVS
2 Samuel 16 in the DBT
2 Samuel 16 in the DGDNT
2 Samuel 16 in the DHNT
2 Samuel 16 in the DNT
2 Samuel 16 in the ELBE
2 Samuel 16 in the EMTV
2 Samuel 16 in the ESV
2 Samuel 16 in the FBV
2 Samuel 16 in the FEB
2 Samuel 16 in the GGMNT
2 Samuel 16 in the GNT
2 Samuel 16 in the HARY
2 Samuel 16 in the HNT
2 Samuel 16 in the IRVA
2 Samuel 16 in the IRVB
2 Samuel 16 in the IRVG
2 Samuel 16 in the IRVH
2 Samuel 16 in the IRVK
2 Samuel 16 in the IRVM
2 Samuel 16 in the IRVM2
2 Samuel 16 in the IRVO
2 Samuel 16 in the IRVP
2 Samuel 16 in the IRVT
2 Samuel 16 in the IRVT2
2 Samuel 16 in the IRVU
2 Samuel 16 in the ISVN
2 Samuel 16 in the JSNT
2 Samuel 16 in the KAPI
2 Samuel 16 in the KBT1ETNIK
2 Samuel 16 in the KBV
2 Samuel 16 in the KJV
2 Samuel 16 in the KNFD
2 Samuel 16 in the LBA
2 Samuel 16 in the LBLA
2 Samuel 16 in the LNT
2 Samuel 16 in the LSV
2 Samuel 16 in the MAAL
2 Samuel 16 in the MBV
2 Samuel 16 in the MBV2
2 Samuel 16 in the MHNT
2 Samuel 16 in the MKNFD
2 Samuel 16 in the MNG
2 Samuel 16 in the MNT
2 Samuel 16 in the MNT2
2 Samuel 16 in the MRS1T
2 Samuel 16 in the NAA
2 Samuel 16 in the NASB
2 Samuel 16 in the NBLA
2 Samuel 16 in the NBS
2 Samuel 16 in the NBVTP
2 Samuel 16 in the NET2
2 Samuel 16 in the NIV11
2 Samuel 16 in the NNT
2 Samuel 16 in the NNT2
2 Samuel 16 in the NNT3
2 Samuel 16 in the PDDPT
2 Samuel 16 in the PFNT
2 Samuel 16 in the RMNT
2 Samuel 16 in the SBIAS
2 Samuel 16 in the SBIBS
2 Samuel 16 in the SBIBS2
2 Samuel 16 in the SBICS
2 Samuel 16 in the SBIDS
2 Samuel 16 in the SBIGS
2 Samuel 16 in the SBIHS
2 Samuel 16 in the SBIIS
2 Samuel 16 in the SBIIS2
2 Samuel 16 in the SBIIS3
2 Samuel 16 in the SBIKS
2 Samuel 16 in the SBIKS2
2 Samuel 16 in the SBIMS
2 Samuel 16 in the SBIOS
2 Samuel 16 in the SBIPS
2 Samuel 16 in the SBISS
2 Samuel 16 in the SBITS
2 Samuel 16 in the SBITS2
2 Samuel 16 in the SBITS3
2 Samuel 16 in the SBITS4
2 Samuel 16 in the SBIUS
2 Samuel 16 in the SBIVS
2 Samuel 16 in the SBT
2 Samuel 16 in the SBT1E
2 Samuel 16 in the SCHL
2 Samuel 16 in the SNT
2 Samuel 16 in the SUSU
2 Samuel 16 in the SUSU2
2 Samuel 16 in the SYNO
2 Samuel 16 in the TBIAOTANT
2 Samuel 16 in the TBT1E
2 Samuel 16 in the TBT1E2
2 Samuel 16 in the TFTIP
2 Samuel 16 in the TFTU
2 Samuel 16 in the TGNTATF3T
2 Samuel 16 in the THAI
2 Samuel 16 in the TNFD
2 Samuel 16 in the TNT
2 Samuel 16 in the TNTIK
2 Samuel 16 in the TNTIL
2 Samuel 16 in the TNTIN
2 Samuel 16 in the TNTIP
2 Samuel 16 in the TNTIZ
2 Samuel 16 in the TOMA
2 Samuel 16 in the TTENT
2 Samuel 16 in the UBG
2 Samuel 16 in the UGV
2 Samuel 16 in the UGV2
2 Samuel 16 in the UGV3
2 Samuel 16 in the VBL
2 Samuel 16 in the VDCC
2 Samuel 16 in the YALU
2 Samuel 16 in the YAPE
2 Samuel 16 in the YBVTP
2 Samuel 16 in the ZBP