Ecclesiastes 9 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. 2 Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rerebẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúrabẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra. 3 Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. 4 Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ! 5 Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kúṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kanwọn kò ní èrè kankan mọ́,àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé. 6 Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn,àti ìlara wọn ti parẹ́:láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpínnínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. 7 Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe. 8 Máa wọ aṣọ funfun nígbàkígbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. 9 Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ. 11 Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn.Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yáratàbí ogun fún alágbára,bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́ntàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òyetàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. 12 Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé,gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburútàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùngẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibití ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀. 13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn. 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé, “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe. 17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ. 18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.
In Other Versions
Ecclesiastes 9 in the ANGEFD
Ecclesiastes 9 in the ANTPNG2D
Ecclesiastes 9 in the AS21
Ecclesiastes 9 in the BAGH
Ecclesiastes 9 in the BBPNG
Ecclesiastes 9 in the BBT1E
Ecclesiastes 9 in the BDS
Ecclesiastes 9 in the BEV
Ecclesiastes 9 in the BHAD
Ecclesiastes 9 in the BIB
Ecclesiastes 9 in the BLPT
Ecclesiastes 9 in the BNT
Ecclesiastes 9 in the BNTABOOT
Ecclesiastes 9 in the BNTLV
Ecclesiastes 9 in the BOATCB
Ecclesiastes 9 in the BOATCB2
Ecclesiastes 9 in the BOBCV
Ecclesiastes 9 in the BOCNT
Ecclesiastes 9 in the BOECS
Ecclesiastes 9 in the BOGWICC
Ecclesiastes 9 in the BOHCB
Ecclesiastes 9 in the BOHCV
Ecclesiastes 9 in the BOHLNT
Ecclesiastes 9 in the BOHNTLTAL
Ecclesiastes 9 in the BOICB
Ecclesiastes 9 in the BOILNTAP
Ecclesiastes 9 in the BOITCV
Ecclesiastes 9 in the BOKCV
Ecclesiastes 9 in the BOKCV2
Ecclesiastes 9 in the BOKHWOG
Ecclesiastes 9 in the BOKSSV
Ecclesiastes 9 in the BOLCB
Ecclesiastes 9 in the BOLCB2
Ecclesiastes 9 in the BOMCV
Ecclesiastes 9 in the BONAV
Ecclesiastes 9 in the BONCB
Ecclesiastes 9 in the BONLT
Ecclesiastes 9 in the BONUT2
Ecclesiastes 9 in the BOPLNT
Ecclesiastes 9 in the BOSCB
Ecclesiastes 9 in the BOSNC
Ecclesiastes 9 in the BOTLNT
Ecclesiastes 9 in the BOVCB
Ecclesiastes 9 in the BPBB
Ecclesiastes 9 in the BPH
Ecclesiastes 9 in the BSB
