Deuteronomy 17 (BOYCB)
1 Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un. 2 Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí OLÚWA fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá, 3 èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, 4 tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli. 5 Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa. 6 Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. 7 Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín. 8 Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn. 9 Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́. 10 Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí OLÚWA yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ. 11 Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín. 12 Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli. 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́. 14 Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.” 15 Ẹ rí i dájú pé ọba tí OLÚWA Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjèjì jẹ ọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Israẹli. 16 Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé OLÚWA ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.” 17 Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 18 Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. 19 Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn. 20 Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.
In Other Versions
Deuteronomy 17 in the ANGEFD
Deuteronomy 17 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 17 in the AS21
Deuteronomy 17 in the BAGH
Deuteronomy 17 in the BBPNG
Deuteronomy 17 in the BBT1E
Deuteronomy 17 in the BDS
Deuteronomy 17 in the BEV
Deuteronomy 17 in the BHAD
Deuteronomy 17 in the BIB
Deuteronomy 17 in the BLPT
Deuteronomy 17 in the BNT
Deuteronomy 17 in the BNTABOOT
Deuteronomy 17 in the BNTLV
Deuteronomy 17 in the BOATCB
Deuteronomy 17 in the BOATCB2
Deuteronomy 17 in the BOBCV
Deuteronomy 17 in the BOCNT
Deuteronomy 17 in the BOECS
Deuteronomy 17 in the BOGWICC
Deuteronomy 17 in the BOHCB
Deuteronomy 17 in the BOHCV
Deuteronomy 17 in the BOHLNT
Deuteronomy 17 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 17 in the BOICB
Deuteronomy 17 in the BOILNTAP
Deuteronomy 17 in the BOITCV
Deuteronomy 17 in the BOKCV
Deuteronomy 17 in the BOKCV2
Deuteronomy 17 in the BOKHWOG
Deuteronomy 17 in the BOKSSV
Deuteronomy 17 in the BOLCB
Deuteronomy 17 in the BOLCB2
Deuteronomy 17 in the BOMCV
Deuteronomy 17 in the BONAV
Deuteronomy 17 in the BONCB
Deuteronomy 17 in the BONLT
Deuteronomy 17 in the BONUT2
Deuteronomy 17 in the BOPLNT
Deuteronomy 17 in the BOSCB
Deuteronomy 17 in the BOSNC
Deuteronomy 17 in the BOTLNT
Deuteronomy 17 in the BOVCB
Deuteronomy 17 in the BPBB
Deuteronomy 17 in the BPH
Deuteronomy 17 in the BSB
Deuteronomy 17 in the CCB
Deuteronomy 17 in the CUV
Deuteronomy 17 in the CUVS
Deuteronomy 17 in the DBT
Deuteronomy 17 in the DGDNT
Deuteronomy 17 in the DHNT
Deuteronomy 17 in the DNT
Deuteronomy 17 in the ELBE
Deuteronomy 17 in the EMTV
Deuteronomy 17 in the ESV
Deuteronomy 17 in the FBV
Deuteronomy 17 in the FEB
Deuteronomy 17 in the GGMNT
Deuteronomy 17 in the GNT
Deuteronomy 17 in the HARY
Deuteronomy 17 in the HNT
Deuteronomy 17 in the IRVA
Deuteronomy 17 in the IRVB
Deuteronomy 17 in the IRVG
Deuteronomy 17 in the IRVH
Deuteronomy 17 in the IRVK
Deuteronomy 17 in the IRVM
Deuteronomy 17 in the IRVM2
Deuteronomy 17 in the IRVO
Deuteronomy 17 in the IRVP
Deuteronomy 17 in the IRVT
Deuteronomy 17 in the IRVT2
Deuteronomy 17 in the IRVU
Deuteronomy 17 in the ISVN
Deuteronomy 17 in the JSNT
Deuteronomy 17 in the KAPI
Deuteronomy 17 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 17 in the KBV
Deuteronomy 17 in the KJV
Deuteronomy 17 in the KNFD
Deuteronomy 17 in the LBA
Deuteronomy 17 in the LBLA
Deuteronomy 17 in the LNT
Deuteronomy 17 in the LSV
Deuteronomy 17 in the MAAL
Deuteronomy 17 in the MBV
Deuteronomy 17 in the MBV2
Deuteronomy 17 in the MHNT
Deuteronomy 17 in the MKNFD
Deuteronomy 17 in the MNG
Deuteronomy 17 in the MNT
Deuteronomy 17 in the MNT2
Deuteronomy 17 in the MRS1T
Deuteronomy 17 in the NAA
Deuteronomy 17 in the NASB
Deuteronomy 17 in the NBLA
Deuteronomy 17 in the NBS
Deuteronomy 17 in the NBVTP
Deuteronomy 17 in the NET2
Deuteronomy 17 in the NIV11
Deuteronomy 17 in the NNT
Deuteronomy 17 in the NNT2
Deuteronomy 17 in the NNT3
Deuteronomy 17 in the PDDPT
Deuteronomy 17 in the PFNT
Deuteronomy 17 in the RMNT
Deuteronomy 17 in the SBIAS
Deuteronomy 17 in the SBIBS
Deuteronomy 17 in the SBIBS2
Deuteronomy 17 in the SBICS
Deuteronomy 17 in the SBIDS
Deuteronomy 17 in the SBIGS
Deuteronomy 17 in the SBIHS
Deuteronomy 17 in the SBIIS
Deuteronomy 17 in the SBIIS2
Deuteronomy 17 in the SBIIS3
Deuteronomy 17 in the SBIKS
Deuteronomy 17 in the SBIKS2
Deuteronomy 17 in the SBIMS
Deuteronomy 17 in the SBIOS
Deuteronomy 17 in the SBIPS
Deuteronomy 17 in the SBISS
Deuteronomy 17 in the SBITS
Deuteronomy 17 in the SBITS2
Deuteronomy 17 in the SBITS3
Deuteronomy 17 in the SBITS4
Deuteronomy 17 in the SBIUS
Deuteronomy 17 in the SBIVS
Deuteronomy 17 in the SBT
Deuteronomy 17 in the SBT1E
Deuteronomy 17 in the SCHL
Deuteronomy 17 in the SNT
Deuteronomy 17 in the SUSU
Deuteronomy 17 in the SUSU2
Deuteronomy 17 in the SYNO
Deuteronomy 17 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 17 in the TBT1E
Deuteronomy 17 in the TBT1E2
Deuteronomy 17 in the TFTIP
Deuteronomy 17 in the TFTU
Deuteronomy 17 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 17 in the THAI
Deuteronomy 17 in the TNFD
Deuteronomy 17 in the TNT
Deuteronomy 17 in the TNTIK
Deuteronomy 17 in the TNTIL
Deuteronomy 17 in the TNTIN
Deuteronomy 17 in the TNTIP
Deuteronomy 17 in the TNTIZ
Deuteronomy 17 in the TOMA
Deuteronomy 17 in the TTENT
Deuteronomy 17 in the UBG
Deuteronomy 17 in the UGV
Deuteronomy 17 in the UGV2
Deuteronomy 17 in the UGV3
Deuteronomy 17 in the VBL
Deuteronomy 17 in the VDCC
Deuteronomy 17 in the YALU
Deuteronomy 17 in the YAPE
Deuteronomy 17 in the YBVTP
Deuteronomy 17 in the ZBP