Deuteronomy 30 (BOYCB)

1 Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, 2 àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí. 3 Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí. 4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà. 5 Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. OLÚWA yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ. 6 OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ. 7 OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ. 8 Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí OLÚWA àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí. 9 Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. OLÚWA yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ. 10 Bí o bá gbọ́ ti OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ. 11 Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ. 12 Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?” 13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì Òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?” 14 Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí rẹ, ó wà ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é. 15 Wò ó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun. 16 Ní èyí tí mo pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè yè, kí ó sì máa bí sí i, kí OLÚWA Ọlọ́run lè bù si fún ọ ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ìwọ ń lọ láti gbà á. 17 Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, 18 èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní. 19 Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ, 20 kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí OLÚWA ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

In Other Versions

Deuteronomy 30 in the ANGEFD

Deuteronomy 30 in the ANTPNG2D

Deuteronomy 30 in the AS21

Deuteronomy 30 in the BAGH

Deuteronomy 30 in the BBPNG

Deuteronomy 30 in the BBT1E

Deuteronomy 30 in the BDS

Deuteronomy 30 in the BEV

Deuteronomy 30 in the BHAD

Deuteronomy 30 in the BIB

Deuteronomy 30 in the BLPT

Deuteronomy 30 in the BNT

Deuteronomy 30 in the BNTABOOT

Deuteronomy 30 in the BNTLV

Deuteronomy 30 in the BOATCB

Deuteronomy 30 in the BOATCB2

Deuteronomy 30 in the BOBCV

Deuteronomy 30 in the BOCNT

Deuteronomy 30 in the BOECS

Deuteronomy 30 in the BOGWICC

Deuteronomy 30 in the BOHCB

Deuteronomy 30 in the BOHCV

Deuteronomy 30 in the BOHLNT

Deuteronomy 30 in the BOHNTLTAL

Deuteronomy 30 in the BOICB

Deuteronomy 30 in the BOILNTAP

Deuteronomy 30 in the BOITCV

Deuteronomy 30 in the BOKCV

Deuteronomy 30 in the BOKCV2

Deuteronomy 30 in the BOKHWOG

Deuteronomy 30 in the BOKSSV

Deuteronomy 30 in the BOLCB

Deuteronomy 30 in the BOLCB2

Deuteronomy 30 in the BOMCV

Deuteronomy 30 in the BONAV

Deuteronomy 30 in the BONCB

Deuteronomy 30 in the BONLT

Deuteronomy 30 in the BONUT2

Deuteronomy 30 in the BOPLNT

Deuteronomy 30 in the BOSCB

Deuteronomy 30 in the BOSNC

Deuteronomy 30 in the BOTLNT

Deuteronomy 30 in the BOVCB

Deuteronomy 30 in the BPBB

Deuteronomy 30 in the BPH

Deuteronomy 30 in the BSB

Deuteronomy 30 in the CCB

Deuteronomy 30 in the CUV

Deuteronomy 30 in the CUVS

Deuteronomy 30 in the DBT