Ecclesiastes 9 in the CCB
Ecclesiastes 9 in the CUV
Ecclesiastes 9 in the CUVS
Ecclesiastes 9 in the DBT
Ecclesiastes 9 in the DGDNT
Ecclesiastes 9 in the DHNT
Ecclesiastes 9 in the DNT
Ecclesiastes 9 in the ELBE
Ecclesiastes 9 in the EMTV
Ecclesiastes 9 in the ESV
Ecclesiastes 9 in the FBV
Ecclesiastes 9 in the FEB
Ecclesiastes 9 in the GGMNT
Ecclesiastes 9 in the GNT
Ecclesiastes 9 in the HARY
Ecclesiastes 9 in the HNT
Ecclesiastes 9 in the IRVA
Ecclesiastes 9 in the IRVB
Ecclesiastes 9 in the IRVG
Ecclesiastes 9 in the IRVH
Ecclesiastes 9 in the IRVK
Ecclesiastes 9 in the IRVM
Ecclesiastes 9 in the IRVM2
Ecclesiastes 9 in the IRVO
Ecclesiastes 9 in the IRVP
Ecclesiastes 9 in the IRVT
Ecclesiastes 9 in the IRVT2
Ecclesiastes 9 in the IRVU
Ecclesiastes 9 in the ISVN
Ecclesiastes 9 in the JSNT
Ecclesiastes 9 in the KAPI
Ecclesiastes 9 in the KBT1ETNIK
Ecclesiastes 9 in the KBV
Ecclesiastes 9 in the KJV
Ecclesiastes 9 in the KNFD
Ecclesiastes 9 in the LBA
Ecclesiastes 9 in the LBLA
Ecclesiastes 9 in the LNT
Ecclesiastes 9 in the LSV
Ecclesiastes 9 in the MAAL
Ecclesiastes 9 in the MBV
Ecclesiastes 9 in the MBV2
Ecclesiastes 9 in the MHNT
Ecclesiastes 9 in the MKNFD
Ecclesiastes 9 in the MNG
Ecclesiastes 9 in the MNT
Ecclesiastes 9 in the MNT2
Ecclesiastes 9 in the MRS1T
Ecclesiastes 9 in the NAA
Ecclesiastes 9 in the NASB
Ecclesiastes 9 in the NBLA
Ecclesiastes 9 in the NBS
Ecclesiastes 9 in the NBVTP
Ecclesiastes 9 in the NET2
Ecclesiastes 9 in the NIV11
Ecclesiastes 9 in the NNT
Ecclesiastes 9 in the NNT2
Ecclesiastes 9 in the NNT3
Ecclesiastes 9 in the PDDPT
Ecclesiastes 9 in the PFNT
Ecclesiastes 9 in the RMNT
Ecclesiastes 9 in the SBIAS
Ecclesiastes 9 in the SBIBS
Ecclesiastes 9 in the SBIBS2
Ecclesiastes 9 in the SBICS
Ecclesiastes 9 in the SBIDS
Ecclesiastes 9 in the SBIGS
Ecclesiastes 9 in the SBIHS
Ecclesiastes 9 in the SBIIS
Ecclesiastes 9 in the SBIIS2
Ecclesiastes 9 in the SBIIS3
Ecclesiastes 9 in the SBIKS
Ecclesiastes 9 in the SBIKS2
Ecclesiastes 9 in the SBIMS
Ecclesiastes 9 in the SBIOS
Ecclesiastes 9 in the SBIPS
Ecclesiastes 9 in the SBISS
Ecclesiastes 9 in the SBITS
Ecclesiastes 9 in the SBITS2
Ecclesiastes 9 in the SBITS3
Ecclesiastes 9 in the SBITS4
Ecclesiastes 9 in the SBIUS
Ecclesiastes 9 in the SBIVS
Ecclesiastes 9 in the SBT
Ecclesiastes 9 in the SBT1E
Ecclesiastes 9 in the SCHL
Ecclesiastes 9 in the SNT
Ecclesiastes 9 in the SUSU
Ecclesiastes 9 in the SUSU2
Ecclesiastes 9 in the SYNO
Ecclesiastes 9 in the TBIAOTANT
Ecclesiastes 9 in the TBT1E
Ecclesiastes 9 in the TBT1E2
Ecclesiastes 9 in the TFTIP
Ecclesiastes 9 in the TFTU
Ecclesiastes 9 in the TGNTATF3T
Ecclesiastes 9 in the THAI
Ecclesiastes 9 in the TNFD
Ecclesiastes 9 in the TNT
Ecclesiastes 9 in the TNTIK
Ecclesiastes 9 in the TNTIL
Ecclesiastes 9 in the TNTIN
Ecclesiastes 9 in the TNTIP
Ecclesiastes 9 in the TNTIZ
Ecclesiastes 9 in the TOMA
Ecclesiastes 9 in the TTENT
Ecclesiastes 9 in the UBG
Ecclesiastes 9 in the UGV
Ecclesiastes 9 in the UGV2
Ecclesiastes 9 in the UGV3
Ecclesiastes 9 in the VBL
Ecclesiastes 9 in the VDCC
Ecclesiastes 9 in the YALU
Ecclesiastes 9 in the YAPE
Ecclesiastes 9 in the YBVTP
Ecclesiastes 9 in the ZBP