Exodus 38 (BOYCB)

1 Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé. 2 Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. 3 Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀. 4 Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà. 5 Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú. 6 Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ. 7 Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú. 8 Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 9 Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, 10 pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11 Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 12 Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13 Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀. 14 Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15 àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà. 16 Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 17 Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà. 18 Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé, 19 pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà. 20 Gbogbo èèkàn àgọ́ tabanaku náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ. 21 Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà. 22 (Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti OLÚWA pàṣẹ fún Mose. 23 Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.) 24 Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti òjìlélẹ́ẹ̀gbẹ́rín ó dín mẹ́wàá (730) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́. 25 Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì àti òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (1,775) ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, 26 ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ lé ẹgbẹ̀tadínlógún ó lé àádọ́jọ (603,550) ọkùnrin. 27 Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùn-ún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì náà tálẹ́ǹtì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 28 Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (1,775) ṣékélì ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn. 29 Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá (2,400) ṣékélì. 30 Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú ààrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, 31 ihò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá náà àyíká àti ihò ìtẹ̀bọ̀ ẹnu-ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà, àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà yíká.

In Other Versions

Exodus 38 in the ANGEFD

Exodus 38 in the ANTPNG2D

Exodus 38 in the AS21

Exodus 38 in the BAGH

Exodus 38 in the BBPNG

Exodus 38 in the BBT1E

Exodus 38 in the BDS

Exodus 38 in the BEV

Exodus 38 in the BHAD

Exodus 38 in the BIB

Exodus 38 in the BLPT

Exodus 38 in the BNT

Exodus 38 in the BNTABOOT

Exodus 38 in the BNTLV

Exodus 38 in the BOATCB

Exodus 38 in the BOATCB2

Exodus 38 in the BOBCV

Exodus 38 in the BOCNT

Exodus 38 in the BOECS

Exodus 38 in the BOGWICC

Exodus 38 in the BOHCB

Exodus 38 in the BOHCV

Exodus 38 in the BOHLNT

Exodus 38 in the BOHNTLTAL

Exodus 38 in the BOICB

Exodus 38 in the BOILNTAP

Exodus 38 in the BOITCV

Exodus 38 in the BOKCV

Exodus 38 in the BOKCV2

Exodus 38 in the BOKHWOG

Exodus 38 in the BOKSSV

Exodus 38 in the BOLCB

Exodus 38 in the BOLCB2

Exodus 38 in the BOMCV

Exodus 38 in the BONAV

Exodus 38 in the BONCB

Exodus 38 in the BONLT

Exodus 38 in the BONUT2

Exodus 38 in the BOPLNT

Exodus 38 in the BOSCB

Exodus 38 in the BOSNC

Exodus 38 in the BOTLNT

Exodus 38 in the BOVCB

Exodus 38 in the BPBB

Exodus 38 in the BPH

Exodus 38 in the BSB

Exodus 38 in the CCB

Exodus 38 in the CUV

Exodus 38 in the CUVS

Exodus 38 in the DBT

Exodus 38 in the DGDNT

Exodus 38 in the DHNT

Exodus 38 in the DNT

Exodus 38 in the ELBE

Exodus 38 in the EMTV

Exodus 38 in the ESV

Exodus 38 in the FBV

Exodus 38 in the FEB

Exodus 38 in the GGMNT

Exodus 38 in the GNT

Exodus 38 in the HARY

Exodus 38 in the HNT

Exodus 38 in the IRVA

Exodus 38 in the IRVB

Exodus 38 in the IRVG

Exodus 38 in the IRVH

Exodus 38 in the IRVK

Exodus 38 in the IRVM

Exodus 38 in the IRVM2

Exodus 38 in the IRVO

Exodus 38 in the IRVP

Exodus 38 in the IRVT

Exodus 38 in the IRVT2

Exodus 38 in the IRVU

Exodus 38 in the ISVN

Exodus 38 in the JSNT

Exodus 38 in the KAPI

Exodus 38 in the KBT1ETNIK

Exodus 38 in the KBV

Exodus 38 in the KJV

Exodus 38 in the KNFD

Exodus 38 in the LBA

Exodus 38 in the LBLA

Exodus 38 in the LNT

Exodus 38 in the LSV

Exodus 38 in the MAAL

Exodus 38 in the MBV

Exodus 38 in the MBV2

Exodus 38 in the MHNT

Exodus 38 in the MKNFD

Exodus 38 in the MNG

Exodus 38 in the MNT

Exodus 38 in the MNT2

Exodus 38 in the MRS1T

Exodus 38 in the NAA

Exodus 38 in the NASB

Exodus 38 in the NBLA

Exodus 38 in the NBS

Exodus 38 in the NBVTP

Exodus 38 in the NET2

Exodus 38 in the NIV11

Exodus 38 in the NNT

Exodus 38 in the NNT2

Exodus 38 in the NNT3

Exodus 38 in the PDDPT

Exodus 38 in the PFNT

Exodus 38 in the RMNT

Exodus 38 in the SBIAS

Exodus 38 in the SBIBS

Exodus 38 in the SBIBS2

Exodus 38 in the SBICS

Exodus 38 in the SBIDS

Exodus 38 in the SBIGS

Exodus 38 in the SBIHS

Exodus 38 in the SBIIS

Exodus 38 in the SBIIS2

Exodus 38 in the SBIIS3

Exodus 38 in the SBIKS

Exodus 38 in the SBIKS2

Exodus 38 in the SBIMS

Exodus 38 in the SBIOS

Exodus 38 in the SBIPS

Exodus 38 in the SBISS

Exodus 38 in the SBITS

Exodus 38 in the SBITS2

Exodus 38 in the SBITS3

Exodus 38 in the SBITS4

Exodus 38 in the SBIUS

Exodus 38 in the SBIVS

Exodus 38 in the SBT

Exodus 38 in the SBT1E

Exodus 38 in the SCHL

Exodus 38 in the SNT

Exodus 38 in the SUSU

Exodus 38 in the SUSU2

Exodus 38 in the SYNO

Exodus 38 in the TBIAOTANT

Exodus 38 in the TBT1E

Exodus 38 in the TBT1E2

Exodus 38 in the TFTIP

Exodus 38 in the TFTU

Exodus 38 in the TGNTATF3T

Exodus 38 in the THAI

Exodus 38 in the TNFD

Exodus 38 in the TNT

Exodus 38 in the TNTIK

Exodus 38 in the TNTIL

Exodus 38 in the TNTIN

Exodus 38 in the TNTIP

Exodus 38 in the TNTIZ

Exodus 38 in the TOMA

Exodus 38 in the TTENT

Exodus 38 in the UBG

Exodus 38 in the UGV

Exodus 38 in the UGV2

Exodus 38 in the UGV3

Exodus 38 in the VBL

Exodus 38 in the VDCC

Exodus 38 in the YALU

Exodus 38 in the YAPE

Exodus 38 in the YBVTP

Exodus 38 in the ZBP