2 Samuel 9 (BOYCB)
1 Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani. 2 Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?”Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.” 3 Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?”Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.” 4 Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?”Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.” 5 Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá. 6 Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un.Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!”Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!” 7 Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” 8 Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.” 9 Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. 10 Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.) 11 Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.” 12 Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti. 13 Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.
In Other Versions
2 Samuel 9 in the ANGEFD
2 Samuel 9 in the ANTPNG2D
2 Samuel 9 in the AS21
2 Samuel 9 in the BAGH
2 Samuel 9 in the BBPNG
2 Samuel 9 in the BBT1E
2 Samuel 9 in the BDS
2 Samuel 9 in the BEV
2 Samuel 9 in the BHAD
2 Samuel 9 in the BIB
2 Samuel 9 in the BLPT
2 Samuel 9 in the BNT
2 Samuel 9 in the BNTABOOT
2 Samuel 9 in the BNTLV
2 Samuel 9 in the BOATCB
2 Samuel 9 in the BOATCB2
2 Samuel 9 in the BOBCV
2 Samuel 9 in the BOCNT
2 Samuel 9 in the BOECS
2 Samuel 9 in the BOGWICC
2 Samuel 9 in the BOHCB
2 Samuel 9 in the BOHCV
2 Samuel 9 in the BOHLNT
2 Samuel 9 in the BOHNTLTAL
2 Samuel 9 in the BOICB
2 Samuel 9 in the BOILNTAP
2 Samuel 9 in the BOITCV
2 Samuel 9 in the BOKCV
2 Samuel 9 in the BOKCV2
2 Samuel 9 in the BOKHWOG
2 Samuel 9 in the BOKSSV
2 Samuel 9 in the BOLCB
2 Samuel 9 in the BOLCB2
2 Samuel 9 in the BOMCV
2 Samuel 9 in the BONAV
2 Samuel 9 in the BONCB
2 Samuel 9 in the BONLT
2 Samuel 9 in the BONUT2
2 Samuel 9 in the BOPLNT
2 Samuel 9 in the BOSCB
2 Samuel 9 in the BOSNC
2 Samuel 9 in the BOTLNT
2 Samuel 9 in the BOVCB
2 Samuel 9 in the BPBB
2 Samuel 9 in the BPH
2 Samuel 9 in the BSB
2 Samuel 9 in the CCB
2 Samuel 9 in the CUV
2 Samuel 9 in the CUVS
2 Samuel 9 in the DBT
2 Samuel 9 in the DGDNT
2 Samuel 9 in the DHNT
2 Samuel 9 in the DNT
2 Samuel 9 in the ELBE
2 Samuel 9 in the EMTV
2 Samuel 9 in the ESV
2 Samuel 9 in the FBV
2 Samuel 9 in the FEB
2 Samuel 9 in the GGMNT
2 Samuel 9 in the GNT
2 Samuel 9 in the HARY
2 Samuel 9 in the HNT
2 Samuel 9 in the IRVA
2 Samuel 9 in the IRVB
2 Samuel 9 in the IRVG
2 Samuel 9 in the IRVH
2 Samuel 9 in the IRVK
2 Samuel 9 in the IRVM
2 Samuel 9 in the IRVM2
2 Samuel 9 in the IRVO
2 Samuel 9 in the IRVP
2 Samuel 9 in the IRVT
2 Samuel 9 in the IRVT2
2 Samuel 9 in the IRVU
2 Samuel 9 in the ISVN
2 Samuel 9 in the JSNT
2 Samuel 9 in the KAPI
2 Samuel 9 in the KBT1ETNIK
2 Samuel 9 in the KBV
2 Samuel 9 in the KJV
2 Samuel 9 in the KNFD
2 Samuel 9 in the LBA
2 Samuel 9 in the LBLA
2 Samuel 9 in the LNT
2 Samuel 9 in the LSV
2 Samuel 9 in the MAAL
2 Samuel 9 in the MBV
2 Samuel 9 in the MBV2
2 Samuel 9 in the MHNT
2 Samuel 9 in the MKNFD
2 Samuel 9 in the MNG
2 Samuel 9 in the MNT
2 Samuel 9 in the MNT2
2 Samuel 9 in the MRS1T
2 Samuel 9 in the NAA
2 Samuel 9 in the NASB
2 Samuel 9 in the NBLA
2 Samuel 9 in the NBS
2 Samuel 9 in the NBVTP
2 Samuel 9 in the NET2
2 Samuel 9 in the NIV11
2 Samuel 9 in the NNT
2 Samuel 9 in the NNT2
2 Samuel 9 in the NNT3
2 Samuel 9 in the PDDPT
2 Samuel 9 in the PFNT
2 Samuel 9 in the RMNT
2 Samuel 9 in the SBIAS
2 Samuel 9 in the SBIBS
2 Samuel 9 in the SBIBS2
2 Samuel 9 in the SBICS
2 Samuel 9 in the SBIDS
2 Samuel 9 in the SBIGS
2 Samuel 9 in the SBIHS
2 Samuel 9 in the SBIIS
2 Samuel 9 in the SBIIS2
2 Samuel 9 in the SBIIS3
2 Samuel 9 in the SBIKS
2 Samuel 9 in the SBIKS2
2 Samuel 9 in the SBIMS
2 Samuel 9 in the SBIOS
2 Samuel 9 in the SBIPS
2 Samuel 9 in the SBISS
2 Samuel 9 in the SBITS
2 Samuel 9 in the SBITS2
2 Samuel 9 in the SBITS3
2 Samuel 9 in the SBITS4
2 Samuel 9 in the SBIUS
2 Samuel 9 in the SBIVS
2 Samuel 9 in the SBT
2 Samuel 9 in the SBT1E
2 Samuel 9 in the SCHL
2 Samuel 9 in the SNT
2 Samuel 9 in the SUSU
2 Samuel 9 in the SUSU2
2 Samuel 9 in the SYNO
2 Samuel 9 in the TBIAOTANT
2 Samuel 9 in the TBT1E
2 Samuel 9 in the TBT1E2
2 Samuel 9 in the TFTIP
2 Samuel 9 in the TFTU
2 Samuel 9 in the TGNTATF3T
2 Samuel 9 in the THAI
2 Samuel 9 in the TNFD
2 Samuel 9 in the TNT
2 Samuel 9 in the TNTIK
2 Samuel 9 in the TNTIL
2 Samuel 9 in the TNTIN
2 Samuel 9 in the TNTIP
2 Samuel 9 in the TNTIZ
2 Samuel 9 in the TOMA
2 Samuel 9 in the TTENT
2 Samuel 9 in the UBG
2 Samuel 9 in the UGV
2 Samuel 9 in the UGV2
2 Samuel 9 in the UGV3
2 Samuel 9 in the VBL
2 Samuel 9 in the VDCC
2 Samuel 9 in the YALU
2 Samuel 9 in the YAPE
2 Samuel 9 in the YBVTP
2 Samuel 9 in the ZBP