Deuteronomy 23 (BOYCB)
1 Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ OLÚWA wá. 2 Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ OLÚWA, pàápàá títí dé ìran kẹwàá. 3 Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ OLÚWA, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn OLÚWA láéláé. 4 Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Ejibiti àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégùn ún Balaamu ọmọ Beori ará a Petori ti Aramu-Naharaimu. 5 Síbẹ̀síbẹ̀, OLÚWA Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ. 6 Ìwọ kò gbọdọ̀ wá àlàáfíà, tàbí ire wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láààyè. 7 Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Edomu kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra ará Ejibiti, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀. 8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ OLÚWA. 9 Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀tá rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò. 10 Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́. 11 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́. 12 Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára. 13 Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ. 14 Nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín. 15 Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. 16 Jẹ́ kí ó máa gbé láàrín rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyìí ìlú tí ó bá mú. Má ṣe ni í lára. 17 Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Israẹli má ṣe padà di alágbèrè ojúbọ òrìṣà. 18 Ìwọ kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé OLÚWA Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ kórìíra àwọn méjèèjì. 19 Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá. 20 Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní. 21 Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 22 Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi. 23 Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ. 24 Bí ìwọ bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi nǹkan kan sínú agbọ̀n rẹ. 25 Bí ìwọ bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya síírí rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.
In Other Versions
Deuteronomy 23 in the ANGEFD
Deuteronomy 23 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 23 in the AS21
Deuteronomy 23 in the BAGH
Deuteronomy 23 in the BBPNG
Deuteronomy 23 in the BBT1E
Deuteronomy 23 in the BDS
Deuteronomy 23 in the BEV
Deuteronomy 23 in the BHAD
Deuteronomy 23 in the BIB
Deuteronomy 23 in the BLPT
Deuteronomy 23 in the BNT
Deuteronomy 23 in the BNTABOOT
Deuteronomy 23 in the BNTLV
Deuteronomy 23 in the BOATCB
Deuteronomy 23 in the BOATCB2
Deuteronomy 23 in the BOBCV
Deuteronomy 23 in the BOCNT
Deuteronomy 23 in the BOECS
Deuteronomy 23 in the BOGWICC
Deuteronomy 23 in the BOHCB
Deuteronomy 23 in the BOHCV
Deuteronomy 23 in the BOHLNT
Deuteronomy 23 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 23 in the BOICB
Deuteronomy 23 in the BOILNTAP
Deuteronomy 23 in the BOITCV
Deuteronomy 23 in the BOKCV
Deuteronomy 23 in the BOKCV2
Deuteronomy 23 in the BOKHWOG
Deuteronomy 23 in the BOKSSV
Deuteronomy 23 in the BOLCB
Deuteronomy 23 in the BOLCB2
Deuteronomy 23 in the BOMCV
Deuteronomy 23 in the BONAV
Deuteronomy 23 in the BONCB
Deuteronomy 23 in the BONLT
Deuteronomy 23 in the BONUT2
Deuteronomy 23 in the BOPLNT
