Deuteronomy 27 (BOYCB)
        
        
          1 Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́. 2 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. 3 Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. 4 Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. 5 Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. 6 Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ. 7 Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ. 8 Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”  9 Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn OLÚWA Ọlọ́run rẹ báyìí. 10 Gbọ́rọ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”  11 Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.  12 Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.  14 Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:   15 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú OLÚWA, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  16 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  17 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  18 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  19 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  20 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  21 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  23 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”  26 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
        
        
          In Other Versions
        
        
  
    Deuteronomy 27 in the ANGEFD
  
  
    Deuteronomy 27 in the ANTPNG2D
  
  
    Deuteronomy 27 in the AS21
  
  
    Deuteronomy 27 in the BAGH
  
  
    Deuteronomy 27 in the BBPNG
  
  
    Deuteronomy 27 in the BBT1E
  
  
    Deuteronomy 27 in the BDS
  
  
    Deuteronomy 27 in the BEV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BHAD
  
  
    Deuteronomy 27 in the BIB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BLPT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BNTABOOT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BNTLV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOATCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOATCB2
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOBCV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOCNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOECS
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOGWICC
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOHCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOHCV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOHLNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOHNTLTAL
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOICB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOILNTAP
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOITCV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOKCV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOKCV2
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOKHWOG
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOKSSV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOLCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOLCB2
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOMCV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BONAV
  
  
    Deuteronomy 27 in the BONCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BONLT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BONUT2
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOPLNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOSCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOSNC
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOTLNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the BOVCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BPBB
  
  
    Deuteronomy 27 in the BPH
  
  
    Deuteronomy 27 in the BSB
  
  
    Deuteronomy 27 in the CCB
  
  
    Deuteronomy 27 in the CUV
  
  
    Deuteronomy 27 in the CUVS
  
  
    Deuteronomy 27 in the DBT
  
  
    Deuteronomy 27 in the DGDNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the DHNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the DNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the ELBE
  
  
    Deuteronomy 27 in the EMTV
  
  
    Deuteronomy 27 in the ESV
  
  
    Deuteronomy 27 in the FBV
  
  
    Deuteronomy 27 in the FEB
  
  
    Deuteronomy 27 in the GGMNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the GNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the HARY
  
  
    Deuteronomy 27 in the HNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVA
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVB
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVG
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVH
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVK
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVM
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVM2
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVO
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVP
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVT
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVT2
  
  
    Deuteronomy 27 in the IRVU
  
  
    Deuteronomy 27 in the ISVN
  
  
    Deuteronomy 27 in the JSNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the KAPI
  
  
    Deuteronomy 27 in the KBT1ETNIK
  
  
    Deuteronomy 27 in the KBV
  
  
    Deuteronomy 27 in the KJV
  
  
    Deuteronomy 27 in the KNFD
  
  
    Deuteronomy 27 in the LBA
  
  
    Deuteronomy 27 in the LBLA
  
  
    Deuteronomy 27 in the LNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the LSV
  
  
    Deuteronomy 27 in the MAAL
  
  
    Deuteronomy 27 in the MBV
  
  
    Deuteronomy 27 in the MBV2
  
  
    Deuteronomy 27 in the MHNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the MKNFD
  
  
    Deuteronomy 27 in the MNG
  
  
    Deuteronomy 27 in the MNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the MNT2
  
  
    Deuteronomy 27 in the MRS1T
  
  
    Deuteronomy 27 in the NAA
  
  
    Deuteronomy 27 in the NASB
  
  
    Deuteronomy 27 in the NBLA
  
  
    Deuteronomy 27 in the NBS
  
  
    Deuteronomy 27 in the NBVTP
  
  
    Deuteronomy 27 in the NET2
  
  
    Deuteronomy 27 in the NIV11
  
  
    Deuteronomy 27 in the NNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the NNT2
  
  
    Deuteronomy 27 in the NNT3
  
  
    Deuteronomy 27 in the PDDPT
  
  
    Deuteronomy 27 in the PFNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the RMNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIAS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIBS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIBS2
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBICS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIDS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIGS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIHS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIIS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIIS2
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIIS3
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIKS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIKS2
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIMS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIOS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIPS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBISS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBITS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBITS2
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBITS3
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBITS4
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIUS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBIVS
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBT
  
  
    Deuteronomy 27 in the SBT1E
  
  
    Deuteronomy 27 in the SCHL
  
  
    Deuteronomy 27 in the SNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the SUSU
  
  
    Deuteronomy 27 in the SUSU2
  
  
    Deuteronomy 27 in the SYNO
  
  
    Deuteronomy 27 in the TBIAOTANT
  
  
    Deuteronomy 27 in the TBT1E
  
  
    Deuteronomy 27 in the TBT1E2
  
  
    Deuteronomy 27 in the TFTIP
  
  
    Deuteronomy 27 in the TFTU
  
  
    Deuteronomy 27 in the TGNTATF3T
  
  
    Deuteronomy 27 in the THAI
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNFD
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNT
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNTIK
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNTIL
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNTIN
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNTIP
  
  
    Deuteronomy 27 in the TNTIZ
  
  
    Deuteronomy 27 in the TOMA
  
  
    Deuteronomy 27 in the TTENT
  
  
    Deuteronomy 27 in the UBG
  
  
    Deuteronomy 27 in the UGV
  
  
    Deuteronomy 27 in the UGV2
  
  
    Deuteronomy 27 in the UGV3
  
  
    Deuteronomy 27 in the VBL
  
  
    Deuteronomy 27 in the VDCC
  
  
    Deuteronomy 27 in the YALU
  
  
    Deuteronomy 27 in the YAPE
  
  
    Deuteronomy 27 in the YBVTP
  
  
    Deuteronomy 27 in the ZBP