Acts 12 (BOYCB)
1 Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. 2 Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. 3 Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. 4 Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́. 5 Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un. 6 Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. 7 Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru. 8 Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” 9 Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. 10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ. 11 Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!” 12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!” 16 Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17 Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé, “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn. 18 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. 19 Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n.Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ. 21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́. 24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i. 25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.
In Other Versions
Acts 12 in the ANGEFD
Acts 12 in the ANTPNG2D
Acts 12 in the AS21
Acts 12 in the BAGH
Acts 12 in the BBPNG
Acts 12 in the BBT1E
Acts 12 in the BDS
Acts 12 in the BEV
Acts 12 in the BHAD
Acts 12 in the BIB
Acts 12 in the BLPT
Acts 12 in the BNT
Acts 12 in the BNTABOOT
Acts 12 in the BNTLV
Acts 12 in the BOATCB
Acts 12 in the BOATCB2
Acts 12 in the BOBCV
Acts 12 in the BOCNT
Acts 12 in the BOECS
Acts 12 in the BOGWICC
Acts 12 in the BOHCB
Acts 12 in the BOHCV
Acts 12 in the BOHLNT
Acts 12 in the BOHNTLTAL
Acts 12 in the BOICB
Acts 12 in the BOILNTAP
Acts 12 in the BOITCV
Acts 12 in the BOKCV
Acts 12 in the BOKCV2
Acts 12 in the BOKHWOG
Acts 12 in the BOKSSV
Acts 12 in the BOLCB
Acts 12 in the BOLCB2
Acts 12 in the BOMCV
Acts 12 in the BONAV
Acts 12 in the BONCB
Acts 12 in the BONLT
Acts 12 in the BONUT2
Acts 12 in the BOPLNT
Acts 12 in the BOSCB
Acts 12 in the BOSNC
Acts 12 in the BOTLNT
Acts 12 in the BOVCB
Acts 12 in the BPBB
Acts 12 in the BPH
Acts 12 in the BSB
Acts 12 in the CCB
Acts 12 in the CUV
Acts 12 in the CUVS
Acts 12 in the DBT
Acts 12 in the DGDNT
Acts 12 in the DHNT
Acts 12 in the DNT
Acts 12 in the ELBE
Acts 12 in the EMTV
Acts 12 in the ESV
Acts 12 in the FBV
Acts 12 in the FEB
Acts 12 in the GGMNT
Acts 12 in the GNT
Acts 12 in the HARY
Acts 12 in the HNT
Acts 12 in the IRVA
Acts 12 in the IRVB
Acts 12 in the IRVG
Acts 12 in the IRVH
Acts 12 in the IRVK
Acts 12 in the IRVM
Acts 12 in the IRVM2
Acts 12 in the IRVO
Acts 12 in the IRVP
Acts 12 in the IRVT
Acts 12 in the IRVT2
Acts 12 in the IRVU
Acts 12 in the ISVN
Acts 12 in the JSNT
Acts 12 in the KAPI
Acts 12 in the KBT1ETNIK
Acts 12 in the KBV
Acts 12 in the KJV
Acts 12 in the KNFD
Acts 12 in the LBA
Acts 12 in the LBLA
Acts 12 in the LNT
Acts 12 in the LSV
Acts 12 in the MAAL
Acts 12 in the MBV
Acts 12 in the MBV2
Acts 12 in the MHNT
Acts 12 in the MKNFD
Acts 12 in the MNG
Acts 12 in the MNT
Acts 12 in the MNT2
Acts 12 in the MRS1T
Acts 12 in the NAA
Acts 12 in the NASB
Acts 12 in the NBLA
Acts 12 in the NBS
Acts 12 in the NBVTP
Acts 12 in the NET2
Acts 12 in the NIV11
Acts 12 in the NNT
Acts 12 in the NNT2
Acts 12 in the NNT3
Acts 12 in the PDDPT
Acts 12 in the PFNT
Acts 12 in the RMNT
Acts 12 in the SBIAS
Acts 12 in the SBIBS
Acts 12 in the SBIBS2
Acts 12 in the SBICS
Acts 12 in the SBIDS
Acts 12 in the SBIGS
Acts 12 in the SBIHS
Acts 12 in the SBIIS
Acts 12 in the SBIIS2
Acts 12 in the SBIIS3
Acts 12 in the SBIKS
Acts 12 in the SBIKS2
Acts 12 in the SBIMS
Acts 12 in the SBIOS
Acts 12 in the SBIPS
Acts 12 in the SBISS
Acts 12 in the SBITS
Acts 12 in the SBITS2
Acts 12 in the SBITS3
Acts 12 in the SBITS4
Acts 12 in the SBIUS
Acts 12 in the SBIVS
Acts 12 in the SBT
Acts 12 in the SBT1E
Acts 12 in the SCHL
Acts 12 in the SNT
Acts 12 in the SUSU
Acts 12 in the SUSU2
Acts 12 in the SYNO
Acts 12 in the TBIAOTANT
Acts 12 in the TBT1E
Acts 12 in the TBT1E2
Acts 12 in the TFTIP
Acts 12 in the TFTU
Acts 12 in the TGNTATF3T
Acts 12 in the THAI
Acts 12 in the TNFD
Acts 12 in the TNT
Acts 12 in the TNTIK
Acts 12 in the TNTIL
Acts 12 in the TNTIN
Acts 12 in the TNTIP
Acts 12 in the TNTIZ
Acts 12 in the TOMA
Acts 12 in the TTENT
Acts 12 in the UBG
Acts 12 in the UGV
Acts 12 in the UGV2
Acts 12 in the UGV3
Acts 12 in the VBL
Acts 12 in the VDCC
Acts 12 in the YALU
Acts 12 in the YAPE
Acts 12 in the YBVTP
Acts 12 in the ZBP