Deuteronomy 23 in the BOSCB
Deuteronomy 23 in the BOSNC
Deuteronomy 23 in the BOTLNT
Deuteronomy 23 in the BOVCB
Deuteronomy 23 in the BPBB
Deuteronomy 23 in the BPH
Deuteronomy 23 in the BSB
Deuteronomy 23 in the CCB
Deuteronomy 23 in the CUV
Deuteronomy 23 in the CUVS
Deuteronomy 23 in the DBT
Deuteronomy 23 in the DGDNT
Deuteronomy 23 in the DHNT
Deuteronomy 23 in the DNT
Deuteronomy 23 in the ELBE
Deuteronomy 23 in the EMTV
Deuteronomy 23 in the ESV
Deuteronomy 23 in the FBV
Deuteronomy 23 in the FEB
Deuteronomy 23 in the GGMNT
Deuteronomy 23 in the GNT
Deuteronomy 23 in the HARY
Deuteronomy 23 in the HNT
Deuteronomy 23 in the IRVA
Deuteronomy 23 in the IRVB
Deuteronomy 23 in the IRVG
Deuteronomy 23 in the IRVH
Deuteronomy 23 in the IRVK
Deuteronomy 23 in the IRVM
Deuteronomy 23 in the IRVM2
Deuteronomy 23 in the IRVO
Deuteronomy 23 in the IRVP
Deuteronomy 23 in the IRVT
Deuteronomy 23 in the IRVT2
Deuteronomy 23 in the IRVU
Deuteronomy 23 in the ISVN
Deuteronomy 23 in the JSNT
Deuteronomy 23 in the KAPI
Deuteronomy 23 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 23 in the KBV
Deuteronomy 23 in the KJV
Deuteronomy 23 in the KNFD
Deuteronomy 23 in the LBA
Deuteronomy 23 in the LBLA
Deuteronomy 23 in the LNT
Deuteronomy 23 in the LSV
Deuteronomy 23 in the MAAL
Deuteronomy 23 in the MBV
Deuteronomy 23 in the MBV2
Deuteronomy 23 in the MHNT
Deuteronomy 23 in the MKNFD
Deuteronomy 23 in the MNG
Deuteronomy 23 in the MNT
Deuteronomy 23 in the MNT2
Deuteronomy 23 in the MRS1T
Deuteronomy 23 in the NAA
Deuteronomy 23 in the NASB
Deuteronomy 23 in the NBLA
Deuteronomy 23 in the NBS
Deuteronomy 23 in the NBVTP
Deuteronomy 23 in the NET2
Deuteronomy 23 in the NIV11
Deuteronomy 23 in the NNT
Deuteronomy 23 in the NNT2
Deuteronomy 23 in the NNT3
Deuteronomy 23 in the PDDPT
Deuteronomy 23 in the PFNT
Deuteronomy 23 in the RMNT
Deuteronomy 23 in the SBIAS
Deuteronomy 23 in the SBIBS
Deuteronomy 23 in the SBIBS2
Deuteronomy 23 in the SBICS
Deuteronomy 23 in the SBIDS
Deuteronomy 23 in the SBIGS
Deuteronomy 23 in the SBIHS
Deuteronomy 23 in the SBIIS
Deuteronomy 23 in the SBIIS2
Deuteronomy 23 in the SBIIS3
Deuteronomy 23 in the SBIKS
Deuteronomy 23 in the SBIKS2
Deuteronomy 23 in the SBIMS
Deuteronomy 23 in the SBIOS
Deuteronomy 23 in the SBIPS
Deuteronomy 23 in the SBISS
Deuteronomy 23 in the SBITS
Deuteronomy 23 in the SBITS2
Deuteronomy 23 in the SBITS3
Deuteronomy 23 in the SBITS4
Deuteronomy 23 in the SBIUS
Deuteronomy 23 in the SBIVS
Deuteronomy 23 in the SBT
Deuteronomy 23 in the SBT1E
Deuteronomy 23 in the SCHL
Deuteronomy 23 in the SNT
Deuteronomy 23 in the SUSU
Deuteronomy 23 in the SUSU2
Deuteronomy 23 in the SYNO
Deuteronomy 23 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 23 in the TBT1E
Deuteronomy 23 in the TBT1E2
Deuteronomy 23 in the TFTIP
Deuteronomy 23 in the TFTU
Deuteronomy 23 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 23 in the THAI
Deuteronomy 23 in the TNFD
Deuteronomy 23 in the TNT
Deuteronomy 23 in the TNTIK
Deuteronomy 23 in the TNTIL
Deuteronomy 23 in the TNTIN
Deuteronomy 23 in the TNTIP
Deuteronomy 23 in the TNTIZ
Deuteronomy 23 in the TOMA
Deuteronomy 23 in the TTENT
Deuteronomy 23 in the UBG
Deuteronomy 23 in the UGV
Deuteronomy 23 in the UGV2
Deuteronomy 23 in the UGV3
Deuteronomy 23 in the VBL
Deuteronomy 23 in the VDCC
Deuteronomy 23 in the YALU
Deuteronomy 23 in the YAPE
Deuteronomy 23 in the YBVTP
Deuteronomy 23 in the ZBP