Deuteronomy 16 (BOYCB)
1 Ẹ kíyèsi oṣù Abibu, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti OLÚWA Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Abibu yìí ni ó mú un yín jáde ní Ejibiti lóru. 2 Ẹ fi ẹran kan rú ẹbọ bí ìrékọjá sí OLÚWA Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. 3 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Ejibiti: kí ẹ bá à lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Ejibiti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. 4 Kí a má sì ṣe rí àkàrà wíwú ní ọ̀dọ̀ rẹ nínú ilẹ̀ rẹ ní ijọ́ méje. Kí ìwọ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹ́kù nínú ẹran tí ìwọ ó fi rú ẹbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kejì. 5 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi fún un yín 6 bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 7 Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín. 8 Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún OLÚWA Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 9 Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà. 10 Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí OLÚWA Ọlọ́run yín fún un yín. 11 Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín. 12 Ẹ rántí pé, ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára. 13 Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán. 14 Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín. 15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ̀yin kí ó fi ṣe ayẹyẹ fún OLÚWA Ọlọ́run yín ní ibi tí OLÚWA yóò yàn. Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún. 16 Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ kí ó farahàn níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, ní ibi tí yóò yàn. Níbi àjọ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀sẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú OLÚWA ní ọwọ́ òfo. 17 Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀. 18 Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. 19 Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. 20 Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run yín ń fún un yín. 21 Ẹ má ṣe ri ère òrìṣà Aṣerah sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún OLÚWA Ọlọ́run yín. 22 Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni OLÚWA Ọlọ́run yín kórìíra.
In Other Versions
Deuteronomy 16 in the ANGEFD
Deuteronomy 16 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 16 in the AS21
Deuteronomy 16 in the BAGH
Deuteronomy 16 in the BBPNG
Deuteronomy 16 in the BBT1E
Deuteronomy 16 in the BDS
Deuteronomy 16 in the BEV
Deuteronomy 16 in the BHAD
Deuteronomy 16 in the BIB
Deuteronomy 16 in the BLPT
Deuteronomy 16 in the BNT
Deuteronomy 16 in the BNTABOOT
Deuteronomy 16 in the BNTLV
Deuteronomy 16 in the BOATCB
Deuteronomy 16 in the BOATCB2
Deuteronomy 16 in the BOBCV
Deuteronomy 16 in the BOCNT
Deuteronomy 16 in the BOECS
Deuteronomy 16 in the BOGWICC
Deuteronomy 16 in the BOHCB
Deuteronomy 16 in the BOHCV
Deuteronomy 16 in the BOHLNT
Deuteronomy 16 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 16 in the BOICB
Deuteronomy 16 in the BOILNTAP
Deuteronomy 16 in the BOITCV
Deuteronomy 16 in the BOKCV
Deuteronomy 16 in the BOKCV2
Deuteronomy 16 in the BOKHWOG
Deuteronomy 16 in the BOKSSV
Deuteronomy 16 in the BOLCB
Deuteronomy 16 in the BOLCB2
Deuteronomy 16 in the BOMCV
Deuteronomy 16 in the BONAV
Deuteronomy 16 in the BONCB
Deuteronomy 16 in the BONLT
Deuteronomy 16 in the BONUT2