Deuteronomy 30 in the DGDNT

Deuteronomy 30 in the DHNT

Deuteronomy 30 in the DNT

Deuteronomy 30 in the ELBE

Deuteronomy 30 in the EMTV

Deuteronomy 30 in the ESV

Deuteronomy 30 in the FBV

Deuteronomy 30 in the FEB

Deuteronomy 30 in the GGMNT

Deuteronomy 30 in the GNT

Deuteronomy 30 in the HARY

Deuteronomy 30 in the HNT

Deuteronomy 30 in the IRVA

Deuteronomy 30 in the IRVB

Deuteronomy 30 in the IRVG

Deuteronomy 30 in the IRVH

Deuteronomy 30 in the IRVK

Deuteronomy 30 in the IRVM

Deuteronomy 30 in the IRVM2

Deuteronomy 30 in the IRVO

Deuteronomy 30 in the IRVP

Deuteronomy 30 in the IRVT

Deuteronomy 30 in the IRVT2

Deuteronomy 30 in the IRVU

Deuteronomy 30 in the ISVN

Deuteronomy 30 in the JSNT

Deuteronomy 30 in the KAPI

Deuteronomy 30 in the KBT1ETNIK

Deuteronomy 30 in the KBV

Deuteronomy 30 in the KJV

Deuteronomy 30 in the KNFD

Deuteronomy 30 in the LBA

Deuteronomy 30 in the LBLA

Deuteronomy 30 in the LNT

Deuteronomy 30 in the LSV

Deuteronomy 30 in the MAAL

Deuteronomy 30 in the MBV

Deuteronomy 30 in the MBV2

Deuteronomy 30 in the MHNT

Deuteronomy 30 in the MKNFD

Deuteronomy 30 in the MNG

Deuteronomy 30 in the MNT

Deuteronomy 30 in the MNT2

Deuteronomy 30 in the MRS1T

Deuteronomy 30 in the NAA

Deuteronomy 30 in the NASB

Deuteronomy 30 in the NBLA

Deuteronomy 30 in the NBS

Deuteronomy 30 in the NBVTP

Deuteronomy 30 in the NET2

Deuteronomy 30 in the NIV11

Deuteronomy 30 in the NNT

Deuteronomy 30 in the NNT2

Deuteronomy 30 in the NNT3

Deuteronomy 30 in the PDDPT

Deuteronomy 30 in the PFNT

Deuteronomy 30 in the RMNT

Deuteronomy 30 in the SBIAS

Deuteronomy 30 in the SBIBS

Deuteronomy 30 in the SBIBS2

Deuteronomy 30 in the SBICS

Deuteronomy 30 in the SBIDS

Deuteronomy 30 in the SBIGS

Deuteronomy 30 in the SBIHS

Deuteronomy 30 in the SBIIS

Deuteronomy 30 in the SBIIS2

Deuteronomy 30 in the SBIIS3

Deuteronomy 30 in the SBIKS

Deuteronomy 30 in the SBIKS2

Deuteronomy 30 in the SBIMS

Deuteronomy 30 in the SBIOS

Deuteronomy 30 in the SBIPS

Deuteronomy 30 in the SBISS

Deuteronomy 30 in the SBITS

Deuteronomy 30 in the SBITS2

Deuteronomy 30 in the SBITS3

Deuteronomy 30 in the SBITS4

Deuteronomy 30 in the SBIUS

Deuteronomy 30 in the SBIVS

Deuteronomy 30 in the SBT

Deuteronomy 30 in the SBT1E

Deuteronomy 30 in the SCHL

Deuteronomy 30 in the SNT

Deuteronomy 30 in the SUSU

Deuteronomy 30 in the SUSU2

Deuteronomy 30 in the SYNO

Deuteronomy 30 in the TBIAOTANT

Deuteronomy 30 in the TBT1E

Deuteronomy 30 in the TBT1E2

Deuteronomy 30 in the TFTIP

Deuteronomy 30 in the TFTU

Deuteronomy 30 in the TGNTATF3T

Deuteronomy 30 in the THAI

Deuteronomy 30 in the TNFD

Deuteronomy 30 in the TNT

Deuteronomy 30 in the TNTIK

Deuteronomy 30 in the TNTIL

Deuteronomy 30 in the TNTIN

Deuteronomy 30 in the TNTIP

Deuteronomy 30 in the TNTIZ

Deuteronomy 30 in the TOMA

Deuteronomy 30 in the TTENT

Deuteronomy 30 in the UBG

Deuteronomy 30 in the UGV

Deuteronomy 30 in the UGV2

Deuteronomy 30 in the UGV3

Deuteronomy 30 in the VBL

Deuteronomy 30 in the VDCC

Deuteronomy 30 in the YALU

Deuteronomy 30 in the YAPE

Deuteronomy 30 in the YBVTP

Deuteronomy 30 in the ZBP