Deuteronomy 8 (BOYCB)
1 Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí OLÚWA fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 2 Ẹ rántí bí OLÚWA Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 3 Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu OLÚWA wá. 4 Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. 5 Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. 6 Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. 7 Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8 Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. 9 Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá. 10 Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin OLÚWA Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín. 11 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 12 Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, 13 nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, 14 nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. 15 Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta. 16 Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. 17 Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” 18 Ṣùgbọ́n ẹ rántí OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí. 19 Bí ẹ bá wá gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ̀yin yóò run. 20 Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLÚWA parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín lẹ́nu.
In Other Versions
Deuteronomy 8 in the ANGEFD
Deuteronomy 8 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 8 in the AS21
Deuteronomy 8 in the BAGH
Deuteronomy 8 in the BBPNG
Deuteronomy 8 in the BBT1E
Deuteronomy 8 in the BDS
Deuteronomy 8 in the BEV
Deuteronomy 8 in the BHAD
Deuteronomy 8 in the BIB
Deuteronomy 8 in the BLPT
Deuteronomy 8 in the BNT
Deuteronomy 8 in the BNTABOOT
Deuteronomy 8 in the BNTLV
Deuteronomy 8 in the BOATCB
Deuteronomy 8 in the BOATCB2
Deuteronomy 8 in the BOBCV
Deuteronomy 8 in the BOCNT
Deuteronomy 8 in the BOECS
Deuteronomy 8 in the BOGWICC
Deuteronomy 8 in the BOHCB
Deuteronomy 8 in the BOHCV
Deuteronomy 8 in the BOHLNT
Deuteronomy 8 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 8 in the BOICB
Deuteronomy 8 in the BOILNTAP
Deuteronomy 8 in the BOITCV
Deuteronomy 8 in the BOKCV
Deuteronomy 8 in the BOKCV2
Deuteronomy 8 in the BOKHWOG
Deuteronomy 8 in the BOKSSV
Deuteronomy 8 in the BOLCB
Deuteronomy 8 in the BOLCB2
Deuteronomy 8 in the BOMCV
Deuteronomy 8 in the BONAV
Deuteronomy 8 in the BONCB
Deuteronomy 8 in the BONLT
Deuteronomy 8 in the BONUT2
Deuteronomy 8 in the BOPLNT
Deuteronomy 8 in the BOSCB
Deuteronomy 8 in the BOSNC
Deuteronomy 8 in the BOTLNT
Deuteronomy 8 in the BOVCB
Deuteronomy 8 in the BPBB
Deuteronomy 8 in the BPH
Deuteronomy 8 in the BSB
Deuteronomy 8 in the CCB
Deuteronomy 8 in the CUV
Deuteronomy 8 in the CUVS
Deuteronomy 8 in the DBT
Deuteronomy 8 in the DGDNT
Deuteronomy 8 in the DHNT
Deuteronomy 8 in the DNT
Deuteronomy 8 in the ELBE
Deuteronomy 8 in the EMTV
Deuteronomy 8 in the ESV
Deuteronomy 8 in the FBV
Deuteronomy 8 in the FEB
Deuteronomy 8 in the GGMNT
Deuteronomy 8 in the GNT
Deuteronomy 8 in the HARY
Deuteronomy 8 in the HNT
Deuteronomy 8 in the IRVA
Deuteronomy 8 in the IRVB
Deuteronomy 8 in the IRVG
Deuteronomy 8 in the IRVH
Deuteronomy 8 in the IRVK
Deuteronomy 8 in the IRVM
Deuteronomy 8 in the IRVM2
Deuteronomy 8 in the IRVO
Deuteronomy 8 in the IRVP
Deuteronomy 8 in the IRVT
Deuteronomy 8 in the IRVT2
Deuteronomy 8 in the IRVU
Deuteronomy 8 in the ISVN
Deuteronomy 8 in the JSNT
Deuteronomy 8 in the KAPI
Deuteronomy 8 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 8 in the KBV
Deuteronomy 8 in the KJV
Deuteronomy 8 in the KNFD
Deuteronomy 8 in the LBA
Deuteronomy 8 in the LBLA
Deuteronomy 8 in the LNT
Deuteronomy 8 in the LSV
Deuteronomy 8 in the MAAL
Deuteronomy 8 in the MBV
Deuteronomy 8 in the MBV2
Deuteronomy 8 in the MHNT
Deuteronomy 8 in the MKNFD
Deuteronomy 8 in the MNG
Deuteronomy 8 in the MNT
Deuteronomy 8 in the MNT2
Deuteronomy 8 in the MRS1T
Deuteronomy 8 in the NAA
Deuteronomy 8 in the NASB
Deuteronomy 8 in the NBLA
Deuteronomy 8 in the NBS
Deuteronomy 8 in the NBVTP
Deuteronomy 8 in the NET2
Deuteronomy 8 in the NIV11
Deuteronomy 8 in the NNT
Deuteronomy 8 in the NNT2
Deuteronomy 8 in the NNT3
Deuteronomy 8 in the PDDPT
Deuteronomy 8 in the PFNT
Deuteronomy 8 in the RMNT
Deuteronomy 8 in the SBIAS
Deuteronomy 8 in the SBIBS
Deuteronomy 8 in the SBIBS2
Deuteronomy 8 in the SBICS
Deuteronomy 8 in the SBIDS
Deuteronomy 8 in the SBIGS
Deuteronomy 8 in the SBIHS
Deuteronomy 8 in the SBIIS
Deuteronomy 8 in the SBIIS2
Deuteronomy 8 in the SBIIS3
Deuteronomy 8 in the SBIKS
Deuteronomy 8 in the SBIKS2
Deuteronomy 8 in the SBIMS
Deuteronomy 8 in the SBIOS
Deuteronomy 8 in the SBIPS
Deuteronomy 8 in the SBISS
Deuteronomy 8 in the SBITS
Deuteronomy 8 in the SBITS2
Deuteronomy 8 in the SBITS3
Deuteronomy 8 in the SBITS4
Deuteronomy 8 in the SBIUS
Deuteronomy 8 in the SBIVS
Deuteronomy 8 in the SBT
Deuteronomy 8 in the SBT1E
Deuteronomy 8 in the SCHL
Deuteronomy 8 in the SNT
Deuteronomy 8 in the SUSU
Deuteronomy 8 in the SUSU2
Deuteronomy 8 in the SYNO
Deuteronomy 8 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 8 in the TBT1E
Deuteronomy 8 in the TBT1E2
Deuteronomy 8 in the TFTIP
Deuteronomy 8 in the TFTU
Deuteronomy 8 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 8 in the THAI
Deuteronomy 8 in the TNFD
Deuteronomy 8 in the TNT
Deuteronomy 8 in the TNTIK
Deuteronomy 8 in the TNTIL
Deuteronomy 8 in the TNTIN
Deuteronomy 8 in the TNTIP
Deuteronomy 8 in the TNTIZ
Deuteronomy 8 in the TOMA
Deuteronomy 8 in the TTENT
Deuteronomy 8 in the UBG
Deuteronomy 8 in the UGV
Deuteronomy 8 in the UGV2
Deuteronomy 8 in the UGV3
Deuteronomy 8 in the VBL
Deuteronomy 8 in the VDCC
Deuteronomy 8 in the YALU
Deuteronomy 8 in the YAPE
Deuteronomy 8 in the YBVTP
Deuteronomy 8 in the ZBP