Deuteronomy 16 in the BOPLNT
Deuteronomy 16 in the BOSCB
Deuteronomy 16 in the BOSNC
Deuteronomy 16 in the BOTLNT
Deuteronomy 16 in the BOVCB
Deuteronomy 16 in the BPBB
Deuteronomy 16 in the BPH
Deuteronomy 16 in the BSB
Deuteronomy 16 in the CCB
Deuteronomy 16 in the CUV
Deuteronomy 16 in the CUVS
Deuteronomy 16 in the DBT
Deuteronomy 16 in the DGDNT
Deuteronomy 16 in the DHNT
Deuteronomy 16 in the DNT
Deuteronomy 16 in the ELBE
Deuteronomy 16 in the EMTV
Deuteronomy 16 in the ESV
Deuteronomy 16 in the FBV
Deuteronomy 16 in the FEB
Deuteronomy 16 in the GGMNT
Deuteronomy 16 in the GNT
Deuteronomy 16 in the HARY
Deuteronomy 16 in the HNT
Deuteronomy 16 in the IRVA
Deuteronomy 16 in the IRVB
Deuteronomy 16 in the IRVG
Deuteronomy 16 in the IRVH
Deuteronomy 16 in the IRVK
Deuteronomy 16 in the IRVM
Deuteronomy 16 in the IRVM2
Deuteronomy 16 in the IRVO
Deuteronomy 16 in the IRVP
Deuteronomy 16 in the IRVT
Deuteronomy 16 in the IRVT2
Deuteronomy 16 in the IRVU
Deuteronomy 16 in the ISVN
Deuteronomy 16 in the JSNT
Deuteronomy 16 in the KAPI
Deuteronomy 16 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 16 in the KBV
Deuteronomy 16 in the KJV
Deuteronomy 16 in the KNFD
Deuteronomy 16 in the LBA
Deuteronomy 16 in the LBLA
Deuteronomy 16 in the LNT
Deuteronomy 16 in the LSV
Deuteronomy 16 in the MAAL
Deuteronomy 16 in the MBV
Deuteronomy 16 in the MBV2
Deuteronomy 16 in the MHNT
Deuteronomy 16 in the MKNFD
Deuteronomy 16 in the MNG
Deuteronomy 16 in the MNT
Deuteronomy 16 in the MNT2
Deuteronomy 16 in the MRS1T
Deuteronomy 16 in the NAA
Deuteronomy 16 in the NASB
Deuteronomy 16 in the NBLA
Deuteronomy 16 in the NBS
Deuteronomy 16 in the NBVTP
Deuteronomy 16 in the NET2
Deuteronomy 16 in the NIV11
Deuteronomy 16 in the NNT
Deuteronomy 16 in the NNT2
Deuteronomy 16 in the NNT3
Deuteronomy 16 in the PDDPT
Deuteronomy 16 in the PFNT
Deuteronomy 16 in the RMNT
Deuteronomy 16 in the SBIAS
Deuteronomy 16 in the SBIBS
Deuteronomy 16 in the SBIBS2
Deuteronomy 16 in the SBICS
Deuteronomy 16 in the SBIDS
Deuteronomy 16 in the SBIGS
Deuteronomy 16 in the SBIHS
Deuteronomy 16 in the SBIIS
Deuteronomy 16 in the SBIIS2
Deuteronomy 16 in the SBIIS3
Deuteronomy 16 in the SBIKS
Deuteronomy 16 in the SBIKS2
Deuteronomy 16 in the SBIMS
Deuteronomy 16 in the SBIOS
Deuteronomy 16 in the SBIPS
Deuteronomy 16 in the SBISS
Deuteronomy 16 in the SBITS
Deuteronomy 16 in the SBITS2
Deuteronomy 16 in the SBITS3
Deuteronomy 16 in the SBITS4
Deuteronomy 16 in the SBIUS
Deuteronomy 16 in the SBIVS
Deuteronomy 16 in the SBT
Deuteronomy 16 in the SBT1E
Deuteronomy 16 in the SCHL
Deuteronomy 16 in the SNT
Deuteronomy 16 in the SUSU
Deuteronomy 16 in the SUSU2
Deuteronomy 16 in the SYNO
Deuteronomy 16 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 16 in the TBT1E
Deuteronomy 16 in the TBT1E2
Deuteronomy 16 in the TFTIP
Deuteronomy 16 in the TFTU
Deuteronomy 16 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 16 in the THAI
Deuteronomy 16 in the TNFD
Deuteronomy 16 in the TNT
Deuteronomy 16 in the TNTIK
Deuteronomy 16 in the TNTIL
Deuteronomy 16 in the TNTIN
Deuteronomy 16 in the TNTIP
Deuteronomy 16 in the TNTIZ
Deuteronomy 16 in the TOMA
Deuteronomy 16 in the TTENT
Deuteronomy 16 in the UBG
Deuteronomy 16 in the UGV
Deuteronomy 16 in the UGV2
Deuteronomy 16 in the UGV3
Deuteronomy 16 in the VBL
Deuteronomy 16 in the VDCC
Deuteronomy 16 in the YALU
Deuteronomy 16 in the YAPE
Deuteronomy 16 in the YBVTP
Deuteronomy 16 in the ZBP